Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 83

“Láti Ilé dé Ilé”

“Láti Ilé dé Ilé”

(Ìṣe 20:20)

  1. 1. À ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

    Láti ilé délé.

    Iṣẹ́ ìwàásù wa ń kárí

    Gbogbo ilẹ̀ ayé.

    Tọmọdé tàgbà wa ló ń ṣe

    Iṣẹ́ pàtàkì yìí.

    Káwọn èèyàn bàa lè mọ̀ pé

    Jésù ti ń ṣàkóso.

  2. 2. Báwo laráyé ṣe máa gbọ́

    Láìsí oníwàásù?

    Báwo ni wọ́n ṣe máa ké pe

    Ẹni tí wọn kò mọ̀?

    Ó pọn dandan fún wa láti

    Kọ́ wọn lọ́r’Ọlọ́run.

    Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe yìí

    Máa jẹ́ kí wọ́n gbà là.

  3. 3. Kí gbogbo wa lọ máa wàásù

    Ìròyìn ayọ̀ náà.

    Ó kù sọ́wọ́ àwọn èèyàn

    Láti yàn fúnra wọn.

    Ká jẹ́ kí gbogbo aráyé

    Morúkọ Jèhófà,

    Kí wọ́n sì fìyìn fún Jésù

    Àti Ìjọba Rẹ̀.