Orin 141
À Ń Wá Àwọn Ọ̀rẹ́ Àlàáfíà
Wà á jáde:
-
Jésù pàṣẹ pé: ‘Ẹ wàásù òótọ́.’
Lójò lẹ́ẹ̀rùn, níbi gbogbo,
Ó ń sọ̀rọ̀ Jáà fáwọn èèyàn.
Jésù nífẹ̀ẹ́ àgùntàn Ọlọ́run.
Ó ń wá wọn lọ
ní òwúrọ̀ títí ’lẹ̀ fi ṣú.
Nílé délé, lópòópónà,
À ń wàásù fún gbogbo èèyàn
Pé láìpẹ́ gbogbo
ìṣòro yóò dópin.
(ÈGBÈ)
Kárí ayé
À ń wá àwọn ọ̀rẹ́ àlàáfíà,
Ó yẹ ká rí
Àwọn èèyàn tó fẹ́ rí’gbàlà,
Ká sì rí i pé
A sapá wa.
-
Àkókò ń lọ, ká tẹra mọ́ṣẹ́ yìí.
Ọ̀pọ̀ èèyàn, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí,
Là ń sapá láti gbà là.
Ìfẹ́ ló ń mú ká ṣáà máa wá wọn lọ.
À ń wo ọgbẹ́ ọkàn wọn sàn,
à ń táyé wọn ṣe.
Nílùú délùú, lópòópónà,
Tá a bá rẹ́ni tó gbọ́rọ̀ wa,
Ayọ̀ tó ń fún wa ń mú ká máa báṣẹ́ lọ.
(ÈGBÈ)
Kárí ayé
À ń wá àwọn ọ̀rẹ́ àlàáfíà,
Ó yẹ ká rí
Àwọn èèyàn tó fẹ́ rí’gbàlà,
Ká sì rí i pé
A sapá wa.
(Tún wo Aísá. 52:7; Mát. 28:19, 20; Lúùkù 8:1; Róòmù 10:10.)