Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Róòmù 6:23—“Ikú ni Èrè Ẹ̀ṣẹ̀, Ṣùgbọ́n Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni Ìyè Àìnípẹ̀kun Nínú Kristi Jesu Olúwa Wa”

Róòmù 6:23—“Ikú ni Èrè Ẹ̀ṣẹ̀, Ṣùgbọ́n Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni Ìyè Àìnípẹ̀kun Nínú Kristi Jesu Olúwa Wa”

 “Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, àmọ́ ìyè àìnípẹ̀kun ni ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fúnni nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”—Róòmù 6:23, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè àìnípẹ̀kun nínú Kristi Jesu Olúwa wa.”—Róòmù 6:23, Bíbélì Mímọ́ Ní Èdè Yorùbá Òde Òní.

Ìtumọ̀ Róòmù 6:23

 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ẹsẹ Bíbélì yìí ṣàlàyé pé ìdí táwa èèyàn fi ń kú ni pé a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Àmọ́, Ọlọ́run ṣèlérí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́.

 “Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀.” Gbogbo wa ni aláìpé nígbà tí wọ́n bí wa, torí náà kò sẹ́ni tí kì í dẹ́ṣẹ̀. a (Sáàmù 51:5; Oníwàásù 7:20) Torí pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ ìdí nìyẹn tá a fi ń darúgbó tá a sì ń kú.—Róòmù 5:12.

 Ká lè lóye kókó yìí, Pọ́ọ̀lù fi ẹ̀ṣẹ̀ wé ọ̀gá kan tó máa ń sanwó iṣẹ́. Bí òṣìṣẹ́ kan ṣe ń retí láti gba owó iṣẹ́, bákan náà ni àwa èèyàn aláìpé ń retí pé a máa kú lọ́jọ́ kan.

 Bákan náà, Pọ́ọ̀lù tún sọ pé ẹni “tó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” (Róòmù 6:7) Téèyàn bá kú a ti dá a sílẹ̀ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí kò fi bọ́gbọ́n mu ká máa ronú pé àwọn tó ti kú ń jìyà níbì kan nítorí àwọn àṣìṣe tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó ti kú ò mọ ohunkóhun, wọn ò lè ronú, tàbí ṣe nǹkan kan.—Oníwàásù 9:5.

 “Àmọ́ ìyè àìnípẹ̀kun ni ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fúnni nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” Bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ ní “èrè” tó ń san, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ń fúnni ní ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. Ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà “ẹ̀bùn” tún lè túmọ̀ sí “ẹ̀bùn tá ò lẹ́tọ̀ọ́ sí” tàbí “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́.” Ó ń tọ́ka sí ohun tá a fún ẹnìkan àmọ́ tí ò tíì lè lò ó. Kò sí èèyàn aláìpé kankan tó lè ní ìgbàlà tàbí ìyè àìnípẹ̀kun. (Sáàmù 49:7, 8) Àmọ́, Ọlọ́run fún àwọn tó ń lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́fẹ̀ẹ́, ìyẹn ẹ̀bùn tí kò ṣe é fowó rà.—Jòhánù 3:16; Róòmù 5:15, 18.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Róòmù 6:23

 Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yìí sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Kristẹni. Ó jọ pé lára àwọn Kristẹni yẹn ní èrò tí kò tọ́ nípa àánú Ọlọ́run. Torí pé ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Gíríìkì ni wọ́n ń tẹ̀ lé, wọ́n lè máa ronú pé báwọn bá ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ tó ni Ọlọ́run á ṣe máa dárí jì àwọn tó. (Róòmù 6:1) Èrò àwọn kan lára wọn ni pé, àwọn ò lè jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé àwọn ò sí lábẹ́ òfin Mósè mọ́. (Róòmù 6:15) Nínú lẹ́tà yìí, Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé àwọn Kristẹni ò lè rí àánú Ọlọ́run tí wọ́n bá jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa darí wọn.—Róòmù 6:12-14, 16.

 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ jẹ́ kó dá àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lónìí lójú pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àtìgbà tí wọ́n ti bí wọn ni wọ́n ti jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, wọ́n ṣì nírètí. Tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere tí Ọlọ́run fún wa, tí wọn ò sì fàyè gba ẹ̀ṣẹ̀, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Róòmù 6:22.

 Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Róòmù.

a Nínú Bíbélì, “ẹ̀ṣẹ̀” túmọ̀ sí ohunkóhun téèyàn ṣe tàbí ìwà téèyàn hù tí ò bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu. (1 Jòhánù 3:4) Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀?