Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KEJE

Ojúlówó Ìrètí Fáwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú

Ojúlówó Ìrètí Fáwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú
  • Báwo la ṣe mọ̀ pé lóòótọ́ làwọn òkú máa jíǹde?

  • Báwo ni ọ̀ràn jíjí òkú dìde ṣe rí lára Jèhófà?

  • Àwọn wo la óò jí dìde?

1-3. Ọ̀tá wo ló ń lé gbogbo wa, kí sì nìdí tí ṣíṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì fi kọ́ni yóò fi mú ìtura bá wa?

FOJÚ inú wò ó pé ọ̀tá kan tó jẹ́ òǹrorò ń lé ọ. Ọ̀tá yìí lágbára jù ọ́ lọ fíìfíì, ó sì lè sáré jù ọ́ lọ. O mọ̀ pé aláìláàánú ẹ̀dá ni nítorí o ti rí i tó pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ kan rí. Àmọ́ bó o ṣe ń fi gbogbo agbára rẹ sá eré àsápajúdé kọ́wọ́ rẹ̀ má bàa tẹ̀ ọ́, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń sún mọ́ ọ. Ó wá dà bí ẹni pé kò sí bó o ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n láìròtẹ́lẹ̀ lo kàn ṣàdédé rí ẹnì kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ. Onítọ̀hún wá gbà ọ́ sílẹ̀ ni, ó sì lágbára gan-an ju ọ̀tá tó ń lé ọ lọ. Ǹjẹ́ ọkàn rẹ ò ní balẹ̀?

2 A lè sọ pé irú ọ̀tá kan bẹ́ẹ̀ wà tí ń lé ọ. Gbogbo wa ni ọ̀tá ọ̀hún sì ń lé. Bí a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí Kẹfà, ọ̀tá ni Bíbélì pé ikú. Kò sẹ́ni tó lè sá mọ́ ikú lọ́wọ́ tàbí tó lè borí rẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ wa la ti rí i tí ọ̀tá yìí gba ẹ̀mí àwọn èèyàn wa. Ṣùgbọ́n Jèhófà lagbára ju ikú lọ fíìfíì. Òun ni Alágbàálẹ̀ wa, ó sì ti fi hàn pé òun lè ṣẹ́gun ikú tí í ṣe ọ̀tá wa. Ó ṣèlérí pé òun yóò mú ikú tó jẹ́ ọ̀tá wa yìí kúrò pátápátá, kò sì ní padà wá mọ́ láéláé. Bíbélì fi kọ́ni pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́ríńtì 15:26) Ìhìn rere ńlá mà lèyí o!

3 Jẹ́ ka kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ní ṣókí bó ṣe máa ń rí lára wa nígbà tẹ́nì kan tá a fẹ́ràn bá kú. Àyẹ̀wò tá a bá ṣe á jẹ́ ká mọ ìlérí kan tí yóò fún wa láyọ̀. Ṣó o rí i, Jèhófà ṣèlérí pé àwọn òkú yóò tún padà wà láàyè. (Aísáyà 26:19) A óò mú wọn padà wá sí ìyè. Ìrètí àjíǹde nìyẹn.

NÍGBÀ TÉÈYÀN ẸNI BÁ KÚ

4. (a) Kí la rí kọ́ nípa bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jèhófà látinú ohun tí Jésù ṣe nígbà tí ẹnì kan tó fẹ́ràn kú? (b) Irú ọ̀rẹ́ wo ni Jésù jẹ́ sí Lásárù àtàwọn arábìnrin rẹ̀?

4 Ǹjẹ́ èèyàn rẹ kan ti kú rí? Kò sí nǹkan téèyàn lè ṣe téèyàn ẹni bá kú, bíi pé ìbànújẹ́ tó báni ò ní ṣeé fara dà ló máa ń rí. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, a ní láti wá ìtùnú lọ sínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Bíbélì jẹ́ ká mọ bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà àti Jésù téèyàn bá kú. Jésù tó jọ Bàbá rẹ̀ pátápátá mọ bí inú ẹni ṣe máa ń bà jẹ́ tó téèyàn ẹni bá kú. (Jòhánù 14:9) Nígbà tí Jésù wà ní Jerúsálẹ́mù, ó máa ń lọ bẹ Lásárù àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin wò. Ìlú kekére kan tí wọ́n ń pè ní Bẹ́tánì tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìn sí Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ń gbé. Wọ́n sì di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. Bíbélì sọ pé: “Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù.” (Jòhánù 11:5) Ṣùgbọ́n bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ní orí tó ṣáájú, Lásárù kú.

5, 6. (a) Kí ni Jésù ṣe nígbà tó wà lọ́dọ̀ àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ Lásárù tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ ikú Lásárù? (b) Kí nìdí tí ìbànújẹ́ tó bá Jésù fi fi wá lọ́kàn balẹ̀?

5 Báwo ló ṣe rí lára Jésù nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú? Bíbélì sọ pé Jésù lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹbí Lásárù àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣòfọ̀ rẹ̀. Nígbà tí Jésù rí wọn, inú rẹ̀ bà jẹ́ gan-an. Ó “kérora nínú ẹ̀mí, ó sì dààmú.” Lẹ́yìn náà, àkọsílẹ̀ yìí sọ pé: “Jésù bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.” (Jòhánù 11:33, 35) Ṣé nítorí pé Jésù o nírètí ni inú rẹ̀ ṣe bà jẹ́? Rárá o. Kódà, Jésù mọ̀ pé ohun àgbàyanu kan máa tó ṣelẹ̀. (Jòhánù 11:3, 4) Síbẹ̀, ó ṣì mọ ìbànújẹ́ tí ikú máa ń fà lára.

6 Lọ́nà kan, bí inú Jésù ṣe bà jẹ́ yẹn jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀. Ó kọ́ wa pé Jésù àti Jèhófà Bàbá rẹ̀ kórìíra ikú. Yàtọ̀ sí pé Jèhófà Ọlọ́run kórìíra ọ̀tá yìí, ó tún lágbára láti bá a jà kó sì borí rẹ̀! Jẹ́ ká wo ohun tí Ọlọ́run fún Jésù lágbára láti ṣe.

“LÁSÁRÙ, JÁDE WÁ!”

7, 8. Kí nìdí tó lè fi dà bíi pé kò sírètí mọ́ lójú àwọn tó wà níbi tí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ Lásárù, ṣùgbọ́n kí ni Jésù ṣe?

7 Inú ihò àpáta kan ni wọ́n sin Lásárù sí, Jésù sì sọ pé kí wọ́n gbé òkúta tí wọ́n fi dí ihò náà kúrò. Màtá sọ pé kí wọ́n má ṣe gbé òkúta náà kúro nítorí pé ọjọ́ kẹrin nìyẹn tí wọ́n ti sin Lásárù, ara rẹ̀ á sì ti máa jẹrà. (Jòhánù 11:39) Àbí, lójú èèyàn, ìrètí wo ló tún wà?

Inú àwọn èèyàn dùn gan-an nígbà tí Lásárù jíǹde.—Jòhánù 11:38-44

8 Wọ́n yí òkúta náà kúrò, Jésù sì kígbe ní ohùn rara pé: “Lásárù, jáde wá!” Kí ló ṣẹlẹ̀? “Ọkùnrin tí ó ti kú náà jáde wá.” (Jòhánù 11:43, 44) Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí inú àwọn tó wà níbẹ̀ á ṣe dùn tó? Yálà àbúrò wọn ni Lásárù o, tàbí ẹbí wọn, yálà ọ̀rẹ́ wọn ní í ṣe o, tàbí aládùúgbò wọn, wọ́n mọ̀ pé ó ti kú. Àmọ́, ẹni tó ti kú ọ̀hún rèé tó dúró láàárín wọn. Kàyéfì ńlá! Ó dájú pé ọ̀pọ̀ lára wọn ló máa fayọ̀ dì mọ́ Lásárù. Wo bí ẹ̀tẹ́ ṣe bá ikú!

Èlíjà jí ọmọkùnrin opó kan dìde.—1 Àwọn Ọba 17:17-24

9, 10. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi ẹni tó fún un lágbára tó fi jí Lásárù dìde hàn? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa ka àwọn àkọsílẹ̀ nípa àjíǹde tó wà nínú Bíbélì?

9 Jésù ò sọ pé agbára òun lòun fi se iṣẹ́ ìyanu yìí o. Nínú àdúrà tó gbà kó tó pe Lásárù, ó fi hàn pé Jèhófà gan-an lẹni tó jí Lásárù dìde. (Ka Jòhánù 11:41, 42) Èyí kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí Jèhófà máa lo agbára rẹ̀ láti jí òkú dìde. Ńṣe ni àjíǹde Lásárù wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àjíǹde mẹ́sàn-án tá a ṣàkọsílẹ̀ wọn sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. * Kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyẹn á múnú èèyàn dùn gan-an ni. Ohun tí wọ́n fi kọ́ wa ni pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú nítorí pé, àtọkùnrin àtobìnrin, àtọmọ Ísírẹ́lì àtẹni tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹlì ló jí dìde. Àwọn tá a sì jí èèyàn wọn dìde ní ayọ̀ ńláǹlà! Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù jí ọmọbìnrin kan tó kú dìde, àwọn òbí rẹ̀ “kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà pọ̀ jọjọ.” (Máàkù 5:42) Jèhófà ti ṣe ohun ayọ̀ tí wọn ò ní gbàgbé láéláé fún wọn.

Àpọ́sítélì Pétérù jí obìnrin Kristẹni kan tó ń jẹ́ Dọ́káàsì, dìde.—Ìṣe 9:36-42

10 Òótọ́ ni pé àwọn tí Jésù jí dìde tún padà kú lásẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé jíjí tí Jésù jí wọn dìde ò wúlò ni? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá. Àwọn àkọsílẹ̀ nípa àjíǹde tó wà nínú Bíbélì wúlò nítorí pé wọ́n fìdí àwọn òtitọ́ pàtàkì tó wà nínú Bíbélì múlẹ̀ wọ́n sì jẹ́ ká ní ìrètí.

KÍKẸ́KỌ̀Ọ́ NÍNÚ ÀWỌN ÀKỌSÍLẸ̀ ÀJÍǸDE TÓ WÀ NÍNÚ BÍBÉLÌ

11. Báwo ni àkọsílẹ̀ nípa àjíǹde Lásárù ṣe fìdí òtítọ́ tó wà nínú Oníwàásù 9:5 múlẹ̀?

11 Bíbélì fi kọ́ni pé àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan rárá.” Àjíǹde Lásárù jẹ́rìí sí èyí. Àbí nígbà tí Lásárù jí dìde, ṣé ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàpèjúwe bí ọ̀run ṣe rí fún àwọn èèyàn kẹ́nu bàa lè yà wọ́n? Ṣé ó ròyìn ọ̀run àpáàdì tí iná ti ń jó kó báa lè dáyà já wọn? Rárá o. Kò sí nínú Bíbélì pé Lásárù sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Ní gbogbo ọjọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí Lásárù fi kú, kò “mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Ó wulẹ̀ ń sùn nínú oorun ikú ni.—Jòhánù 11:11.

12. Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé lóòótọ́ ni àjíǹde Lásárù wáyé?

12 Àkọsílẹ̀ nípa àjíǹde Lásárù tún kọ́ni pé ohun gidi ni àjíǹde, pé kì í wulẹ̀ ṣe ìtàn àròsọ. Níṣojú ọ̀pọ̀ èèyàn ni Jésù ti jí Lásárù dìde. Kódà, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí wọ́n kòrìíra Jésù ò lè sọ pé Jésù ò ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n sọ ni pé: “Kí ni kí a ṣe, nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì?” (Jòhánù 11:47) Ọ̀pọ̀ ló fẹ́ rí Lásárù tí Jésù jí dìde. Àbájáde rẹ̀ sì ni pé ọ̀pọ̀ wọn ló ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù. Rírí tí wọ́n rí Lásárù tí Jésù jí dìde jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé Ọlọ́run ló rán Jésù. Ẹ̀rí yìí lágbára débi pé àwọn aṣáájú ìsìn Júù tí wọ́n jẹ́ olóríkunkun gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù àti Lásárù.—Jòhánù 11:53; 12:9-11.

13. Kí ló jẹ́ ká nígbàgbọ́ pé Jèhófà lè jí àwọn òkú dìde?

13 Ṣé kò wá bọ́gbọ́n mu kéèyàn gbà pé òótọ́ làjíǹde máa wáyé ni? Ó bọ́gbọ́n mu, nítorí Jésù fi kọ́ni pé lọ́jọ́ kan, a óò jí “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí” dìde. (Jòhánù 5:28) Jèhófà ló dá gbogbo ohun alààyè. Ṣé ó wá yẹ kó ṣòro féèyàn láti gbà gbọ́ pé Jèhófà lè tún èèyàn dá ni? Ká sòótọ́, ọwọ́ agbára ìrántí Jèhófà ni ìyẹn kù sí. Ǹjẹ́ ó lè rántí àwọn èèyàn wa tó ti kú? Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé, ẹgbàágbèje ìràwọ̀ tẹ́nì kan ò mọ iye wọn ló wà lójú sánmà, síbẹ̀, Ọlọ́run fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ! (Aísáyà 40:26) Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run lè rántí gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn èèyan wa tó ti kú, ó sì ti múra tán láti mú wọn padà wá sí ìyè.

14, 15. Bí ohun tí Jóòbù sọ ti fi hàn, báwo ni ọ̀ràn jíjí òkú dìde ṣe rí lára Jèhófà?

14 Àmọ́, báwo ni ọ̀ràn jíjí òkú dìde ṣe rí lára Jèhófà? Bíbélì fi kọ́ni pé tọkàntọkàn ni Jèhófà fi fẹ́ láti jí òkú dìde. Ọkùnrin olóòótọ́ nì, Jóòbù, béèrè pé: “Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?” Ohun tí Jóòbù ń sọ ni pé òun á dúró nínú sárèé de àsìkò tí Ọlọ́run yóò rántí òun. Ó sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”—Jóòbù 14:13-15.

15 Tiẹ̀ rò ó wò ná! Jèhófà ń fẹ́ tọkàntọkàn láti jí àwọn òkú dìde. Ǹjẹ́ inú wa ò dùn láti mọ̀ pé bí ọ̀ràn jíjí òkú dìde ṣe rí lára Jèhófà nìyẹn? Ṣùgbọ́n, àjíǹde tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú ńkọ́? Àwọn wo la óò jí dìde, ibo sì ni wọ́n yóò jí dìde sí?

“GBOGBO ÀWỌN TÍ WỌ́N WÀ NÍNÚ IBOJÌ ÌRÁNTÍ”

16. Irú ipò wo ni Ọlọ́run yóò jí àwọn òkú dìde sí?

16 Àwọn àkọsílẹ̀ nípa àjíǹde tó wà nínú Bíbélì fi ohun púpọ̀ kọ́ni nípa àjíǹde tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn tá a jí dìde sí ilẹ̀ ayé níbí tún padà wà pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni àjíǹde tó ń bọ̀ ṣe máa rí, àmọ́, yóò dára jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí Kẹta, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé yìí ni pé kó di Párádísè. Nítorí náà, inú ayé tó kún fún ogun, ìwà ọ̀daràn àti àìsàn kọ́ ni àwọn òkú yóò jí dìde sí. Wọ́n yóò ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé níbi tí àlàáfíà yóò ti jọba tí ayọ̀ yóò sì gbilẹ̀.

17. Báwo ni àwọn òkú tí yóò jíǹde yóò ṣe pọ̀ tó?

17 Àwọn wo la óò jí dìde? Jésù sọ pé “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ [ìyẹn ohùn Jésù], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Bákan náà, Ìṣípayá 20:13 sọ pé: “Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ.” “Hédíìsì” túmọ̀ sí ipò òkú. (Wo Àfikún, “Kí Ni Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì?”) Ipò okú yìí yóò ṣófo. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó ń sùn nínú ikú, ìyẹn àwọn tó wà nínú ipò òkú, yóò padà wá sí ìyè. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí?

Ní Párádísè, a óò jí àwọn òkú dìde, wọ́n á sì tún padà wà pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn

18. Àwọn wo ló wà lára “àwọn olódodo” tí a óò jí dìde, àǹfààní wo sì ni ìrètí àjínde lè ṣe fún ọ?

18 Àwọn tá a kà nípa wọn nínú Bíbélì tí wọ́n gbé ayé ṣáájú kí Jésù tó wá sórí ilẹ̀ ayé wà lára “àwọn olódodo.” Ó ṣeé ṣe kó o ronú kan Nóà, Ábúráhámù, Sárà, Mósè, Rúùtù, Ẹ́sítérì, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn. Hébérù Orí Kọkànlá sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin àtobìnrin wọ̀nyí tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ń kú lóde òní náà wà lára “àwọn olódodo” yìí o. Nítorí pé a ní ìrètí àjíǹde, ẹ̀rù kì í bà wá nítorí ikú.—Hébérù 2:15.

19. Àwọn wo ni “àwọn aláìṣòdodo,” àǹfààní wo sì ni Jèhófà fún wọn?

19 Gbogbo àwọn tí wọn kò sin Jèhófà tí wọn kò sì ṣègbọràn sí i nítorí pe wọn kò mọ̀ ọ́n ńkọ́? Ọlọ́run ò ní gbàgbé ọ̀kẹ́ àìmọye “àwọn aláìṣododo” wọ̀nyẹn o. A óò jí àwọn náà dìde, a óò sì fún wọn lákòókò láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ kí wọ́n sì sìn ín. Lákòókò ẹgbẹ̀rún ọdún, Ọlọ́run yóò jí àwọn òkú dìde yóò sì fún wọn láǹfààní láti dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn olóòótọ́ láti máa sin Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé. Àkókò alárinrin ni àkokò náà yóò jẹ́. Ẹgbẹ̀rún ọdún yìí ni Bíbélì pè ní Ọjọ́ Ìdájọ́. *

20. Kí ni Gẹ̀hẹ́nà, àwọn wo ló sì lọ síbẹ̀?

20 Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tó ti kú pátá la óò jí dìde? Rárá o. Bíbélì sọ pé inú “Gẹ̀hẹ́nà” làwọn òkú kan wà. (Lúùkù 12:5) Inú orúkọ tí wọ́n ń pe ààtàn kan tó wà ní òde ìlú Jerúsálẹ́mù ayé àtijọ́ ni wọ́n ti fa orúkọ náà, Gẹ̀hẹ́nà yọ. Òkú àti pàǹtírí ni wọ́n máa ń sun níbẹ̀. Àwọn Júù ka àwọn òkú tí wọ́n jù síbẹ̀ sí àwọn tí kò yẹ lẹ́ni tá à ń sin tí kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí àjíǹde. Nítorí náà, Gẹ̀hẹ́nà jẹ́ àpẹẹrẹ ìparun ayéráyé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù yóò kópa nínú ṣíṣèdájọ́ àwọn alààyè àtàwọn òkú, Jèhófà ni adájọ́ àgbà pátápátá. (Ìṣe 10:42) Láéláé, kò ní jí àwọn tó dá lẹ́jọ́ pé wọ́n jẹ́ olubi tí wọn ò sì fẹ́ láti yí padà dìde.

ÀJÍǸDE SÍ Ọ̀RUN

21, 22. (a) Oríṣi àjíǹde mìíràn wo ló tún wà? (b) Ta ni ẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run jí dìde sí ìyè ti ẹ̀mí?

21 Bíbélì sọ pé oríṣi àjíǹde mìíràn kan tún wà, ìyẹn àjíǹde sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. Àpẹẹrẹ irú àjíǹde yìí kan péré ló wà nínú Bíbélì, ìyẹn ni, àjíǹde ti Jésù Kristi.

22 Lẹ́yìn tí wọ́n ti pa Jésù gẹ́gẹ́ bí èèyàn, Jèhófà ò jẹ́ kí Ọmọ Rẹ̀ Olóòótọ́ máa wà nínú sàréè títí lọ. (Sáàmù 16:10; Ìṣe 13:34, 35) Ọlọ́run jí Jésù dìde, ṣùgbọ́n kò jí i dìde gẹ́gẹ́ bí èèyàn. Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé pé ‘Wọ́n fikú pa Kristi nínú ẹran ara, ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ ọ́ di ààyè nínú ẹ̀mí.’ (1 Pétérù 3:18) Iṣẹ́ ìyanu ńlá lèyí o. Jésù tún wà láàyè padà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára! (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:3-6) Jésù lẹni tó kọ́kọ́ gba irú àjíǹde ológo yìí. (Jòhánù 3:13) Ṣùgbọ́n òun kọ́ ló máa gba irú rẹ̀ kẹ́yìn.

23, 24. Àwọn wo ló para pọ̀ di “agbo kékeré” Jésù, mélòó sì ni iye wọn yóò jẹ́?

23 Bí Jésù ti mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ padà sí ọ̀run, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ pé òun yóò “pèsè ibì kan” sílẹ̀ fún wọn lọ́run. (Jòhánù 14:2) Jésù pe àwọn tó ń lọ sí ọ̀run ní “agbo kékeré” rẹ̀. (Lúùkù 12:32) Mélòó ni iye àwọn Kristẹni olóòótọ́ tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ agbo kékeré? Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Ìṣípayá 14:1, àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Mo sì rí, sì wò ó! Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Ńlá Síónì, àti pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n ní orúkọ rẹ̀ àti orúkọ Baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.”

24 Àwọn Kristẹni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì wọ̀nyí, tí àwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ wà lára wọn, ni yóò jí dìde sí ìyè ní ọ̀run. Ìgbà wo ni àjíǹde wọn? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé yóò wáyé nígba wíwàníhìn-ín Kristi. (1 Kọ́ríńtì 15:23) Bó o ṣe máa kẹ́kòọ́ ní Orí Kẹsàn-án, àkókò yẹn la wà báyìí. Nítorí náà, bí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ìwọ̀nba àwọn tó kù lára 144,000 ní ọjọ́ tiwa lónìí ṣe ń kú ni wọ́n ń jíǹde lójú ẹsẹ̀ sí ìyè ní ọ̀run. (1 Kọ́ríńtì 15:51-55) Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ lára aráyé ló ní ìrètí láti jí dìde ní ọjọ́ iwájú sí ìyè nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.

25. Kí ni a óò kẹkọ̀ọ́ ní orí tó kàn?

25 Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà yóò ṣẹ́gun ikú tó jẹ́ ọ̀tá wa, a ò sì ní rí i mọ láé! (Ka Aísáyà 25:8) Síbẹ̀, o ṣeé ṣe kó o máa ṣe kàyéfì pé, kí ni àwọn tó jíǹde sí ọ̀run fẹ́ ṣe níbẹ̀? Ńṣe ni wọn yóò di ara Ìjọba àgbàyanu ní ọ̀run. A óò mọ̀ sí i nípa ìjọba yẹn ní orí tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 19 Tó o bá fẹ́ túbọ̀ mọ̀ nípa Ọjọ́ Ìdájọ́ àtohun tí Ọlọ́run máa wò ṣèdájọ́, jọ̀wọ́ wo Àfikún, “Kí Ni Ọjọ́ Ìdájọ́?”.