Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 8

Àpèjúwe Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

Àpèjúwe Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

Mátíù 13:34, 35

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà kọ́ni dára sí i nípa lílo àwọn àpèjúwe tó rọrùn, tó máa mú kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, tó sì máa jẹ́ kí wọ́n rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Lo àpèjúwe tó rọrùn. Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, máa fi àwọn nǹkan kéékèèké ṣàlàyé àwọn nǹkan ńlá, kó o sì máa fi àwọn nǹkan tó rọrùn ṣàlàyé àwọn nǹkan tó le. Má ṣe àlàyé tí kò pọn dandan nínú àpèjúwe rẹ, kí àpèjúwe náà má bàa lọ́jú pọ̀. Kí àpèjúwe rẹ lè bọ́gbọ́n mu, kó sì ṣe kedere lọ́kàn àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀, rí i dájú pé ó bá ohun tó o fẹ́ kọ́ wọn mu dáadáa.

  • Máa ronú nípa àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Lo àwọn àpèjúwe tí kò ní ṣàjèjì sí àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀, tó sì bá ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí mu.

  • Àwọn kókó pàtàkì ni kó o pàfíyèsí sí. Àwọn kókó pàtàkì ni kó o fi àlàyé rẹ gbé yọ, kì í ṣe àwọn tí kò pọn dandan. Fi sọ́kàn pé kò yẹ kó jẹ́ àpèjúwe rẹ nìkan ni àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ máa rántí, wọ́n tún gbọ́dọ̀ rántí ohun tí wọ́n kọ́ látinú rẹ̀.