Sí Àwọn Ará Éfésù 4:1-32

  • Ìṣọ̀kan nínú ara Kristi (1-16)

    • Àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn (8)

  • Ìwà àtijọ́ àti ìwà tuntun (17-32)

4  Nítorí náà, èmi, ẹlẹ́wọ̀n+ nínú Olúwa, pàrọwà fún yín láti máa rìn lọ́nà tó yẹ+ pípè tí a pè yín,  pẹ̀lú gbogbo ìrẹ̀lẹ̀*+ àti ìwà tútù, pẹ̀lú sùúrù,+ kí ẹ máa fara dà á fún ara yín nínú ìfẹ́,+  kí ẹ máa sapá lójú méjèèjì láti pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà.+  Ara kan ló wà+ àti ẹ̀mí kan,+ bó ṣe jẹ́ pé ìrètí kan ṣoṣo + la pè yín sí;  Olúwa kan,+ ìgbàgbọ́ kan, ìbatisí kan;  Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo èèyàn, tó wà lórí ohun gbogbo, tó ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ohun gbogbo àti nínú ohun gbogbo.  A fún kálukú wa ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí bí Kristi ṣe díwọ̀n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ náà fúnni.+  Torí ó sọ pé: “Nígbà tó gòkè lọ sí ibi gíga, ó kó àwọn èèyàn lẹ́rú; ó fúnni ní àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn.”+  Tóò, kí ni gbólóhùn náà pé “ó gòkè” túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé ó ti kọ́kọ́ wá sísàlẹ̀, ìyẹn sí ayé. 10  Ẹni tó sọ̀ kalẹ̀ náà ni ẹni tó tún gòkè+ kọjá gbogbo ọ̀run,+ kí ó lè mú ohun gbogbo ṣẹ. 11  Ó fúnni ní àwọn kan gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì,+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bíi wòlíì,+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere,*+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́,+ 12  láti tọ́ àwọn ẹni mímọ́ sọ́nà,* fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, láti gbé ara Kristi ró,+ 13  títí gbogbo wa á fi ṣọ̀kan* nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, tí a ó fi di géńdé* ọkùnrin,+ tí a ó sì dàgbà dé ìwọ̀n kíkún ti Kristi. 14  Torí náà, kò yẹ ká jẹ́ ọmọdé mọ́, tí à ń gbá kiri bí ìgbì òkun ṣe ń gbá nǹkan kiri, tí gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ ẹ̀tàn àwọn èèyàn sì ń gbá síbí sọ́hùn-ún+ nípasẹ̀ ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí a fi hùmọ̀ ẹ̀tàn. 15  Àmọ́ nípa sísọ òótọ́, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú ká dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú ẹni tó jẹ́ orí, ìyẹn Kristi.+ 16  Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo ara+ ti para pọ̀ di ọ̀kan, tí a sì mú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípasẹ̀ gbogbo oríkèé tó ń pèsè ohun tí a nílò. Tí ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, èyí á mú kí ara máa dàgbà sí i bó ṣe ń gbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.+ 17  Nítorí náà, ohun tí màá sọ, tí màá sì jẹ́rìí sí nínú Olúwa ni pé kí ẹ má ṣe rìn mọ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń rìn,+ torí inú èrò asán* ni wọ́n ti ń rìn.+ 18  Ìrònú wọn ti ṣókùnkùn, wọ́n sì ti di àjèjì sí ìyè tó jẹ́ ti Ọlọ́run, torí pé wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan àti nítorí ọkàn wọn ti yigbì.* 19  Bí wọ́n ṣe wá kọjá gbogbo òye ìwà rere, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìnítìjú*+ láti máa fi ojúkòkòrò hu oríṣiríṣi ìwà àìmọ́. 20  Àmọ́, ẹ ò mọ Kristi sírú ẹni bẹ́ẹ̀, 21  tó bá jẹ́ pé òótọ́ lẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí a sì tipasẹ̀ rẹ̀ kọ́ yín, gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ṣe wà nínú Jésù. 22  Ẹ ti kẹ́kọ̀ọ́ pé kí ẹ bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀,+ èyí tó bá ọ̀nà ìgbésí ayé yín ti tẹ́lẹ̀ mu, tí àwọn ìfẹ́ rẹ̀ tó ń tanni jẹ sì ń sọ di ìbàjẹ́.+ 23  Torí náà, ẹ máa di tuntun nínú agbára tó ń darí ìrònú yín,*+ 24  kí ẹ sì gbé ìwà tuntun wọ̀,+ èyí tí a dá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin. 25  Torí náà, ní báyìí tí ẹ ti fi ẹ̀tàn sílẹ̀, kí kálukú yín máa bá ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́,+ nítorí ẹ̀yà ara kan náà ni wá.+ 26  Tí inú bá bí yín, ẹ má ṣẹ̀;+ ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ìbínú;+ 27  ẹ má gba Èṣù láyè.*+ 28  Kí ẹni tó ń jalè má jalè mọ́; kàkà bẹ́ẹ̀, kó máa ṣiṣẹ́ kára, kó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rere,+ kó lè ní nǹkan tó máa fún ẹni tí kò ní.+ 29  Kí ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́* má ṣe ti ẹnu yín jáde,+ ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró nìkan ni kí ẹ máa sọ bó bá ṣe yẹ, kí ó lè ṣe àwọn tó ń gbọ́ yín láǹfààní.+ 30  Bákan náà, ẹ má ṣe máa kó ẹ̀dùn ọkàn* bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run,+ èyí tí a fi gbé èdìdì lé+ yín fún ọjọ́ ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà.+ 31  Ẹ mú gbogbo inú burúkú,+ ìbínú, ìrunú, ariwo àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín,+ títí kan gbogbo ohun tó lè ṣeni léṣe.+ 32  Àmọ́ ẹ jẹ́ onínúure sí ara yín, kí ẹ máa ṣàánú,+ kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà bí Ọlọ́run náà ṣe tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn.”
Tàbí “akéde ìhìn rere.”
Tàbí “dá àwọn ẹni mímọ́ lẹ́kọ̀ọ́.”
Tàbí “wà ní ìrẹ́pọ̀.”
Tàbí “àgbà.”
Tàbí “òfo; òtúbáńtẹ́.”
Ní Grk., “gíràn-án.”
Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ní Gíríìkì, a·selʹgei·a. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ipá tó ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́.” Ní Grk., “ẹ̀mí èrò inú yín.”
Tàbí “bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má fàyè sílẹ̀ fún Èṣù.”
Ní Grk., “ọ̀rọ̀ tó ti jẹrà.”
Tàbí “ìbànújẹ́.”