Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 4

Ẹ̀bi Ẹ̀ṣẹ̀—‘Wẹ̀ Mí Mọ́ Kúrò Nínú Ẹ̀ṣẹ̀ Mi’

Ẹ̀bi Ẹ̀ṣẹ̀—‘Wẹ̀ Mí Mọ́ Kúrò Nínú Ẹ̀ṣẹ̀ Mi’

“Lóòótọ́ nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹnuure fún ìdílé mi nígbà tí mo ríṣẹ́ tuntun, àmọ́ iṣẹ́ ọ̀hún sún mi débi tí mo fi ṣe àwọn ohun tí kò tọ́. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ayẹyẹ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, mò ń dá sí ohun tó ń lọ lágbo òṣèlú, kódà mó tún lọ ṣọ́ọ̀ṣì. Ogójì [40] ọdún gbáko ni mi ò fi lọ sí ìpàdé mọ́, tí mi ò sì lọ sóde ẹ̀rí mọ́. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún ti mi ò sì pa dà sínú ètò Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ló ń ṣe mi bíi pé Jèhófà ò lè dárí jì mí mọ́. Ṣe ni mò ń dá ara mi lẹ́bi ṣáá. Ó ṣe tán, mo ṣáà rí iná nílẹ̀ kí n tó lọ tọwọ́ bọ̀ ọ́, mo ti mọ ọ̀nà òtítọ́ kí n tó forí lé igbó.”—Martha.

KÁ SÒÓTỌ́, ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ lè wọni lọ́rùn. Dáfídì Ọba sọ pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ òun ti bo òun mọ́lẹ̀, ó tún sọ pé wọ́n dà bí ẹrù tó wúwo jù fún òun. (Sáàmù 38:4) Ìbànújẹ́ ti mú kí àwọn Kristẹni kan rẹ̀wẹ̀sì débi pé wọ́n ń rò pé Jèhófà ò lè dárí ji àwọn láé. (2 Kọ́ríńtì 2:7) Ǹjẹ irú èrò bẹ́ẹ̀ tọ́? Bó o bá tiẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé o ti jìnnà sí Jèhófà débi tí kò fi ní dárí jì ẹ́? Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀.

‘Jẹ́ Kí A Mú Àwọn Ọ̀ràn Tọ́ Láàárín Wa’

Jèhófà kì í kẹ̀yìn sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà. Kódà, ńṣe ló máa ń fojú àánú hàn sí wọn. Nínú àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá, Jésù fi Jèhófà wé Bàbá onífẹ̀ẹ́ kan tọ́mọ rẹ̀ fi ilé sílẹ̀ tó wá lọ ń ṣe ọmọ jayéjayé nílùú òdìkejì. Àmọ́ nígbà tó yá, ọmọ yìí pa dà wá sílé. Jésù sọ pé, “Nígbà tí [ọmọ náà] ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn, baba rẹ̀ tajú kán rí i, àánú sì ṣe é, ó sì sáré, ó sì rọ̀ mọ́ ọrùn rẹ̀, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.” (Lúùkù 15:11-20) Ṣó wu ẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àmọ́ tó ń ṣe ẹ́ bíi pé o ti jìnnà sí i gan-an? Bíi ti bàbá inú àpèjúwe Jésù, aláàánú ni Jèhófà, ó máa ṣàánú ìwọ náà. Ó ṣe tán láti gbà ẹ́ pa dà.

Àmọ́ bó o bá ń rò pé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí burú jù tàbí pé ó pọ̀ ju èyí tí Jèhófà lè dárí rẹ̀ jì ọ́ ńkọ́? Wò ó ná, Jèhófà ń rọ̀ ẹ́ pé kó o wá sọ́dọ̀ òun, bó ṣe sọ nínú Aísáyà 1:18: “‘Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ sì jẹ́ kí a mú àwọn ọ̀ràn tọ́ láàárín wa,’ ni Jèhófà wí. ‘Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, a ó sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì.’” Ṣé o wá rí i báyìí pé bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bá tiẹ̀ pọ́n bí ẹ̀jẹ̀ tó sì dà bí àbàwọ́n lára aṣọ funfun, Jèhófà ṣe tán láti dárí jì ẹ́.

Jèhófà kò fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn rẹ máa dá ọ lẹ́bi ṣáá. Torí náà, kí ni wàá ṣe tí Jèhófà á fi dárí jì ẹ́, tí wàá fi ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, tí ara á sì tù ẹ́? Wo ohun méjì tí Dáfídì Ọba ṣe. Lákọ̀ọ́kọ́, ó sọ pé: “Èmi yóò jẹ́wọ́ àwọn ìrélànàkọjá mi fún Jèhófà.” (Sáàmù 32:5) Rántí pé Jèhófà ti pè ẹ́ pé kó o wá sọ́dọ̀ òun, pé kó o gbàdúrà sí òun, kí ọ̀rọ̀ náà lè yanjú. A rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ fún un, kó o sì sọ àwọn ohun tó ń dùn ẹ́ lọ́kàn fún un. Dáfídì náà mọ̀ pé aláàánú ni Jèhófà, ìdí nìyẹn tó fi bẹ̀ Jèhófà pé: ‘Wẹ̀ mí mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi. . . . Ọkàn tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀ ni ìwọ, Ọlọ́run, kì yóò tẹ́ńbẹ́lú.”—Sáàmù 51:2, 17.

Ohun kejì tí Dáfídì ṣe ni pé, ó gbà kí Nátánì tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ láti pa dà rí ojúrere Jèhófà. (2 Sámúẹ́lì 12:13) Lónìí, Jèhófà yan àwọn alágbà sínú ìjọ, o sì ti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè ran ẹni tó ronú pìwà dà lọ́wọ́ kó lè pa dà bá Ọlọ́run rẹ́. Bó o bá tọ àwọn alàgbà lọ, wọ́n á fi Ìwé Mímọ́ tọ́ ẹ sọ́nà, wọ́n á gbàdúrà fún ẹ, ara á sì tù ẹ́. Èyí á jẹ́ kí èrò tó o ní pé Jèhófà kò lè dárí jì ẹ́ kúrò lọ́kàn rẹ pátápátá. Paríparí rẹ̀, àárín ìwọ àti Jèhófà á gún régé.—Jákọ́bù 5:14-16.

Jèhófà fẹ́ kó o ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ kí ara sì tù ẹ́

‘Aláyọ̀ Ni Ẹni Tí A Dárí Èṣẹ̀ Rẹ̀ Jì’

Ká sòótọ́, ó lè máà rọrùn fún ẹ láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ fún Jèhófà Ọlọ́run ó sì lè máà rọrùn pé kó o tọ àwọn alàgbà lọ. Ó ṣe Dáfídì náà bẹ́ẹ̀. Ó kọ́kọ́ “dákẹ́” làwọn ìgbà kan, kò jẹ́wọ́. (Sáàmù 32:3) Àmọ́, lẹ́yìn náà ó wá mọ̀ pé àǹfààní wà nínú kí òun jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ òun, kí òun sì ṣàtúnṣe.

Àǹfààní ńlá kan tí èyí ṣe Dáfídì ni pé ó tún pa dà láyọ̀. Ó sọ pé: ‘Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí èṣẹ̀ rẹ̀ jì.’ (Sáàmù 32:1) Ó tún gbàdúrà pé: ‘Jèhófà . . . ṣí ètè mi, kí ẹnu mi lè máa sọ ìyìn rẹ jáde.’ (Sáàmù 51:15) Lẹ́yìn tí Jèhófà dárí jì í, tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò sì dá a lẹ́bi mọ́, ó yá Dáfídì lára láti sọ nípa Jèhófà fún àwọn èèyàn.

Jèhófà fẹ́ kí ìwọ náà ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ kí ara sì tù ẹ́. Ó sì fẹ́ kíwọ náà máa sọ̀rọ̀ nípa òun àtàwọn ohun tí òun fẹ́ ṣe fáráyé. Ó fẹ́ kó o máa fayọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ láìsí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ ń dá ẹ lẹ́bi. (Sáàmù 65:1-4) Má sì gbàgbé pé Jèhófà fẹ́ pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ rẹ́, kí àwọn àsìkò títunilára lè wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.—Ìṣe 3:19.

Bọ́rọ̀ ṣe pa dà rí fún arábìnrin Martha tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Ó ti wá ń fayọ̀ sin Jèhófà báyìí. Ó sọ pé: “Ọmọ mi máa ń fi ìwé ìròyìn Ílé Ìṣọ́ àti Jí! ránṣẹ́ sí mi lóòrèkóòrè. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ìgbésẹ̀ tó le jù fún mi níbẹ̀ ni bí mo ṣe máa tọ̀rọ̀ ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi. Àmọ́ nígbà tó yá, mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì mí. Ó kàn dún mí pé mo ti lo ogójì [40] ọdún níta kí n tó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tèmi yìí jẹ́ ẹ̀rí pé bó ti wù kó pẹ́ tó téèyàn ti fi ètò Jèhófà sílẹ̀, ó ṣì láǹfààní láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.”