Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ohun Tá A Fi Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ọ̀fẹ́ làwọn ohun tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí, wọ́n á jẹ́ kó o lè ṣè ìwádìí tó jinlẹ̀ nínú Bíbélì, kó o sì túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. O lè lo Bíbélì orí ìkànnì wa lọ́fẹ̀ẹ́, Bíbélì yìí sì ní ọ̀pọ̀ nǹkan táá jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ yé ẹ dáadáa. Wàá tún rí onírúurú fídíò tó dá lórí Bíbélì, àwòrán àwọn ilẹ̀ inú Bíbélì, àlàyé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì àtàwọn nǹkan míì tó o lè fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.

Ka Bíbélì Lórí Ìkànnì

Ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tó wà nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ péye, tó sì rọrùn kà.

Àwọn Fídíò Táá Jẹ́ Ká Túbọ̀ Lóye Bíbélì

Fídíò Tó Nasẹ̀ Ìwé Bíbélì

Ohun tí ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan dá lé àti kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó wà níbẹ̀.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Inú Bíbélì

Àwọn fídíò kéékèèké yìí dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì látinú Bíbélì, àwọn ìbéèrè bíi: Kí Ni Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé? Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú? Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà?

Àwọn Ohun Táá Jẹ́ Ká Túbọ̀ Lóye Bíbélì

Ìwé Tó Ṣàlàyé Àwọn Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì

Ìwé Insight on the Scriptures ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì. Ó sọ nípa àwọn èèyàn, ìlú, ẹranko, ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì àtàwọn ọ̀rọ̀ míì nínú Bíbélì. Nínú ẹ̀dà tó ṣe é wà jáde, wàá rí àwòrán ilẹ̀, fọ́tò, àpèjúwe títí kan ojú ìwé téèyàn ti lé rí àlàyé nípa ọ̀rọ̀ tàbí ẹsẹ Bíbélì kan.

Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì

Ìwé Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? ṣe àkópọ̀ ohun tó wà nínú Bíbélì ká lè túbọ̀ lóye ohun tó dá lé.

Àwòrán Àwọn Ilẹ̀ Inú Bíbélì

Ìwé Wo Ilẹ̀ Dáradára Náà ní àwọn àtẹ àti àwòrán ilẹ̀ tó jẹ́ ká mọ àwọn ibi tí Bíbélì mẹ́nu kàn, ní pàtàkì jù lọ àwòrán Ilẹ̀ Ìlérí.

Ẹsẹ Bíbélì fún Ọjọ́ Kọ̀ọ̀kan

Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ máa ń ní ẹsẹ Bíbélì kan pàtó fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àti àlàyé ṣókí nípa ẹsẹ Bíbélì náà.

Ètò Kíka Bíbélì

Ìbáà jẹ́ ètò Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ lò ń wá tàbí ti ọdọọdún tàbí èyí tó wà fẹ́ni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ máa ka Bíbélì, ètò Bíbélì kíkà yìí máa wúlò fún ẹ.

Bó O Ṣe Lè Wá Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Nínú Bíbélì Rẹ

Bó o ṣe lè wá ẹsẹ ìwé mímọ́ nínú Bíbélì rẹ: Bá a ṣe to àwọn ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin (66) tó wà nínú Bíbélì síbí ni wọ́n ṣe tò ó tẹ̀ léra nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì. Lẹ́yìn orúkọ ìwé, nọ́ńbà tó tẹ̀ lé e ni orí, nọ́ńbà tó wá tẹ̀ lé ìyẹn ni ẹsẹ.

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè nípa Ọlọ́run, Jésù, ìdílé, ìjìyà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì

Àwọn ẹsẹ Bíbélì kan wà táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó. Wo ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí gan-an.

Àká Ìwé Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì (opens new window)

Ṣàwárí àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lórí íńtánẹ́ẹ̀tì nínú àwọn ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ní Kí Ẹnì Kan Wá Máa Kọ́ Ẹ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Kí Ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn?

Ìtumọ̀ Bíbélì èyíkéyìí tó bá wù ẹ́ lo lè lò láti fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. O sì lè pe gbogbo ìdílé ẹ tàbí kó o pe àwọn ọ̀rẹ́ ẹ wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.

Ṣé O Fẹ́ Ká Wá Ẹ Wá

O lè mọ̀ sí i nípa Bíbélì tàbí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.