Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ásà, Jèhóṣáfátì, Hesekáyà, àti Jòsáyà

Fi Ọkàn Pípé Pérépéré Sin Jèhófà!

Fi Ọkàn Pípé Pérépéré Sin Jèhófà!

“Jèhófà, jọ̀wọ́, rántí bí mo ṣe rìn níwájú rẹ nínú òtítọ́ àti pẹ̀lú ọkàn-àyà pípé pérépéré.”2 ỌBA 20:3.

ORIN: 52, 65

1-3. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn fi “ọkàn-àyà pípé pérépéré” sin Jèhófà? Sọ àpẹẹrẹ kan.

ALÁÌPÉ ni wá, torí náà a máa ń ṣàṣìṣe. Àmọ́, a dúpẹ́ pé Jèhófà kì í ṣe sí wa “gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,” pàápàá jù lọ tá a bá ronú pìwà dà, tá a sì bẹ Jèhófà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé kó wo ọlá ẹbọ ìràpadà Jésù mọ́ wa lára. (Sm. 103:10) Síbẹ̀, bí ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ fún Sólómọ́nì, kí Jèhófà tó lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, a gbọ́dọ̀ máa “fi ọkàn-àyà pípé pérépéré” sìn ín. (1 Kíró. 28:9) Báwo làwa èèyàn aláìpé ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

2 Ohun kan tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká fi ìgbésí ayé Ọba Ásà wé ti Ọba Amasááyà. Bíbélì sọ pé àwọn ọba Júdà méjèèjì yìí ṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà, àmọ́ Ásà ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ọkàn tó pé pérépéré. (2 Kíró. 15:16, 17; 25:1, 2; Òwe 17:3) Aláìpé làwọn ọba méjèèjì, wọ́n sì ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, Ásà kò yẹṣẹ̀ lọ́nà Jèhófà, ṣe ló fi “ọkàn-àyà pípé pérépéré” sin Ọlọ́run. (1 Kíró. 28:9) Àmọ́ ní ti Amasááyà, kò fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà. Ìdí sì ni pé lẹ́yìn tó ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ọlọ́run, ó kó àwọn òrìṣà àwọn èèyàn náà pa dà sílé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ wọ́n.2 Kíró. 25:11-16.

3 Téèyàn bá máa fi “ọkàn-àyà pípé pérépéré” sin Ọlọ́run, ó gba pé kéèyàn sìn ín tọkàntara jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹni. Àpapọ̀ ohun tẹ́nì kan jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún ni Bíbélì sábà máa ń pè ní “ọkàn.” Ìyẹn sì kan ìfẹ́ ọkàn ẹni, ohun téèyàn ń rò, irú ẹni téèyàn jẹ́, ìwà téèyàn ń hù, ohun téèyàn lè ṣe, ohun tó ń mú kéèyàn ṣe nǹkan àti àfojúsùn ẹni. Ẹni tó ń fi ọkàn tó pé pérépéré sin Jèhófà kì í ṣe ojú ayé. Ìjọsìn rẹ̀ kì í ṣe àfaraṣe-má-fọkàn-ṣe. Àwa ńkọ́? Lóòótọ́ aláìpé ni wá, àmọ́ tá a bá ń sin Jèhófà tọkàntara láìbọ́hùn, tá ò sì ṣe ojú ayé, a jẹ́ pé ọkàn tó pé pérépéré la fi ń sin Jèhófà.2 Kíró. 19:9.

4. Kí la máa jíròrò báyìí?

4 Ká lè mọyì ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn fi ọkàn tó pé pérépéré sin Ọlọ́run, a máa jíròrò bí àwọn kan lára àwọn ọba Júdà ṣe fi ọkàn tó pé pérépéré sin Jèhófà. Lára wọn ni Ásà, Jèhóṣáfátì, Hesekáyà àti Jòsáyà. Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ṣàṣìṣe lóòótọ́, àmọ́ Jèhófà fojúure wò wọ́n. Kí nìdí tí Jèhófà fi gbà pé wọ́n fi ọkàn tó pé pérépéré sin òun, báwo la sì ṣe lè fara wé wọn?

ÁSÀ FI “ỌKÀN-ÀYÀ PÍPÉ PÉRÉPÉRÉ” SIN JÈHÓFÀ

5. Àwọn ìgbésẹ̀ akin wo ni Ásà gbé?

5 Ásà ni ọba kẹta tó jẹ nílẹ̀ Júdà lẹ́yìn tí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá dá dúró. Ásà mú ìbọ̀rìṣà kúrò nílẹ̀ Júdà, ó sì lé àwọn aṣẹ́wó ọkùnrin inú tẹ́ńpìlì kúrò nílùú. Kódà, ó yọ Máákà ìyá rẹ̀ àgbà kúrò nípò “ìyáàfin, nítorí tí ó ṣe òrìṣà bíbanilẹ́rù kan.” (1 Ọba 15:11-13) Yàtọ̀ síyẹn, Ásà rọ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà pé “kí wọ́n wá Jèhófà . . . kí wọ́n sì pa òfin àti àṣẹ [rẹ̀] mọ́.” Ó ṣe kedere pé ó gbé ìjọsìn tòótọ́ lárug̣ẹ.2 Kíró. 14:4.

6. Kí ni Ásà ṣe nígbà táwọn ará Etiópíà wá gbéjà kò ó?

6 Jèhófà mú kí àlàáfíà jọba nílẹ̀ Júdà lọ́dún mẹ́wàá àkọ́kọ́ tí Ásà fi wà lórí oyè. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Síírà ará Etiópíà kó àwọn ọmọ ogun mílíọ̀nù kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta kẹ̀kẹ́ ogun láti wá gbéjà ko Júdà. (2 Kíró. 14:1, 6, 9, 10) Kí wá ni Ásà ṣe? Ó yíjú sí Jèhófà, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ran àwọn lọ́wọ́. (Ka 2 Kíróníkà 14:11.) Jèhófà dáhùn àdúrà àtọkànwá tí Ásà gbà, ó mú kó ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Etiópíà, débi pé kò sẹ́nì kan tó ṣẹ́ kù lára wọn. (2 Kíró. 14:12, 13) Kódà nígbà táwọn ọba kan ò bá tiẹ̀ fọkàn sin Jèhófà, ó ṣì máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn nítorí orúkọ rẹ̀. (1 Ọba 20:13, 26-30) Ásà ní tiẹ̀ gbára lé Ọlọ́run, Jèhófà sì gbọ́ àdúrà rẹ̀. Àmọ́ o, ìgbà kan wà tí Ásà hùwà tí kò tọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó lọ bẹ ọba Síríà lọ́wẹ̀ pé kó ran òun lọ́wọ́ dípò kó yíjú sí Jèhófà. (1 Ọba 15:16-22) Síbẹ̀, nígbà tí Jèhófà máa sọ̀rọ̀ nípa Ásà, ó sọ pé ọkàn rẹ̀ “wà ní pípé pérépéré pẹ̀lú [òun] ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀.” Báwo làwa náà ṣe lè máa ṣe rere bíi ti Ásà?1 Ọba 15:14.

7, 8. Báwo lo ṣe le fara wé Ásà?

7 Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè yẹ ọkàn rẹ̀ wò bóyá òun ń fi ọkàn tó pé pérépéré sin Ọlọ́run. Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo ti pinnu pé ìfẹ́ Jèhófà ni màá máa ṣe, ṣé màá máa gbèjà ìjọsìn tòótọ́, tí màá sì máa ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti mú kí ìjọ Ọlọ́run wà ní mímọ́?’ Ó dájú pé ìgboyà gidi ni Ásà ní kó tó lè rọ Máákà tó jẹ́ “ìyáàfin” lóyè! O lè má mọ ẹnikẹ́ni tó ń ṣe bíi ti obìnrin yẹn, àmọ́ àwọn nǹkan míì wà tó lè gba pé kó o lo ìtara bíi ti Ásà. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹnì kan nínú ìdílé rẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan dẹ́ṣẹ̀, tí kò ronú pìwà dà, tí wọ́n sì yọ ọ́ lẹ́gbẹ́, kí ni wàá ṣe? Ṣé wàá lo ìgboyà, kó o sì pinnu pé o ò ní bá onítọ̀hún ṣe mọ́? Kí lọkàn rẹ máa sọ pé kó o ṣe?

8 O lè fi hàn pé tọkàntọkàn lo gbára lé Jèhófà bíi ti Ásà, nígbà tó o bá dojú kọ àtakò, títí kan àwọn ìṣòro tó dà bí òkè. Àwọn ọmọ ilé ìwé rẹ lè máa bú ẹ tàbí kí wọ́n máa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́. Àwọn ará ibiṣẹ́ rẹ sì lè máa bú ẹ torí pé o máa ń gbàyè láti lọ sí ìpàdé àtàwọn ìgbòkègbodò Kristẹni míì, tàbí torí pé o kì í sábà ṣe àṣekún iṣẹ́. Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, gbàdúrà sí Jèhófà bíi ti Ásà. Ṣe ọkàn akin, kó o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kó o sì máa ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu tó sì tọ́. Máa rántí pé Ọlọ́run ran Ásà lọ́wọ́, ó sì dájú pé á ran ìwọ náà lọ́wọ́.

9. Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọkàn wa pé pérépéré tó bá kan ọ̀rọ̀ ìwàásù?

9 Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń ro tàwọn míì mọ́ tiwa. Bí àpẹẹrẹ, Ásà gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ. Àwa náà máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè “wá Jèhófà.” Ẹ wo bí inú Jèhófà ti máa dùn tó bó ṣe ń rí wa tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fáwọn aládùúgbò wa àtàwọn èèyàn míì torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àti pé a fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun!

JÈHÓṢÁFÁTÌ WÁ JÈHÓFÀ

10, 11. Báwo lo ṣe lè fara wé Jèhóṣáfátì?

10 Bíbélì sọ pé Jèhóṣáfátì ọmọ Ásà “ń bá a nìṣó ní rírìn ní ọ̀nà Ásà baba rẹ̀.” (2 Kíró. 20:31, 32) Kí lohun tó ṣe? Bíi ti bàbá rẹ̀, Jèhóṣáfátì rọ àwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà pé kí wọ́n wá Jèhófà. Ó ṣètò àwọn ọmọ Léfì àtàwọn míì pé kí wọ́n máa fi “ìwé òfin Jèhófà” kọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà. (2 Kíró. 17:7-10) Ó tiẹ̀ tún lọ sáwọn ẹkùn olókè ńlá Éfúráímù, tó wà ní àgbègbè ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá, kó lè mú àwọn èèyàn ibẹ̀ “padà wá sọ́dọ̀ Jèhófà.” (2 Kíró. 19:4) Kò sí àní-àní pé Ọba Jèhóṣáfátì “fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ wá Jèhófà.”2 Kíró. 22:9.

11 Gbogbo wa la lè kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà ṣètò rẹ̀ lásìkò wa yìí. Ṣó o máa ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lóṣooṣu láti kọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣó o sì ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá sin Ọlọ́run? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, tó o sì ń bẹ Jèhófà pé kó bù kún ìsapá rẹ, wàá rẹ́ni tí wàá máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣó o máa ń fọ̀rọ̀ náà sádùúrà? Ṣé wàá ṣe gbogbo ohun tó bá gbà, bó bá tiẹ̀ gba pé kó o yááfì lára àkókò ìsinmi rẹ? Bíi ti Jèhóṣáfátì tó lọ sí àgbègbè Éfúráímù kó lè ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, àwa náà lè ṣèrànwọ́ fáwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ kí wọ́n lè pa dà máa ṣe déédéé. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alàgbà máa ń ṣètò láti lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tá a yọ lẹ́gbẹ́ tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ ìjọ wọn, àmọ́ tí wọ́n ti jáwọ́ nínú ìwà àìtọ́. Wọ́n sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

12, 13. (a) Kí ni Jèhóṣáfátì ṣe nígbà táwọn kan wá gbéjà kò ó? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé ó níbi tágbára wa mọ bíi ti Jèhóṣáfátì?

12 Jèhóṣáfátì ṣe bíi ti bàbá rẹ̀ Ásà, ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nígbà táwọn àkòtagìrì ọmọ ogun wá gbéjà kò ó. (Ka 2 Kíróníkà 20:2-4.) Ká sòótọ́, àyà Jèhóṣáfátì já, àmọ́ ó pinnu pé òun máa wá Jèhófà. Nínú àdúrà rẹ̀, ó fìrẹ̀lẹ̀ sọ pé òun àtàwọn èèyàn òun kò ní ‘agbára kankan níwájú ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí,’ àti pé àwọn ò mọ ohun táwọn máa ṣe. Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ó sọ pé: “Ojú wa ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.”2 Kíró. 20:12.

13 Nígbà míì, àwa náà lè má mọ ohun tá a máa ṣe, ẹ̀rù sì lè máa bà wá bíi ti Jèhóṣáfátì. (2 Kọ́r. 4:8, 9) Àmọ́, ká rántí pé Jèhóṣáfátì gbàdúrà níṣojú gbogbo èèyàn pé òun àtàwọn èèyàn òun ò lágbára táwọn lè fi jà. (2 Kíró. 20:5) Ẹ̀yin olórí ìdílé náà lè ṣe bíi ti Jèhóṣáfátì, ẹ bẹ Jèhófà pé kó tọ́ yín sọ́nà, kó sì fún yín lágbára láti kojú àwọn ìṣòro yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kójú tì yín láti gba irú àdúrà bẹ́ẹ̀ lójú àwọn tó wà nínú ìdílé yín. Àdúrà bẹ́ẹ̀ máa mú kí wọ́n rí i pé ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ọlọ́run ran Jèhóṣáfátì lọ́wọ́, ó sì máa ran ẹ̀yin náà lọ́wọ́.

HESEKÁYÀ Ń BÁ A LỌ NÍ ṢÍṢE OHUN TÓ TỌ́

14, 15. Kí ni Hesekáyà ṣe tó fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá?

14 Bí nǹkan ṣe rí fún Ọba Hesekáyà yàtọ̀ sí ti Jèhóṣáfátì torí pé abọ̀rìṣà ni bàbá Hesekáyà. Torí náà, iṣẹ́ ńlá ló ṣe tóun náà kò fi ya abọ̀rìṣà bíi ti bàbá rẹ̀, tó sì ń “bá a nìṣó ní fífà mọ́ Jèhófà.” Hesekáyà ‘mú àwọn ibi gíga kúrò, ó fọ́ àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ sí wẹ́wẹ́, ó gé òpó ọlọ́wọ̀ lulẹ̀ ó sì fọ́ ejò bàbà tí Mósè ṣe sí wẹ́wẹ́,’ torí pé àwọn èèyàn ti sọ ejò bàbà náà di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Tọkàntara ni Hesekáyà fi sin Jèhófà, torí pé “ó ń bá a lọ láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,” ìyẹn àwọn àṣẹ tí Jèhófà pa fún Mósè.2 Ọba 18:1-6.

15 Nígbà tí Ásíríà tó jẹ́ agbára ayé ìgbà yẹn gbógun ti ilẹ̀ Júdà, tí wọ́n sì halẹ̀ pé àwọn máa pa Jerúsálẹ́mù run, Hesekáyà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Senakéríbù tó jẹ́ ọba Ásíríà ṣáátá Jèhófà, ó sì wọ́nà àtikó Hesekáyà láyà jẹ kó lè juwọ́ sílẹ̀. Àmọ́ àdúrà tí Hesekáyà gbà fi hàn pé ó gbà pé Jèhófà lágbára láti dá àwọn nídè. (Ka Aísáyà 37:15-20.) Ọlọ́run dáhùn àdúrà yẹn ní ti pé ó rán áńgẹ́lì kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́, áńgẹ́lì náà sì pa ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́sàn-án ó lé márùn-ún [185,000] ọmọ ogun Ásíríà.Aísá. 37:36, 37.

16, 17. Báwo lo ṣe lè fara wé Hesekáyà?

16 Ẹ̀yìn ìyẹn ni Hesekáyà ṣàìsàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀. Ó wá bẹ Jèhófà pé kó rántí bí òun ṣe rìn níwájú rẹ̀. (Ka 2 Àwọn Ọba 20:1-3.) Àwa ńkọ́? Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé, a ò lè retí pé kí Ọlọ́run wò wá sàn lọ́nà ìyanu tàbí pé kó mú kí ẹ̀mí wa gùn. Síbẹ̀ bíi ti Hesekáyà, a lè sọ nínú àdúrà wa pé, mo ti “rìn níwájú rẹ nínú òtítọ́ àti pẹ̀lú ọkàn-àyà pípé pérépéré.” Ṣó o gbà pé Jèhófà lè gbé ẹ ró tó o bá ń ṣàìsàn?Sm. 41:3.

17 Bá a ṣe ń ronú lórí àpẹẹrẹ Hesekáyà, a lè rí àwọn ohun kan tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, tàbí tó lè má jẹ́ ká pọkàn pọ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ fara wé àwọn èèyàn ayé tí wọ́n ti sọ àwọn èèyàn bíi tiwọn di òrìṣà lórí ìkànnì àjọlò. Ohun kan ni pé àwọn Kristẹni kan gbádùn kí wọ́n máa bá àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìkànnì yìí. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nínú ayé ti ki àṣejù bọ ọ̀rọ̀ lílo ìkànnì àjọlò, wọ́n máa ń tẹ àmì kan tó fi hàn pé àwọn ń tẹ̀ lé àwọn tí wọn ò mọ̀ rí. Wọ́n máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti wo fọ́tò àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n máa kà nípa wọn. Tá ò bá ṣọ́ra, àwa náà lè máa fi àkókò wa ṣòfò lórí àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Kristẹni kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń tẹ àmì kan tí wọ́n fi ń sọ pé àwọn fẹ́ràn àwọn nǹkan tó ń gbé sórí ìkànnì àjọlò, ó sì lè máa bínú torí pé àwọn kan tó ti ń tẹ̀ lé e tẹ́lẹ̀ lórí ìkànnì àjọlò ò tẹ̀ lé e mọ́. Rò ó wò ná, ṣé a lè retí pé kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tàbí Ákúílà àti Pírísílà máa fi ojoojúmọ́ gbé fọ́tò àtàwọn nǹkan míì sórí ìkànnì àjọlò tàbí kí wọ́n máa tẹ àmì kan láti fi hàn pé àwọn ń tẹ̀ lé àwọn tí kì í ṣe Kristẹ́ni? Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí Pọ́ọ̀lù fi àkókò rẹ̀ ṣe, ó ní ‘ọwọ́ Pọ́ọ̀lù dí jọjọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà.’ Bákan náà ni Pírísílà àti Ákúílà lo àkókò wọn láti ṣàlàyé “ọ̀nà Ọlọ́run fún [àwọn èèyàn] lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí.” (Ìṣe 18:4, 5, 26) Àwa náà lè bi ara wa pé, ‘Ṣé mò ń ṣọ́ra kí n má lọ sọ àwọn èèyàn di òrìṣà? Ṣé mi ò kì í lo ọ̀pọ̀ àkókò nídìí àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì?’Ka Éfésù 5:15, 16.

JÒSÁYÀ PA ÀWỌN ÀṢẸ JÈHÓFÀ MỌ́

18, 19. Àwọn ọ̀nà wo ni wàá gbà ṣe bíi ti Jòsáyà?

18 Ọba Jòsáyà tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Hesekáyà pẹ̀lú pinnu pé òun máa fi “gbogbo ọkàn-àyà” tẹ̀ lé òfin Jèhófà. (2 Kíró. 34:31) Nígbà tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún, “ó bẹ̀rẹ̀ sí wá Ọlọ́run Dáfídì,” nígbà tó sì máa fi pọ́mọ ogún ọdún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìbọ̀rìṣà kúrò nílẹ̀ Júdà. (Ka 2 Kíróníkà 34:1-3.) Jòsáyà nítara fún ìjọsìn Ọlọ́run ju èyí tó pọ̀ jù lọ lára awọn ọba tó jẹ ní Júdà. Síbẹ̀, nígbà tí wọ́n rí ìwé Òfin Mósè, tí wọ́n sì kà á sí i létí, ó rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan wà tóun ṣì nílò láti ṣe kóun lè túbọ̀ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Torí náà, ó rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n sin Jèhófà. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn náà “kò yà kúrò nínú títọ Jèhófà Ọlọ́run” lẹ́yìn jálẹ̀ ìgbésí ayé Jòsáyà.2 Kíró. 34:27, 33.

19 Bíi ti Jòsáyà, ó yẹ káwọn ọmọdé bẹ̀rẹ̀ sí í wá Jèhófà ní báyìí tí wọ́n ṣì wà ní kékeré. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ọba Mánásè tó yí pa dà kúrò nínú ìwà búburú tó ń hù ló kọ́ Jòsáyà pé aláàánú ni Ọlọ́run. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, sún mọ́ àwọn àgbàlagbà tó ń fọkàn sin Jèhófà, tí wọ́n wà nínú ìdílé rẹ àti nínú ìjọ, kó o lè mọ bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni rere sí wọn. Bákan náà, rántí pé Ìwé Mímọ́ tí Jòsáyà kà wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó sì mú kó ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run. Tíwọ náà bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wàá máa ṣe ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ láyọ̀, wàá sì túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, á mú kó túbọ̀ máa wù ẹ́ láti wàásù fáwọn míì káwọn náà lè wá sin Ọlọ́run. (Ka 2 Kíróníkà 34:18, 19.) Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá rí àwọn ọ̀nà tó o lè gbà mú iṣẹ́ ìsìn rẹ gbòòrò sí i. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣiṣẹ́ lórí àwọn nǹkan tó o kíyè sí bí Jòsáyà ti ṣe.

FI ỌKÀN PÍPÉ PÉRÉPÉRÉ SIN JÈHÓFÀ!

20, 21. (a) Kí làwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà fi jọra? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

20 Bá a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la rí kọ́ lára àwọn ọba Júdà mẹ́rin tí wọ́n fi ọkàn tó pé pérépéré sin Jèhófà. Wọ́n fìtara ṣe ìfẹ́ Jèhófà, tọkàntara ni wọ́n sì fi jọ́sìn rẹ̀. Wọn ò yé ṣe ohun tó ń múnú Ọlọ́run dùn. Kódà wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n kojú àwọn ìṣòro tó dà bí òkè. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wọn ò ṣojú ayé nínú ìjọsìn wọn.

21 Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí i pé àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tá a jíròrò tán yìí ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, nígbà tí Olùṣàyẹ̀wò ọkàn yẹ ọkàn wọn wò, ó sọ pé ọkàn tó pé pérépéré ni wọ́n fi sin òun. Bíi tàwọn ọba yẹn, aláìpé làwa náà. Àmọ́, tí Jèhófà bá ṣàyẹ̀wò ọkàn tiwa náà, ṣó máa sọ pé à ń fi ọkàn tó pé pérépéré sin òun? Kókó yìí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.