Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Énọ́kù Bá Ọlọ́run Rìn Nínú Ayé Aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run

Énọ́kù Bá Ọlọ́run Rìn Nínú Ayé Aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run

Énọ́kù Bá Ọlọ́run Rìn Nínú Ayé Aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run

ÈṢÙ ń fọ́nnu pé òun lè mú kí gbogbo aráyé kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, ó sì jọ pé nígbà míì yóò kẹ́sẹ járí. Fún nǹkan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún lẹ́yìn ikú Ébẹ́lì ni kò fi sí ẹnì kankan táa lè rí tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àti àìbẹ̀rù Ọlọ́run ló gbòde kan.

Àkókò tí nǹkan dẹnu kọlẹ̀ nípa tẹ̀mí yìí ni Énọ́kù gbé ayé. Ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé ọdún 3404 ṣááju Sànmánì Tiwa la bí i. Énọ́kù yàtọ̀ pátápátá sí àwọn tí wọ́n jọ gbáyé, òun ní tirẹ̀ rí ojú rere Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kà á mọ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí ìgbàgbọ́ wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwa Kristẹni. Ta ni Énọ́kù? Kí làwọn ìṣòro tó dojú kọ? Báwo ló ṣe kojú wọn? Báwo sì ni ìwà títọ́ rẹ̀ ṣe kàn wá lónìí?

Nígbà ayé Énọ́ṣì, tó jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ọdún ṣáájú ìgbà Énọ́kù, “ni a bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:26) Láti ìbẹ̀rẹ̀ pàá ìtàn ẹ̀dá ènìyàn la ti ń lo orúkọ Ọlọ́run. Fún ìdí yìí, ó hàn gbangba pé ohun tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe nígbà ayé Énọ́ṣì kì í ṣe kíké pe Jèhófà nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìjọsìn mímọ́. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan tó ti kẹ́kọ̀ọ́ èdè Hébérù jinlẹ̀ sọ pé bó ṣe yẹ kí Jẹ́nẹ́sísì 4:26 ṣe kà ni pé wọ́n ‘bẹ̀rẹ̀ sí lo orúkọ Jèhófà nílòkulò’ tàbí ‘ìgbà yẹn ni lílo orúkọ Jèhófà nílòkulò bẹ̀rẹ̀.’ Ó lè jẹ́ pé ńṣe làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí fi orúkọ Jèhófà pe ara wọn, tàbí kí wọ́n máa fi pe àwọn ẹ̀dá ènìyàn mìíràn tí wọ́n sọ pé àwọn ń tipasẹ̀ wọn tọ Ọlọ́run lọ nínú ìjọsìn. Tàbí kí wọ́n máa fi orúkọ rẹ̀ pe àwọn òòṣà.

‘Énọ́kù Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn’

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà àìfi-Ọlọ́run-pè gbòde kan nígbà ayé Énọ́kù, síbẹ̀ ó “ń bá a nìṣó ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́,” Jèhófà. Bíbélì kò sọ pé àwọn baba ńlá rẹ̀—ìyẹn Sẹ́ẹ̀tì, Énọ́ṣì, Kénánù, Máhálálélì, àti Járédì—bá Ọlọ́run rìn. Ó kéré tán, wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀ tó Énọ́kù, ẹni tí ọ̀nà ìgbé ayé rẹ̀ mú kó ta wọ́n yọ.—Jẹ́nẹ́sísì 5:3-27.

Bíbá Jèhófà rìn wé mọ́ dídi ojúlùmọ̀ Ọlọ́run àti sísúnmọ́ ọn dáadáa, kìkì nítorí pé Énọ́kù mú ìgbésí ayé rẹ̀ bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu ló sì mú kí èyí ṣeé ṣe. Inú Jèhófà dùn sí ìjọsìn Énọ́kù. Àní Bíbélì Septuagint lédè Gíríìkì sọ pé “Énọ́kù ṣe ohun tó dáa gidigidi” lójú Ọlọ́run, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà tún mẹ́nu ba kókó yìí.—Jẹ́nẹ́sísì 5:22; Hébérù 11:5.

Ohun pàtàkì tó mú kí Énọ́kù ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà ni ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ó ti ní láti lo ìgbàgbọ́ nínú “irú-ọmọ” ti “obìnrin” Ọlọ́run táa ṣèlérí náà. Bí ó bá jẹ́ pé Énọ́kù rí Ádámù sójú, ó ṣeé ṣe kí ó rí àwọn ìsọfúnni kan gbà nípa bí Ọlọ́run ṣe bá tọkọtaya àkọ́kọ́ lò ní Édẹ́nì. Ohun tí Énọ́kù mọ̀ nípa Ọlọ́run ló sọ ọ́ di ẹni “tí ń fi taratara wá a.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Hébérù 11:6, 13.

Nínú ọ̀ràn Énọ́kù àti nínú ọ̀ràn tiwa, níní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà kò mọ sórí wíwulẹ̀ ní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run. Báa bá gbà pé ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ táa ní pẹ̀lú ẹnì kan ṣe pàtàkì gan-an, ǹjẹ́ èrò onítọ̀hún kò ní máa nípa lórí èrò àti ìṣe wa? A óò máa yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ àti ìwà tí yóò ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. Táa bá sì ń ronú àtiṣe àwọn ìyípadà kan nínú ọ̀ràn ara wa, ǹjẹ́ a ò tún ní ronú lórí bí èyí ṣe máa nípa lórí àjọṣe náà?

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìfẹ́ àtọkànwá láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe wé mọ́ ohun táa ń ṣe. Ọ̀kan lára ohun tí à ń béèrè ni ìmọ̀ pípéye nípa ohun tó fẹ́ àtohun tí kò fẹ́. A óò wá jẹ́ kí ìmọ̀ yẹn máa tọ́ wa sọ́nà, a óò máa làkàkà láti ṣe ohun tó wù ú nínú èrò àti ìṣe wa.

Bẹ́ẹ̀ ni o, báa bá fẹ́ bá Ọlọ́run rìn, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó wù ú. Ohun tí Énọ́kù ṣe fún ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan nìyẹn. Àní ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù tó sọ pé Énọ́kù bá Ọlọ́run ‘rìn,’ wé mọ́ ohun tí à ń ṣe ní àṣetúnṣe, láìdáwọ́dúró. Ọkùnrin olódodo mìíràn tó ‘bá Ọlọ́run rìn’ ni Nóà.—Jẹ́nẹ́sísì 6:9.

Onídìílé ni Énọ́kù, ó láya sílé, ó sì bí “àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.” Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ni Mètúsélà. (Jẹ́nẹ́sísì 5:21, 22) Énọ́kù kò ní ṣàì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti bójú tó agboolé rẹ̀ dáadáa. Àmọ́ nítorí ìwà àìfi-Ọlọ́run-pè tó gbòde kan, kò rọrùn fún un láti sin Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ pé Lámékì, bàbá Nóà, nìkan ni ẹlòmíràn tó tún lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà láyé ìgbà yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 5:28, 29) Síbẹ̀, Énọ́kù fìgboyà rọ̀ mọ́ ìjọsìn tòótọ́.

Kí ló ran Énọ́kù lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run? Dájúdájú, kò bá àwọn tí ń lo orúkọ Jèhófà nílòkulò kẹ́gbẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò bá àwọn ẹgbẹ́ búburú tó lè ṣàkóbá fún olùjọsìn Ọlọ́run rìn. Wíwá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà nínú àdúrà kò ní ṣàì fún ìpinnu Énọ́kù lágbára láti yàgò fún ohunkóhun tí yóò bí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ nínú.

Ó Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Lòdì sí Àwọn Aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run

Kì í rọrùn rárá láti tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere nígbà táwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run bá yí wa ká. Àmọ́ Énọ́kù tún jẹ́ iṣẹ́ ìdájọ́ mímúná lòdì sí àwọn olubi. Ẹ̀mí Ọlọ́run darí Énọ́kù láti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Wò ó! Jèhófà wá pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́, láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn, àti láti dá gbogbo aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi nípa gbogbo ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọn, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àti nípa gbogbo ohun amúnigbọ̀nrìrì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti sọ lòdì sí i.”—Júúdà 14, 15.

Ipa wo ni iṣẹ́ yẹn máa ní lórí àwọn aláìgbàgbọ́ tí ń hu ìwàkiwà? Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, irú ọ̀rọ̀ títanilára bẹ́ẹ̀ á mú kí wọ́n máa fojú burúkú wo Énọ́kù, wọ́n á tilẹ̀ máa fi í ṣẹ̀sín, wọ́n á máa pẹ̀gàn rẹ̀, wọ́n á sì máa halẹ̀ mọ́ ọn. Àwọn kan á tiẹ̀ fẹ́ rẹ́yìn rẹ̀ pátápátá. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀rù ò ba Énọ́kù. Ó mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ébẹ́lì olódodo, Énọ́kù sì ti pinnu pé àforí-àfọrùn, òun ti ṣe tán láti sin Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí Ébẹ́lì ti ṣe.

“Ọlọ́run Mú Un Lọ”

Àfàìmọ̀ kí ó máà jẹ́ pé inú ewu ikú ni Énọ́kù wà nígbà tí “Ọlọ́run mú un lọ.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:24) Jèhófà kò jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ jìyà lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó ń ṣe bí ajá dìgbòlugi. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé, “a ṣí Énọ́kù nípò padà láti má ṣe rí ikú.” (Hébérù 11:5) Ọ̀pọ̀ ń sọ pé Énọ́kù kò kú—wọ́n ní ńṣe ni Ọlọ́run mú un lọ sọ́run, tó sì wá ń gbé níbẹ̀. Àmọ́ o, Jésù là á mọ́lẹ̀ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó sọ kalẹ̀ láti ọ̀run, Ọmọ ènìyàn.” Jésù ni “aṣíwájú” nínú gbogbo àwọn tó gòkè re ọ̀run.—Jòhánù 3:13; Hébérù 6:19, 20.

Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí Énọ́kù? ‘Ṣíṣí táa ṣí i nípò padà láti má ṣe rí ikú’ lè túmọ̀ sí pé Ọlọ́run mú un wọnú ojúran, tó sì wá fòpin sí ìwàláàyè rẹ̀ bó ṣe wà nínú ojúran yẹn. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, Énọ́kù kò ní pọ̀kàkà ikú. Lẹ́yìn náà, “ó sì dàwátì,” ní ti pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jèhófà palẹ̀ òkú rẹ̀ mọ́, gẹ́gẹ́ bó ti palẹ̀ òkú Mósè mọ́.—Diutarónómì 34:5, 6.

Òjìdínnírínwó ó lé márùn-ún [365] ọdún ni Énọ́kù lò láyé—kò pẹ́ láyé bíi tàwọn ojúgbà rẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun tó ṣe pàtàkì lójú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni fífi ìṣòtítọ́ sìn ín títí dọjọ́ ikú wọn. A mọ̀ pé Énọ́kù ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé “ṣáájú ìṣínípòpadà rẹ̀, ó ní ẹ̀rí náà pé ó ti wu Ọlọ́run dáadáa.” Ìwé Mímọ́ kò sọ fún wa nípa bí Jèhófà ṣe fi èyí tó Énọ́kù létí. Ṣùgbọ́n kí Énọ́kù tó kú, Ọlọ́run mú un dá a lójú pé ó rí ojú rere òun, ó sì dá wa lójú pé Jèhófà yóò rántí rẹ̀ nígbà àjíǹde.

Fara Wé Ìgbàgbọ́ Énọ́kù

Ó yẹ ká fara wé ìgbàgbọ́ àwọn olùfọkànsin Ọlọ́run. (Hébérù 13:7) Nípa ìgbàgbọ́ ni Énọ́kù sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì àkọ́kọ́ tó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Ayé tí Énọ́kù gbé nígbà yẹn kò yàtọ̀ sáyé táa wà lónìí—ó kún fún ìwà ipá, ìwà ìbàjẹ́, àti ìwà àìfi Ọlọ́run pè. Ṣùgbọ́n Énọ́kù yàtọ̀. Ó ní ìgbàgbọ́ tòótọ́, ó sì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú fífọkànsin Ọlọ́run. Lóòótọ́, Jèhófà rán an ní iṣẹ́ ìdájọ́ tó lágbára gan-an, ṣùgbọ́n ó fún un lókun láti fi kéde rẹ̀. Énọ́kù fìgboyà jẹ́ iṣẹ́ táa rán an, Ọlọ́run sì tọ́jú rẹ̀ nígbà táwọn ọ̀tá gbé àtakò dìde sí i.

Báa bá lo ìgbàgbọ́ bíi ti Énọ́kù, Jèhófà yóò fún wa lókun láti jẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fìgboyà dojú kọ àtakò, ẹ̀mí ìfọkànsin wa yóò sì jẹ́ ká yàtọ̀ pátápátá sí àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run. Ìgbàgbọ́ yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti bá Ọlọ́run rìn, ká sì máa hùwà lọ́nà tí yóò mú un lọ́kàn yọ̀. (Òwe 27:11) Nípa ìgbàgbọ́ ni Énọ́kù olódodo kẹ́sẹ járí ní bíbá Jèhófà rìn nínú ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àwa náà sì lè ṣe bẹ́ẹ̀.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

Ǹjẹ́ Bíbélì Fa Ọ̀rọ̀ Yọ Látinú Ìwé Énọ́kù?

Ìwé tí wọ́n ń pè ní Ìwé Énọ́kù kì í ṣe ara Ìwé Mímọ́, kì í sì í ṣe Énọ́kù ló kọ ọ́ ní ti gidi. Wọ́n kàn parọ́ mọ́ Énọ́kù pé òun lọ́ kọ ọ́ ni. Ó ní láti jẹ́ ọ̀rúndún kejì tàbí èkíní ṣááju Sànmánì Tiwa ni wọ́n kọ ọ́. Inú ìtàn àròsọ àwọn Júù tó kún fún àbùmọ́ ló ti wá. Ó sì hàn gbangba pé ọ̀rọ̀ ṣókí tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa Énọ́kù ni wọ́n fẹ̀ lójú fẹ̀ nímú. Òkodoro òtítọ́ yìí ti tó láti mú kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yàgò pátápátá fún ìwé yìí.

Nínú Bíbélì, ìwé Júúdà nìkan ló sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Énọ́kù, pé: “Wò ó! Jèhófà wá pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́, láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn, àti láti dá gbogbo aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi nípa gbogbo ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọn, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àti nípa gbogbo ohun amúnigbọ̀nrìrì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti sọ lòdì sí i.” (Júúdà 14, 15) Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ló ń jiyàn pé inú Ìwé Énọ́kù la ti ṣàyọlò àsọtẹ́lẹ̀ tí Énọ́kù sọ lòdì sí àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ìgbà ayé rẹ̀. Ó ha ṣeé ṣe kí Júúdà fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ látinú ìwé tí kò ṣeé gbára lé, tí kì í ṣe ara Bíbélì?

Ìwé Mímọ́ kò ṣàlàyé bí Júúdà ṣe mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Énọ́kù. Ó kúkú lè jẹ́ pé orísun kan tí gbogbo èèyàn mọ̀ nígbà yẹn ló lò, bóyá ìtàn kan tó ṣeé gbára lé láti ìgbà ìṣẹ̀ǹbáyé. Ó jọ pé Pọ́ọ̀lù ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ nígbà tó dárúkọ Jánésì àti Jámíbírésì, ìyẹn àwọn pidánpidán tí a kò dárúkọ wọn, tí wọ́n tako Mósè ní ààfin Fáráò. Bí ẹni tó kọ Ìwé Énọ́kù bá mọ̀ nípa irú ìtàn àtayébáyé bẹ́ẹ̀, kí nìdí fún sísẹ́ pé Júúdà pẹ̀lú kò lè mọ̀ nípa irú ìtàn yẹn? aẸ́kísódù 7:11, 22; 2 Tímótì 3:8.

Bí Júúdà ṣe mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tí Énọ́kù sọ lòdì sí àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run kì í ṣe nǹkan bàbàrà. Ó ṣeé gbára lé nítorí pé abẹ́ ìmísí ni Júúdà wà nígbà tó ń kọ̀wé. (2 Tímótì 3:16) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run rí sí i pé kò kọ ọ̀rọ̀ tí kì í ṣòótọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Sítéfánù ọmọ ẹ̀yìn pẹ̀lú lo ìsọfúnni tí a kò rí níbòmíì nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ó lò ó nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí Mósè gbà ní Íjíbítì, jíjẹ́ tó jẹ́ ẹni ogójì ọdún nígbà tó sá fi Íjíbítì sílẹ̀, ogójì ọdún tó fi wà ní ilẹ̀ Mídíánì, àti ipa tí áńgẹ́lì kó nínú títa àtaré Òfin Mósè.—Ìṣe 7:22, 23, 30, 38.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Énọ́kù fìgboyà jẹ́ iṣẹ́ Jèhófà