Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn tí Wọ́n Ń Fìyà Jẹ Nínú Ilé

Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn tí Wọ́n Ń Fìyà Jẹ Nínú Ilé

 Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé: “Kárí ibi gbogbo lágbàáyé, kò síbi tí wọn kì í ti í fìyà jẹ àwọn obìnrin. Ọ̀rọ̀ náà ti dà bí àjàkálẹ̀ àrùn tó ń yára gbèèràn báyìí, ó sì ṣe pàtàkì ká wá nǹkan ṣe sí i.” Àjọ yẹn fojú bù ú pé nínú “gbogbo obìnrin” mẹ́wàá “tó ti lọ́kọ tàbí tó ti wà pẹ̀lú ọkùnrin rí,” ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mẹ́ta tí “ọkọ wọn ń fi ìbálòpọ̀ fìtínà tàbí tó ń lù bí ẹni lu bàrà tàbí tó ń ṣe méjèèjì sí.” Nínú ìròyìn kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fojú bù ú pé, kárí ayé, obìnrin mẹ́tàdínlógóje [137] ló ń ti ọwọ́ àwọn ọkọ tàbí ẹlòmíì nínú ìdílé wọn kú. a

 Tá a bá gbọ́ iye àwọn tí wọ́n ń fìyà jẹ nínú ilé, a lè lóye bí ìṣòro náà ṣe pọ̀ tó, ṣùgbọ́n a ò lè fìyẹn mọ bí ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn tó ń bá ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ṣe tó.

 Ṣé wọ́n ń fìyà jẹ ìwọ náà nínú ilé? Àbí o mọ ẹnì kan tó ń fojú winá irú ìṣòro bẹ́ẹ̀? Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ṣe àyẹ̀wò díẹ̀ lára ohun tó lè ṣèrànwọ́ tí Bíbélì sọ yìí.

  Bí ẹnì kejì rẹ bá ń fìyà jẹ ọ́, ìwọ kọ́ lo lẹ̀bi

  Ó lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà

  O ò dá wà

  Á dópin lọ́jọ́ kan

  Bó o ṣe lè ran ẹni tí wọ́n ń fìyà jẹ lọ́wọ́

 Bí ẹnì kejì rẹ bá ń fìyà jẹ ọ́, ìwọ kọ́ lo lẹ̀bi

 Ohun tí Bíbélì sọ: “Kálukú wa ló máa jíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.”​—Róòmù 14:12.

 Rántí: Ọwọ́ ẹni tó ń fìyà jẹ ọ́ ni ẹ̀bi wà.

 Bí ẹnì kejì rẹ̀ bá sọ pé ìwọ lo fà á tí òun fi ń fìyà jẹ ọ́, irọ́ ló pa. Ṣe ló yẹ kéèyàn nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀ kò yẹ kó máa fìyà jẹ ẹ́.​—Kólósè 3:19.

 Ìgbà míì wà tó jẹ́ pé ṣe ni ẹni tó ń fìyà jẹni ní ìṣòro ọpọlọ, ó sì lè jẹ́ ilé tí wọ́n ti ń luni bí ẹni lu bàrà ló gbé dàgbà, tàbí kó máa mu ọtí lámujù. Síbẹ̀ náà, ó máa jíhìn fún Ọlọ́run nítorí bó ṣe hùwà sí ẹ. Ọwọ́ ẹ̀ ló kù sí láti yíwà pa dà.

 O lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà

 Ohun tí Bíbélì sọ: “Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbaninímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.”​—Òwe 15:22.

 Rántí: Bí ẹ̀mí rẹ bá wà nínú ewu tàbí tí o ò mọ ohun tó yẹ kó o ṣe, àwọn míì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

 Kí nìdí tó fi yẹ kí ẹlòmíì ràn ẹ́ lọ́wọ́? Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni wọ́n ń fìyà jẹ, ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè máa wá sí ẹ lọ́kàn. Ó lè ṣòro fún ẹ láti pinnu ohun tó dáa jù lọ pé kó o ṣe, torí pé o lè máa ronú pé èwo ló ṣe pàtàkì jù nínú àwọn nǹkan bí:

  •   Ààbò tìrẹ alára

  •   Ohun tó máa ṣe àwọn ọmọ rẹ láǹfààní

  •   Ìṣúnná owó

  •   Ìfẹ́ tó o ní sí ẹnì kejì rẹ

  •   O lè wù ẹ́ kí ẹnì kejì rẹ yíwà pa dà kí ìgbéyàwó rẹ má bàa tú ká

 O lè má mọ èwo ni ṣíṣe, kó sì dà bíi pé ọ̀rọ̀ náà ti dojú rú pátápátá. Ọ̀dọ̀ ta lo lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ?

 Ọ̀rẹ́ tó ṣeé gbára lé tàbí ìbátan rẹ kan lè ṣe ohun tó o nílò tàbí kó sọ̀rọ̀ ìtùnú fún ẹ. Ìrànlọ́wọ́ kékeré kọ́ lo máa rí tó o bá sọ tinú ẹ fun ẹnì kan tí ọ̀rọ̀ rẹ jẹ lógún.

 Àwọn ètò orí afẹ́fẹ́ kan wà táwọn tí wọ́n ń fìyà jẹ lè tẹ̀ láago kí wọ́n lè rí ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò lójú ẹsẹ̀ gbà. Àwọn olóòtú ètò náà lè sọ ohun tó o máa ṣe tí wàá fi dáàbò bo ara rẹ. Bí ẹnì kejì rẹ bá gbà pé òun nílò ìrànlọ́wọ́ kóun lè ṣíwọ́ àtimáa fìyà jẹ ọ́ tó sì múra tán láti yíwà pa dà, àwọn olóòtú ètò náà lè sọ àwọn ìgbésẹ̀ tó máa kọ́kọ́ gbé fún un.

 Àwọn míì tó ń pèsè ìrànlọ́wọ́ pàjáwìrì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá nílò ìrànlọ́wọ́ lójú ẹsẹ̀. Lára àwọn tó ń pèsè ìrànlọ́wọ́ náà ni àwọn dókítà, nọ́ọ̀sì, tàbí àwọn òṣìṣẹ́ míì tí wọ́n gba àkànṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́.

 O ò dá wà

 Ohun tí Bíbélì sọ: “Jèhófà b wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là.”​—Sáàmù 34:18.

 Rántí: Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

 Jèhófà bìkítà gan-an nípa rẹ. (1 Pétérù 5:7) Ó mọ èrò ọkàn rẹ àti bí nǹkan ṣe rí lára rẹ dunjú. Ó lè fi Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tù ẹ́ nínú. Ó sì ní kó o máa gbàdúrà sí òun. Tó o bá gbàdúrà, o lè ní kó fún ẹ ní ọgbọ́n àti agbára tí wàá fi lè fara da ìṣòro tó ń bá ẹ fínra.​—Àìsáyà 41:10.

 Á dópin lọ́jọ́ kan

 Ohun tí Bíbélì sọ: “Kálukú wọn máa gbé lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”​—Míkà 4:​4, àlàyé ìsàlẹ̀.

 Rántí: Bíbélì sọ pé láìpẹ́ sígbà tí a wà yìí inú ilé á di ibùgbé àlàáfíà fún gbogbo èèyàn.

 Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú gbogbo ìṣòro wa pátápátá táwọn ìṣòro náà ò sì ní gbérí mọ́ láé. Bíbélì sọ ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí, ó ní: “Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìfihàn 21:4) Nígbà yẹn, a ò ní rántí àwọn ohun búburú tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa mọ́, àwọn nǹkan rere á ti dípò wọn. (Àìsáyà 65:17) Ọjọ́ iwájú alálàáfíà tí Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì pé ó ń dúró dè ẹ́ nìyẹn.

a Obìnrin ni àpilẹ̀kọ yìí tọ́ka sí pé wọ́n ń fìyà jẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ nínú ohun tí àpilẹ̀kọ náà sọ ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọkùnrin.

b Nínú Bíbélì, Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.