Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Jòhánù 16:33—“Mo Ti Ṣẹgun Aiye”

Jòhánù 16:33—“Mo Ti Ṣẹgun Aiye”

 “Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín kí ẹ lè ní àlàáfíà nípasẹ̀ mi. Ẹ máa ní ìpọ́njú nínú ayé, àmọ́ ẹ mọ́kàn le! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”—Jòhánù 16:33, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin tẹlẹ̀, ki ẹnyin ki o le ni alafia ninu mi. Ninu aiye, ẹnyin o ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tújuka; mo ti ṣẹgun aiye.”—Johanu 16:33, Bíbélì Mímọ́.

Ìtumọ̀ Jòhánù 16:33

 Jésù sọ ọ̀rọ̀ yìí láti fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé àwọn náà lè ṣe ohun tó máa mú inú Jèhófà dùn kódà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro tàbí lójú àtakò.

 “Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín kí ẹ lè ní àlàáfíà nípasẹ̀ mi.” a Apá tó kù nínú ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí i pé àlàáfíà tí Jésù mẹ́nu bà yìí kò túmọ̀ sí pé èèyàn ò ní níṣòro kankan. Ohun tó túmọ̀ sí ni ìbàlẹ̀ ọkàn. A lè ní àlàáfíà yìí “nípasẹ̀” Jésù tó ṣèlérí pé òun máa rán ẹ̀mí mímọ́ wá. “Olùrànlọ́wọ́” tó lágbára yìí máa jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lè ṣàṣeyọrí kódà lójú ìṣòro èyíkéyìí.—Jòhánù 14:16, 26, 27.

 “Ẹ máa ní ìpọ́njú nínú ayé, àmọ́ ẹ mọ́kàn le!” Jésù jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀ pé wọ́n máa kojú àwọn ìṣòro, bíi kí wọ́n hùwà tí ò dáa sí wọn, wọ́n sì lè ṣe inúnibíni sí wọn. (Mátíù 24:9; 2 Tímótì 3:12) Síbẹ̀, wọ́n nídìí láti “mọ́kàn le,” tàbí “tújúká.”—Jòhánù 16:33, Bíbélì Mímọ́.

 “Mo ti ṣẹ́gun ayé.” Nínú ẹsẹ yìí, “ayé” ń tọ́ka sí àwùjọ àwọn èèyàn aláìṣòdodo tó jìnnà sí Ọlọ́run. b 1 Jòhánù 5:19 sọ pé: “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” tàbí Sátánì. Ìdí nìyẹn tí èrò àti ìṣe àwọn èèyàn “ayé” yìí kò fi bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.—1 Jòhánù 2:15-17.

 Sátánì àti ayé tó ń darí ò fẹ́ kí Jésù ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, wọn ò fẹ́ kó kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run, kó sì fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé rà wá pa dà. (Mátíù 20:28; Lúùkù 4:13; Jòhánù 18:37) Àmọ́ Jésù ò jẹ́ kí ayé yí òun lérò pa dà, kó wá kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Ó jẹ́ olóòótọ́, àní títí dójú ikú. Torí náà, Jésù lè sọ pé òun ti ṣẹ́gun ayé àti pé Sátánì tó jẹ́ “alákòóso ayé” yìí ‘kò ní agbára kankan’ lórí òun.—Jòhánù 14:30.

 Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ bó ṣe gbé ìgbésí ayé rẹ̀, èyí sì jẹ́ kó ṣe kedere sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé àwọn náà lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run kódà tí wọ́n bá ń kojú àwọn àdánwò tó lè dán ìṣòtítọ́ wọn wò. Torí náà, ńṣe ni Jésù ń fi àpẹẹrẹ rẹ̀ sọ fún wọn pé: “Tí mo bá lè ṣẹ́gun ayé, ẹ̀yìn náà lè ṣe é.”

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Jòhánù 16:33

 Alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú ló sọ ọ̀rọ̀ yìí. Ó mọ̀ pé wọ́n máa tó pa òun, torí náà, ó fi àsìkò yẹn fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ ní ìmọ̀ràn bó ṣe ń dá gbére fún wọn. Jésù tún sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì míì tó yẹ kí wọ́n fi sọ́kàn, ìyẹn ni pé: Wọn ò ní rí òun mọ́, àwọn èèyàn máa ṣe inúnibíni sí wọn, kódà wọ́n máa pa wọ́n. (Jòhánù 15:20; 16:2, 10) Jésù mọ̀ pé ó ṣeé ṣe káwọn ọ̀rọ̀ yẹn ba àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́rù. Torí náà, ó fi ọ̀rọ̀ inú Jòhánù 16:33 parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kó lè fún wọn níṣìírí, kó sì gbé wọn ró.

 Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù àti àpẹẹrẹ rẹ̀ lè fún àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níṣìírí lóde òní. Gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run bí wọ́n tiẹ̀ ń kojú ìṣòro.

a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “nípasẹ̀ mi” tún lè túmọ̀ sí “ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi.” Ìyẹn ń fi hàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lè ní àlàáfíà tí wọ́n bá wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀.

b Ọ̀rọ̀ náà “ayé” nínú ẹsẹ Bíbélì yìí bára mu pẹ̀lú bó ṣe wà nínú Jòhánù 15:19 àti 2 Pétérù 2:5.