Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Fílípì 4:8—“Ohunkóhun Tó Jẹ́ Òótọ́, . . . Ẹ Máa Ronú Lórí Àwọn Nǹkan Yìí”

Fílípì 4:8—“Ohunkóhun Tó Jẹ́ Òótọ́, . . . Ẹ Máa Ronú Lórí Àwọn Nǹkan Yìí”

 “Paríparí rẹ̀, ẹ̀yin ará, ohunkóhun tó jẹ́ òótọ́, ohunkóhun tó ṣe pàtàkì, ohunkóhun tó jẹ́ òdodo, ohunkóhun tó jẹ́ mímọ́, ohunkóhun tó yẹ ní fífẹ́, ohunkóhun tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ohunkóhun tó bá dára, ohunkóhun tó bá yẹ fún ìyìn, ẹ máa ronú lórí àwọn nǹkan yìí.”—Fílípì 4:8, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Li akotan, ará, ohunkohun ti iṣe õtọ, ohunkohun ti iṣe ọ̀wọ, ohunkohun ti iṣe titọ́, ohunkohun ti iṣe mimọ́, ohunkohun ti iṣe fifẹ, ohunkohun ti o ni irohin rere; bi ìwa titọ́ kan ba wà, bi iyìn kan ba si wà, ẹ mã gbà nkan wọnyi rò.”—Fílípì 4:8, Bíbélì Mímọ́.

Ìtumọ̀ Fílípì 4:8

 Ọlọ́run máa ń fẹ́ mọ ohun tí àwa èèyàn ń rò, torí ohun tá à ń rò lọ́kàn la máa ń ṣe. (Sáàmù 19:14; Máàkù 7:20-23) Nítorí náà, àwọn tó bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run máa ń yẹra fún èrò tí kò dáa, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa ronú nípa ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run.

 Ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu ba nǹkan mẹ́jọ tó jẹ́ ohun rere tí àwọn Kristẹni lè “máa ronú” lé lórí, tàbí tá a fẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa rò.

  •   “Òótọ́.” Ọ̀rọ̀ yìí ń ṣàlàyé àwọn ohun tó jẹ́ òótọ́, tó sì ṣeé gbára lé. Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ àpẹẹrẹ ibi tí a ti lè rí àwọn òótọ́ ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.—1 Tímótì 6:20.

  •   “Tó ṣe pàtàkì.” Èyí jẹ́ kìkì àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe kókó, tó gbàfiyèsí, tí kò sì ṣeé fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú. Tí Kristẹni kan bá ń ronú nípa irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ kó lè pinnu láti ṣe ohun tó tọ́.—Títù 2:6-8.

  •   “Òdodo.” Ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ìwà àti ìṣe tó bá ìlànà Ọlọ́run mu nípa ohun tó dára, dípò ọgbọ́n orí èèyàn tó níbi tó mọ.—Òwe 3:5, 6; 14:12.

  •   “Mímọ́.” Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tá à ń rò àti ìdí tá a fi ń ṣe nǹkan gbọ́dọ̀ jẹ mímọ́, kì í ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ nìkan, àmọ́ nínú ohun gbogbo.—2 Kọ́ríńtì 11:3.

  •   “Tó yẹ ní fífẹ́.” Gbólóhùn ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí àwọn ohun tó ń dùn mọ́ni, tó ń mú kéèyàn nífẹ̀ẹ́ dípò èyí tó máa ń fa ìkórìíra, ìbínú tàbí ìjà.—1 Pétérù 4:8.

  •   “Tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa.” Gbólóhùn yìí ń tọ́ka sí àwọn ohun tó máa ń mú kí àwọn míì ní èrò tó dáa nípa ẹnì kan, àtàwọn ọ̀rọ̀ tó máa ń dáa lójú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.—Òwe 22:1.

  •   “Tó bá dára.” Ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí ìwà mímọ́ tó bá ìlànà Ọlọ́run mu. Ó jẹ́ ìwà tó dáa gan-an.—2 Pétérù 1:5, 9.

  •   “Tó bá yẹ fún ìyìn.” Ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí awọn ohun tó ń mórí ẹni wú, tó sì ní ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run. Lára ẹ̀ ni àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run tó yẹ fún ìyìn táwa èèyàn lè ronú nípa ẹ̀.—Sáàmù 78:4.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Fílípì 4:8

 Àtìmọ́lé ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà nílùú Róòmù nígbà tó kọ lẹ́tà sí àwọn Kristẹni tó wà nílùú Fílípì. Àmọ́ àwọn tó ń ṣàlàyé Bíbélì pe lẹ́tà rẹ̀ ní “lẹ́tà ìdùnnú” torí bó ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ to tura, tó fìfẹ́ hàn, tó sì dùn ún gbọ́.—Fílípì 1:3, 4, 7, 8, 18; 3:1; 4:1, 4, 10.

 Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nílùú Fílípì, ó sì fẹ́ kí wọ́n ní irú ayọ̀ àti àlàáfíà tí òun náà ní. (Fílípì 2:17, 18) Ní apá tó gbẹ̀yìn nínú lẹ́tà rẹ̀, Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n ní ìwà táá máa jẹ́ kí wọn láyọ̀, kí wọ́n máa fòye báni lò, kí wọ́n máa gbára lé Ọlọ́run nígbà gbogbo nípasẹ̀ àdúrà, kí wọ́n sì pọkàn pọ̀ sórí ohun tó lè jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀, kí wọ́n sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run.—Fílípì 4:4-9.

 Wo fídíò kékeré yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Fílípì.