Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Bibeli Dahun Gbogbo Ibeere Mi

Bibeli Dahun Gbogbo Ibeere Mi
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1987

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: AZERBAIJAN

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MÙSÙLÙMÍ NI BÀBÁ MI, ÌYÁ MI SÌ JẸ́ ẸLẸ́SÌN JÚÙ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Ìlú Baku, lórílẹ̀-èdè Azerbaijan ni wọ́n bí mi sí, èmi sì ni àbígbẹ̀yìn nínú ọmọbìnrin méjì táwọn òbí mi bí. Mùsùlùmí ni bàbá mi, àmọ́ ẹlẹ́sìn Júù ni ìyá mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀sìn àwọn òbí mi yàtọ̀ síra, wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ìyá mi máa ń tẹ̀ lé bàbá mi lọ sí mọ́ṣáláṣí tí wọ́n bá ń gbààwẹ̀ lóṣù Ramadan, bàbá mi náà sì máa ń gbárùkù ti ìyá mi tí wọ́n bá ń ṣàjọyọ̀ ọdún Ìrékọjá. Kódà, a ní Kùránì, Tórà àti Bíbélì nínú ilé wa.

Ẹ̀sìn Mùsùlùmí ni mò ń ṣe ní tèmi, mo sì gba Ọlọ́run gbọ́ dáadáa. Àmọ́ àwọn ìbéèrè kan máa ń wà lọ́kàn mi. Mo máa ń ronú pé, ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn? Kí nìdí téèyàn fi máa jìyà láyé tí á tún wá lọ joró ní ọ̀run àpáàdì?’ Àwọn èèyàn máa ń sọ pé àmúwá Ọlọ́run ni gbogbo ohun tó bá dé bá ẹ̀dá, èyí máa ń mú kí n ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣé Ọlọ́run kàn ń ṣe wá bó ṣe wù ú, kó lè máa fi wá ṣèranwò ni?’

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìlá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kírun ẹ̀ẹ̀marùn-ún ojúmọ́. Àkókò yẹn ni bàbá mi rán èmi àti ẹ̀gbọ́n mi lọ sí iléèwé àwọn Júù. Lára ohun tí wọ́n kọ́ wa níbẹ̀ ni èdè Hébérù àti àṣà àwọn Júù tó wà nínú Tórà. Ṣáájú ká tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níléèwé láàárọ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, àá kọ́kọ́ gbàdúrà ní ìlànà àwọn Júù. Torí náà, láàárọ̀ kùtùkùtù, màá kọ́kọ́ kírun nílé, ti mo bá tún dé iléèwé, màá tún gba àdúrà àwọn Júù.

Síbẹ̀, àwọn ìbéèrè tí mo mẹ́nu bà yẹn ò kúrò lọ́kàn mi. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń bi àwọn rábì iléèwé wa pé: “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn? Irú èèyàn wo ni Ọlọ́run ka bàbá mi tó jẹ́ Mùsùlùmí sí? Èèyàn dáadáa ni bàbá mi, kí wá ló dé táwọn Júù fi kà á sí aláìmọ́ torí pé ó jẹ́ Mùsùlùmí? Nígbà tí Ọlọ́run mọ̀ pé aláìmọ́ ni, kí nìdí tó fi dá a?” Àmọ́, gbogbo ìdáhùn tí wọ́n fún mi kò yé mi.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Ohun kan ṣẹlẹ̀ sí mi ní ọdún 2002 tó mú kí n sọ ìgbàgbọ́ nù. Ọ̀sẹ̀ kan péré lẹ́yìn tá a kó dé ìlú Jámánì ni àrùn rọpárọsẹ̀ kọ lu bàbá mi, ló bá dá kú lọ gbári. Bẹ́ẹ̀ àti kékeré ni mo ti máa ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run lọ́ra ẹ̀mí gbogbo ìdílé mi. Mo mọ̀ nínú ọkàn mi pé Ọlọ́run Ọba nìkan ló lágbára láti pani tàbí kó gbani, torí náà, ojoojúmọ́ ni mò ń bẹ̀ ẹ́ pé kó dá ẹ̀mí bàbá mi sí. Mo mọ̀ pé kò ná Ọlọ́run ní nǹkan kan láti dáhùn àdúrà mi, èyí mú kó dá mi lójú pé ara bàbá mi máa yá. Àmọ́ àìsàn yẹn ló pa bàbá mi.

Ó dùn mí gan-an pé Ọlọ́run ò dáhùn àdúrà mi. Mo wò ó pé ‘bóyá bó ṣe yẹ kí n gbàdúrà kọ́ ni mò ń gbà á tàbí bóyá kò tiẹ̀ sí Ọlọ́run.’ Ìgbà tó yá, mi ò kírun mọ́, ìsìn kankan ò sì jọ mí lójú mọ́. Mo gbà nínú ọkàn mi pé kò sí Ọlọ́run.

Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìgbà yẹn ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí ilé wa. Àmọ́, a ò ka àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni sí rárá ní tiwa, èmi àti ẹ̀gbọ́n mi wá pinnu láti ṣàlàyé fún wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé ìsìn wọn ò tọ̀nà. A bi wọ́n pé: “Ṣé ó yẹ káwọn Kristẹni máa jọ́sìn Jésù, àgbélébùú, Màríà àtàwọn òrìṣà míì nígbà tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ta ko Òfin Mẹ́wàá?” Àwọn Ajẹ́rìí yìí fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé fún wa pé Ọlọ́run ka jíjọ́sìn àwọn òrìṣà léèwọ̀ fún àwọn Kristẹni tòótọ́ àti pé Ọlọ́run nìkan la gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí. Ìdáhùn wọn yìí wọ̀ mí lọ́kàn.

La bá tún bi wọ́n pé: “Mẹ́talọ́kan ńkọ́? Tó bá jẹ́ pé Jésù ni Ọlọ́run, báwo ló ṣe máa gbé ní ayé táwọn èèyàn á sì pa á?” Wọ́n tún fi Bíbélì ṣàlàyé pé Jésù kì í ṣe Ọlọ́run, kò sì bá Ọlọ́run dọ́gba. Wọ́n ní torí ìdí yìí làwọn ò ṣe gbà gbọ́ nínú Mẹ́talọ́kan. Ìyàlẹ́nu ni gbogbo nǹkan yìí jẹ́ fún mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, ‘Awọn Kristẹni yìí mà tún yàtọ̀ o.’

Síbẹ̀, ó ṣì wù mí láti mọ ìdí tí àwa èèyàn fi ń kú àti ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà. Àwọn Ajẹ́rìí yìí fi ìwé kan hàn mí tó dáhùn gbogbo ìbéèrè mi, ìyẹn ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. * Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn nìyẹn.

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìdáhùn Bíbélì tó tẹ́ mi lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè mi. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé orúkọ Ọlọ́run ni Jèhófà. (Sáàmù 83:18) Ìfẹ́ sì ni ìwà rẹ̀ tó ta yọ jù lọ. (1 Jòhánù 4:8) Ó dá àwa èèyàn torí pé ó fẹ́ káwa náà gbádùn ìgbésí ayé. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kórìíra ìwà ibi, àmọ́, ó nídìí tó fi fàyè gbà á, ó sì máa fòpin sí i láìpẹ́. Mo tún kọ́ nípa wàhálà tí àìgbọràn Ádámù àti Éfà ti fà fún gbogbo èèyàn pátápátá. (Róòmù 5:12) Ọ̀kan lára àwọn wàhálà yìí ni ikú àwọn tá a fẹ́ràn, bí ikú bàbá mi. Àmọ́ nínú ayé tuntun tó ń bọ̀, Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo àwọn àjálù bẹ́ẹ̀, àwọn tó sì ti kú máa jíǹde.—Ìṣe 24:15.

Níkẹyìn, Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè mi. Bí ìgbàgbọ́ mi nínú Ọlọ́run ṣe tún sọ jí nìyẹn o. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í sún mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo wá rí i pé bí ọmọ ìyà ni gbogbo wọn rí síra wọn kárí ayé. Ìfẹ́ tí mo rí àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn wú mi lórí gan-an. (Jòhánù 13:34, 35) Àwọn nǹkan tí mo sì kọ́ nípa Jèhófà mú kó wù mí láti sìn ín. Bí mo ṣe pinnu láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn, mo sì ṣèrìbọmi ní January 8, ọdún 2005.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Àwọn èrò tí kò tọ́ ni mo ní tẹ́lẹ̀, àmọ́ àwọn àlàyé tó ṣe ṣàkó tó wà nínú Bíbélì ti mú kí n tún àwọn èrò náà pa. Àwọn òótọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀. Ìlérí àjíǹde tó wà nínú Bíbélì máa ń fún mi láyọ̀ gan-an, ó sì tún máa ń jẹ́ kí n retí ìgbà tí màá rí bàbá mi lẹ́ẹ̀kan sí i nínú ayé tuntun.—Jòhánù 5:28, 29.

Ọdún kẹfà rèé tí mo ti wà nílé ọkọ. Èmi àti Jonathan ọkọ mi jọ ń gbádùn ìgbésí ayé wa, òun náà sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an. Àwa méjèèjì ti rí i pé òtítọ́ nípa Ọlọ́run kò lọ́jú pọ̀ rárá àti pé àǹfààní tó wà nínú rẹ̀ kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti àwọn ìlérí rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíì. Mo ti wá rí i pé Kristẹni tòótọ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọn kì í Kristẹni aláfẹnujẹ́.

^ ìpínrọ̀ 15 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.