Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àǹfààní Wo Lo Máa Rí Tó O Bá Mọ Ọlọ́run?

Àǹfààní Wo Lo Máa Rí Tó O Bá Mọ Ọlọ́run?

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú ìwé yìí ti jẹ́ ká rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà, Ta ni Ọlọ́run? Ìdáhùn tá a kọ́kọ́ rí nínú Bíbélì ni pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, ìfẹ́ sì ànímọ́ rẹ̀ tó ta yọ jù. A tún ti rí àwọn ohun tó ti gbé ṣe àti àwọn nǹkan míì tó ṣì máa ṣe lọ́jọ́ iwájú fún àǹfààní àwa èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ṣì wà tá a máa kọ́ nípa Ọlọ́run, o lè máa ronú pé, àǹfààní wo ni ìyẹn máa ṣe fún ẹ.

Jèhófà ṣèlérí pé tí a bá wá òun, òun máa jẹ́ ká rí òun. (1 Kíróníkà 28:9) Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé bó o ṣe túbọ̀ ń mọ Ọlọ́run, wàá ní “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.” (Sáàmù 25:14) Oò rí i pé àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ gbáà ni ìyẹn máa jẹ́! Àwọn àǹfààní wo là ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

Wàá ní ayọ̀ tòótọ́. Bíbélì pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Torí náà, tó o bá sún mọ́ ọn, tó o sì ń fara wé e, wàá ní ayọ̀ tòótọ́. Èyí á sì hàn lójú rẹ, nínú bó o ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe rí lára rẹ. (Sáàmù 33:12) Ọlọ́run tún máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ìgbésí ayé rẹ lè ládùn kó sì lóyin. Kí ìyẹn lè ṣeé ṣe, á kọ́ ẹ láti yẹra fún àwọn ìwà tó lè bà ẹ́ láyé jẹ́, á tọ́ ẹ sọ́nà láti máa hùwà rere àti bó o ṣe lè máa ṣe dáadáa sí àwọn èèyàn. Níkẹyìn, ìwọ fúnra rẹ á lè sọ bíi ti onísáàmù náà pé: “Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.”​—Sáàmù 73:28.

Ọlọ́run á bójú tó ẹ, á sì máa ṣìkẹ́ rẹ. Jèhófà ṣèlérí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” (Sáàmù 32:8) Ohun tí Jèhófà ń sọ ni pé òun máa fìfẹ́ bójú tó àwọn ìránṣẹ́ òun lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, òun á sì pèsè ohun tí wọ́n nílò lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Sáàmù 139:​1, 2) Tó o bá sapá kí àárín ìwọ àti Ọlọ́run lè gún régé, wàá rí i pé á máa dúró tì ẹ́ nígbà gbogbo.

Ọjọ́ iwájú rẹ máa dára. Yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run máa jẹ́ kó o láyọ̀ kí ayé rẹ sì dára ní báyìí, á tún mú kí ọjọ́ ọ̀la rẹ dára gan-an. (Aísáyà 48:​17, 18) Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Nínú ayé tó kún fún wàhálà yìí, ńṣe ni ìrètí àgbàyanu yìí dà bí ìdákọ̀ró tó ń “fìdí wa múlẹ̀ gbọn-in.”​—Hébérù 6:19.

Àwọn nǹkan tá a sọ yìí kàn jẹ́ díẹ̀ lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ mọ Ọlọ́run ká sì sún mọ́ ọn. A rọ̀ ẹ́ pé kó o bá ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ tàbí kó o lọ sí ìkànnì jw.org/yo kó o lè rí àwọn ìsọfúnni síwájú sí i.