Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Máa Bọ̀wọ̀ fún Èrò Àwọn Míì

Bíbélì Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Máa Bọ̀wọ̀ fún Èrò Àwọn Míì

 “Àlááfíà máa wà láyé yìí táwọn èèyàn bá ń bọ̀wọ̀ fún èrò àwọn míì.”​—Ìkéde àjọ UNESCO Nípa Bí A Ṣe Lè Bọ̀wọ̀ fún Èrò Àwọn Míì, ọdún 1995.

 Lọ́wọ́ kejì, téèyàn ò bá mọ bó ṣe lè gba tàwọn míì rò, ó lè mú kó kórìíra àwọn míì tàbí kó má tiẹ̀ bọ̀wọ̀ fún wọn. Irú ìwà yìí sì lè mú kéèyàn máa sọ̀rọ̀ àbùkù sáwọn míì, kó máa ṣẹ̀tanú sí wọn, kó sì máa hùwà ipá.

 Oríṣiríṣi èrò làwọn èèyàn ní nípa ohun tó túmọ̀ sí láti máa bọ̀wọ̀ fún èrò àwọn míì. Àwọn kan rò pé àwọn tó bá ń gba tàwọn míì rò máa ń fara mọ́ gbogbo ìwà àwọn èèyàn títí kan gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. Àwọn míì sì fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ pé, àwọn tó bá ń gba tàwọn míì rò máa ń bọ̀wọ̀ fún ìpinnu táwọn míì ṣe lórí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn fúnra wọn lè má gba ohun náà gbọ́.

 Ṣe Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa bọ̀wọ̀ fún èrò àwọn míì lákòókò wa yìí?

Ohun tí Bíbélì sọ nípa bá a ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fún èrò àwọn míì

 Bíbélì sọ pé ó dáa ká máa gba tàwọn míì rò. Ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.” (Fílípì 4:5) Ó tún rọ̀ wá pé, ká máa ṣe sùúrù fáwọn míì, ká máa hùwà tó dáa sì wọn ká sì máa fi ire wọn ṣáájú tiwa. Àwọn tó ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì yìí lè pinnu láti fara mọ́ ohun tó wu àwọn míì tàbí kí wọ́n má fara mọ́ ọn. Àmọ́ ìyẹn ò sọ pé kí wọ́n má jẹ́ kí ẹni náà ṣe ohun tó bá fẹ́.

 Ohun kan ni pé, Ọlọ́run ní àwọn ìlànà tó fẹ́ káwa èèyàn máa tẹ̀ lé, Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “[Ọlọ́run] ti sọ ohun tó dára fún ọ, ìwọ ọmọ aráyé.” (Míkà 6:8) Àwọn ìlànà yìí ló sì lè jẹ́ ká gbádùn ìgbésí ayé tó nítumọ̀.​—Àìsáyà 48:17, 18.

 Ọlọ́run kò fẹ́ ká máa dá àwọn míì lẹ́jọ́. Bí Bíbélì ṣe sọ, “Ẹnì kan ṣoṣo ni Afúnnilófin àti Onídàájọ́ wa . . . Ta ni ọ́ tí o fi ń dá ọmọnìkejì rẹ lẹ́jọ́?” (Jémíìsì 4:12) Torí náà, Ọlọ́run ti fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láǹfààní láti ṣe ohun tá a bá fẹ́. Ká ṣáà fi sọ́kàn pé àwa la máa kórè àbájáde ohun tá a bá ṣe.​—Diutarónómì 30:19.

Bíbélì sọ pé ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn

 Bíbélì sọ pé “Ẹ bọ̀wọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (1 Pétérù 2:17, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní ) Torí náà, àwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì máa ń bọ̀wọ̀ fún gbogbo èèyàn láìka ohun tí wọ́n gbà gbọ́ sí tàbí irú ìgbé ayé tí wọ́n ń gbé. (Lúùkù 6:31) Àmọ́, ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé wọ́n máa fara mọ́ gbogbo ohun táwọn èèyàn bá ṣáà ti gbà gbọ́ tàbí ìpinnu tí wọ́n bá ṣe. Wọn kì í yájú sáwọn míì tàbí kí wọ́n máa hùwà tí ò bójú mu sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti fara wé bí Jésù ṣe máa ń ṣe sáwọn míì.

 Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Jésù pà dé obìnrin kan tó ń ṣe ìsìn tó yàtọ̀ sí tiẹ̀. Kódà, obìnrin yìí tún ń gbé pẹ̀lú ọkùnrin tí kì í ṣe ọkọ ẹ̀, Jésù ò sì fara mọ́ irú ìgbé ayé yìí. Síbẹ̀, ó bá obìnrin náà sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.​—Jòhánù 4:9, 17-24.

 Bíi ti Jésù, àwọn Kristẹni máa ń fara balẹ̀ ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn tó bá ṣe tán láti gbọ́ wọn, wọ́n sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú “ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:15) Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n má ṣe fipá mú àwọn míì láti gba èrò wọn. Ó sọ pé kò yẹ kí ọmọ ẹ̀yìn Kristi “máa jà, àmọ́ ó yẹ kó máa hùwà jẹ́jẹ́ sí gbogbo èèyàn,” tó fi mọ́ àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ sí tiwọn.​—2 Tímótì 2:24.

Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìkórìíra

 Bíbélì sọ pé ká “máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn.” (Hébérù 12:14) Ẹni tó ń wá àlàáfíà kì í kórìíra ẹlòmíì. Ó máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn míì. Àmọ́ o, ó máa ń dúró lórí ohun tó gbà pé ó tọ́. (Mátíù 5:9) Kódà Bíbélì sọ pé kí àwọn Kristẹni máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn, kí wọ́n sì máa ṣe ohun tó dáa sí àwọn tó ń hùwà burúkú sí wọn.​—Mátíù 5:44.

 Òótọ́ ni pé Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “kórìíra” àwọn ìwà kan tó máa ń buni kù tàbí tó lè pa àwọn míì lára, kódà irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ “jẹ́ ohun ìríra fún un.” (Òwe 6:16-19) Àmọ́ bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “kórìíra” nínú ẹsẹ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ ìwà burúkú rárá. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa dárí ji àwọn tó bá yí pá dà kúrò nínú ìwà burúkú wọn, ó sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀.​—Àìsáyà 55:7.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fún èrò àwọn míì

 Títù 3:2: “Kí wọ́n máa fòye báni lò, kí wọ́n jẹ́ oníwà tútù sí gbogbo èèyàn.”

 Ẹni tó ń fòye báni lò kì í bínú tí àwọn míì bá sọ èrò wọn, èyí á sì jẹ́ ká lè máa bọ̀wọ̀ fúnra wa.

 Mátíù 7:12: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.”

 Inú wa máa ń dùn táwọn míì bá ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún wa, tí wọ́n ka èrò wa sí pàtàkì, tí wọ́n sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa bá a ṣe lè tẹ̀ lé ìlànà pàtàkì tí Jésù kọ́ wa yìí, wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Òfin Oníwúrà?

 Jóṣúà 24:15: “Ẹ fúnra yín yan ẹni tí ẹ fẹ́ máa sìn lónìí.”

 Àlàáfíà máa wà tá a bá gbà pé àwọn míì lẹ́tọ̀ọ́ láti yan ohun tí wọ́n fẹ́.

 Ìṣe 10:34: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.”

 Àwọn tó bá fẹ́ fara wé Ọlọ́run máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn míì. Torí pé Ọlọ́run kì í gbé ẹ̀yà, àṣà, àwọ̀, orílẹ̀-èdè àti bí ẹnìkan ṣe jẹ́ láwùjọ ga ju àwọn míì lọ.

 Hábákúkù 1:12, 13: “[Ọlọ́run] kò ní gba ìwà burúkú láyè.”

 Ó níbi tí Ọlọ́run lè fàyè gba nǹkan mọ. Torí náà, kò ní fàyè gba ìwà burúkú àwọn èèyàn títí láé. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo fídíò náà Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà?

 Róòmù 12:19: “Ẹ fàyè sílẹ̀ fún ìrunú; nítorí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san,’ ni Jèhófà wí.” a

 Jèhófà ò fún ẹni kẹ́ni láṣẹ láti gbẹ̀san. Tí àkókò bá tó lójú rẹ̀, ó dájú pé ó máa ṣe ìdájọ́ òdodo. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ìdájọ́ Òdodo Máa Wà?

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”