Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Bá A Ṣe Borí Ìṣòro Èdè—Iṣẹ́ Táwọn Atúmọ̀ Èdè Wa Ń Ṣe

Bá A Ṣe Borí Ìṣòro Èdè—Iṣẹ́ Táwọn Atúmọ̀ Èdè Wa Ń Ṣe

“Wọ́n sábà máa ń sọ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí iṣẹ́ kankan tó díjú tó iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè.”—Ìwé “The Cambridge Encyclopedia of Language.”

KÁ TÓ bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ ìwé wa, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń múra sílẹ̀ gidigidi, a sì máa ń fara balẹ̀ ṣèwádìí. Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ ní oríléeṣẹ́ wa tó wà ní ìlú New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà á sì ṣàyẹ̀wò gbogbo ohun tí wọ́n kọ fínífíní, kí wọ́n lè rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ló wà níbẹ̀. Lẹ́yìn náà ni wọ́n á wá gbé e jáde lọ́nà tó bá ọ̀nà ìkọ̀wé òde òní mu tó sì dùn ún kà. *

Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ á wá fi ìwé náà ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà sí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn atúmọ̀ èdè kárí ayé. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló ń ṣiṣẹ́ ní ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè wọn, ibẹ̀ náà sì ni wọ́n ń gbé. Èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló ń túmọ̀ sí èdè abínibí wọn. Àmọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè àbínibí wọn lágbọ̀ọ́yé.

Báwo làwọn atúmọ̀ èdè ṣe máa ń ṣiṣẹ́ wọn?

Ẹ gbọ́ bí Geraint, tó jẹ́ atúmọ̀ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe ṣàlàyé. Ó ní: “Ẹnì kan kì í dá ṣiṣẹ́, torí náà inú àwùjọ kan ni wọ́n pín mi sí, èyí sì gba ìfọwọ́sowọ́pọ̀. Tá a bá ko ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́ tá à ń túmọ̀, a jọ máa ń wá ojútùú sí i ni. Ìyẹn gba pé ká máa túmọ̀ àkójọ ọ̀rọ̀ lápapọ̀ dípò ká máa wá ìtúmọ̀ fún ẹyọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan. Torí náà, a máa ń ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí òǹkọ̀wé ní lọ́kàn gan-an ká lè túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó máa wọ àwọn tó ń sọ èdè wa lọ́kàn.”

Kí ni àfojúsùn yín gẹ́gẹ́ bí atúmọ̀ èdè?

“A máa ń sapá ká lè túmọ̀ ìwé wa lọ́nà tó fi máa dà bíi pé èdè abínibí ni wọ́n fi kọ ìwé náà látilẹ̀. Kó sì dà bíi pé ẹni tó gbọ́ èdè yẹn ló ń bá wọn sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Torí náà, a máa ń sapá láti túmọ̀ lọ́nà tó rọrùn. Èyí ló máa ń mú kí ìwé wa dùn ún kà kó sì fa òǹkàwé lọ́kàn mọ́ra bí oúnjẹ aládùn ṣe máa ń dùn lẹ́nu.”

Àǹfààní wo lẹ̀ ń rí bẹ́ ẹ ṣe ń gbé níbi táwọn tó ń sọ èdè yín wà?

“Àǹfànní ńlá ló wà nínú bá a ṣe wà níbi tí àwọn tó ń sọ èdè wa wà, ojoojúmọ́ là ń gbọ́ bí wọ́n ṣe ń sọ èdè náà. A tún láǹfààní láti fi ọ̀rọ̀ dán àwọn èèyàn létí wò, ká lè mọ bó ṣe yé wọn sí àti pé bóyá ó dùn ún gbọ́ létí. Èyí máa ń jẹ́ ká lè túmọ̀ lọ́nà tó dára.”

Báwo lẹ ṣe ń ṣètò iṣẹ́ yín?

“Wọ́n máa ń yan iṣẹ́ fún àwùjọ kan. Ẹnì kọ̀ọ̀kan á kọ́kọ́ ka iṣẹ́ náà látòkèdélẹ̀ kó lè lóye rẹ̀, kó sì mọ àwọn tí wọ́n dìídì kọ ọ́ fún. Lẹ́yìn náà, àá wá bi ara wa pé: ‘Kí ní òǹkọ̀wé ní lọ́kàn tó fi kọ àpilẹ̀kọ yìí? Kí ló dá lé, kí sì ni kókó tó fẹ́ mú jáde? Ẹ̀kọ́ wo la fẹ́ rí kọ́ nínú rẹ̀?’ Àwọn ìgbésẹ̀ yìí la máa ń fi tọsẹ̀ iṣẹ́ wa.

“Lẹ́yìn ìyẹn, àá wá jíròrò bá a ṣe lóye rẹ̀. A máa ń bi ara wa pé: Ṣé ohun tí wọ́n ń sọ yé wa? Báwo la ṣe lè gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ bí Gẹ̀ẹ́sì náà ṣe gbé e kalẹ̀? Ohun tá a fẹ́ ni pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn tó ka èdè Gẹ̀ẹ́sì, bẹ́ẹ̀ náà ni kó rí lára àwọn tó ka èyí tá a túmọ̀.”

Báwo ni àwùjọ náà ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀?

“Ohun tá a fẹ́ ni pé kí ẹni tó bá kà á lóye rẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ tó bá kà á. Torí náà, àkàtúnkà la máa ń kà á lẹ́yìn tá a bá ti túmọ̀ rẹ̀ tán.

“Ẹnì kan á ṣe ìtúmọ̀, àwa tó kù á sì máa wò ó lójú kọ̀ǹpútà wa. A máa wò ó láti rí i pé a kò fo ọ̀rọ̀ tàbí fi ọ̀rọ̀ míì kún un. Àá sì rí i pé ọ̀rọ̀ wa dùn ún gbọ́ létí, pé a ó ṣi ọ̀rọ̀ kọ, tó sì bá bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ mu. Lẹ́yìn náà, ẹnì kan á kà á sí wa létí. Tó bá kọsẹ̀ nígbà tó ń kà á lọ, àá yẹ ibẹ̀ wò dáadáa. Tí a bá ti túmọ̀ gbogbo àpilẹ̀kọ inú ìwé náà tán, ọ̀kan lára wa máa ka ìwé náà sókè ketekete, àwa tó kù á sì máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tó yẹ ká tún ṣe.”

Ó jọ pé iṣẹ́ tó gbomi gidigidi ni!

“Bẹ́ẹ̀ ni! Ìgbà tá a bá máa fi parí iṣẹ́ lọ́jọ́ kan, á ti rẹ̀ wá. Torí náà, tó bá dàárọ̀ ọjọ́ kejì tí ọpọlọ wa ṣì tutù, àá tún gbe é yẹ̀ wò. Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà, Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ á fi àwọn àtúnṣe kan ránṣẹ́ sí wa lórí iṣẹ́ náà. A óò wá ṣe àwọn àtúnṣe náà, àá sì tún un kà lákọ̀tun.”

Àwọn ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà wo lẹ máa ń lò?

“A ò lè fi kọ̀ǹpútà rọ́pò àwọn èèyàn tó jẹ́ atúmọ̀ èdè. Síbẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe àwọn ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà kan láti mú iṣẹ́ náà rọrùn díẹ̀. Ọ̀kan lára ohun èlò náà ni ìwé atúmọ̀ èdè kan tá a kó àwọn ọ̀rọ̀ àtàwọn gbólóhùn tá a sábà máa ń lò sí. Òmíràn ni ètò ìṣiṣẹ́ kan tá a lè fi ṣe ìwádìí lórí gbogbo ìtẹ̀jáde tá a ti túmọ̀, èyí sì máa ń mú kó rọrùn láti rí ojútùú sáwọn ìṣòro kọ̀ọ̀kan tá a máa ń bá pàdé.”

Báwo lẹ̀yin fúnra yín ṣe rí iṣẹ́ yìí sí?

“Ẹ̀bùn ni iṣẹ́ yìí jẹ́ fún gbogbo èèyàn. Torí náà, a fẹ́ kó ṣe wọ́n láǹfààní. Tá a bá sì rí bí ohun tá a túmọ̀ nínú ìwé tàbí lórí ìkànnì wa ṣe wọ ẹnì kan lọ́kàn, tó sì yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà sí rere, orí wa máa ń wú.”

Àǹfààní Ayérayé

Àìmọye èèyàn kárí ayé ló ń rí àwọn ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kà ní èdè wọn, ó sì ń ṣe wọ́n láǹfààní. Ìlànà Bíbélì ló wà nínú àwọn ìwé, fídíò àtàwọn àpilẹ̀kọ tá à ń gbé sórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org. Ó ṣe tán, inú Bíbélì yẹn kan náà ni Ọlọ́run, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà ti sọ fún wa pé òun fẹ́ kí á sọ ọ̀rọ̀ òun fún gbogbo “orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.”—Ìṣípayá 14:6. *

^ ìpínrọ̀ 4 Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fi ń kọ̀wé, kí wọ́n tó túmọ̀ rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 25 Lọ sórí ìkànnì wa www.mt711.com, wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ, èyí tá a gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀ àti fídíò tó wà ní èdè rẹ àti ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èdè míì.