Òwe 21:1-31

  • Jèhófà ń darí ọkàn ọba (1)

  • Ṣíṣe ohun tí ó tọ́ sàn ju ẹbọ lọ (3)

  • Iṣẹ́ àṣekára máa ń múni ṣàṣeyọrí (5)

  • Ẹni tí kì í fetí sí ẹni rírẹlẹ̀, a ò ní gbọ́ tiẹ̀ (13)

  • Kò sí ọgbọ́n tó lòdì sí Jèhófà tó lè dúró (30)

21  Ọkàn ọba dà bí odò ní ọwọ́ Jèhófà.+ Ibi tí Ó bá fẹ́ ló ń darí rẹ̀ sí.+   Gbogbo ọ̀nà èèyàn máa ń tọ́ lójú ara rẹ̀,+Àmọ́ Jèhófà máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn.*+   Kí èèyàn ṣe ohun tó dára tí ó sì tọ́Máa ń mú inú Jèhófà dùn ju ẹbọ lọ.+   Ojú ìgbéraga àti ọkàn gígaNi fìtílà tó ń darí àwọn ẹni burúkú, ẹ̀ṣẹ̀ sì ni.+   Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere,*+Àmọ́ ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń kánjú yóò di aláìní.+   Láti fi ahọ́n èké kó ìṣúra jọDà bí ìkùukùu tó ń pòórá, ìdẹkùn ikú ni.*+   Ìwà ipá àwọn ẹni burúkú yóò gbá wọn dà nù,+Torí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́.   Ọ̀nà ẹlẹ́bi kì í gún,Àmọ́ iṣẹ́ aláìlẹ́bi máa ń tọ́.+   Ó sàn láti máa gbé ní igun òrùléJu kéèyàn máa bá aya tó jẹ́ oníjà* gbé inú ilé kan náà.+ 10  Ohun tí kò dáa ló máa ń wu ẹni* burúkú;+Kì í ṣàánú ọmọnìkejì rẹ̀.+ 11  Nígbà tí wọ́n bá fìyà jẹ afiniṣẹ̀sín, aláìmọ̀kan á kọ́gbọ́n,Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá sì rí ìjìnlẹ̀ òye, á ní ìmọ̀.*+ 12  Ọlọ́run Olódodo máa ń kíyè sí ilé ẹni burúkú;Ó ń dojú àwọn ẹni burúkú dé kí wọ́n lè pa run.+ 13  Ẹni tó bá di etí rẹ̀ sí igbe aláìníÒun fúnra rẹ̀ yóò pè, a kò sì ní dá a lóhùn.+ 14  Ẹ̀bùn tí a fúnni ní ìkọ̀kọ̀ ń mú ìbínú rọlẹ̀,+Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí a sì fúnni ní bòókẹ́lẹ́* ń mú ìbínú gbígbóná rọlẹ̀. 15  Inú olódodo máa ń dùn láti ṣe ohun tó bá ẹ̀tọ́ mu,+Àmọ́ ó ṣòro gan-an fún àwọn tó ń hùwà burúkú. 16  Ẹni tó bá fi ọ̀nà ìjìnlẹ̀ òye sílẹ̀Á sinmi pẹ̀lú àwọn tí ikú ti pa.*+ 17  Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ fàájì* yóò di aláìní;+Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ wáìnì àti òróró kò ní lówó lọ́wọ́. 18  Ẹni burúkú ni ìràpadà fún olódodo,A ó sì mú oníbékebèke dípò adúróṣinṣin.+ 19  Ó sàn láti máa gbé ní aginjùJu kéèyàn máa bá aya tó jẹ́ oníjà* àti oníkanra gbé.+ 20  Ìṣúra tó ṣeyebíye àti òróró máa ń wà ní ilé ọlọ́gbọ́n,+Àmọ́ òmùgọ̀ èèyàn máa ń fi ohun tó ní ṣòfò.*+ 21  Ẹni tó bá ń wá òdodo àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀Yóò rí ìyè, òdodo àti ògo.+ 22  Ọlọ́gbọ́n lè gun* ìlú àwọn alágbáraKí ó sì mú agbára tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé balẹ̀.+ 23  Ẹni tó bá ń ṣọ́ ẹnu àti ahọ́n rẹ̀Ń pa ara* rẹ̀ mọ́ lọ́wọ́ wàhálà.+ 24  Agbéraga tó ń fọ́nnu tó sì ń kọjá àyè rẹ̀Là ń pe ẹni tó ń fi wàdùwàdù ṣe nǹkan láìbìkítà.+ 25  Ohun tó ń wu ọ̀lẹ ló máa pa á,Nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ láti ṣiṣẹ́.+ 26  Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ló ń ṣojúkòkòrò,Àmọ́ olódodo ń fúnni láìfawọ́ nǹkan kan sẹ́yìn.+ 27  Ẹbọ ẹni burúkú jẹ́ ohun ìríra.+ Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kó mú un wá pẹ̀lú èrò ibi!* 28  Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé,+Àmọ́ ẹ̀rí ẹni tó ń fetí sílẹ̀ yóò fìdí múlẹ̀.* 29  Èèyàn burúkú máa ń lo ògbójú,+Àmọ́ adúróṣinṣin ni ọ̀nà rẹ̀ dájú.*+ 30  Kò sí ọgbọ́n tàbí òye tàbí ìmọ̀ràn tó lòdì sí Jèhófà tó lè dúró.+ 31  Èèyàn lè ṣètò ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun,+Àmọ́ ti Jèhófà ni ìgbàlà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “èrò ọkàn.”
Tàbí “àǹfààní.”
Tàbí kó jẹ́, “fún àwọn tó ń wá ikú.”
Tàbí “ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.”
Tàbí “ọkàn ẹni.”
Tàbí “mọ ohun tó yẹ kó ṣe.”
Ní Héb., “ní àyà.”
Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”
Tàbí “ìgbádùn.”
Tàbí “ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.”
Ní Héb., “gbé ohun tó ní mì.”
Tàbí “borí.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “pẹ̀lú ìwà tó ń tini lójú.”
Ní Héb., “ẹni tó ń fetí sílẹ̀ yóò máa sọ̀rọ̀ títí láé.”
Tàbí “ló ń mú kí ọ̀nà rẹ̀ dájú.”