Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Owó Ni Gbòǹgbò Ohun Búburú Gbogbo?

Ṣé Owó Ni Gbòǹgbò Ohun Búburú Gbogbo?

Ohun tí Bíbélì sọ

Rárá. Bíbélì kò sọ pé owó burú bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé owó ló ń ṣokùnfà gbogbo ohun búburú. Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé “owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo,” àmọ́ kì í ṣe bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ nìyẹn, ọ̀rọ̀ náà sì lè ṣí èèyàn lọ́nà. Ohun tí Bíbélì sọ ní ti gidi ni pé “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo.” a​—1 Tímótì 6:10, Bíbélì Mímọ́, àwa la kọ ọ̀rọ̀ lọ́nà tó dúdú yàtọ̀.

 Kí ni Bíbélì sọ nípa owó?

Bíbélì gbà pé owó wúlò, kódà tá a bá fi ọgbọ́n lò ó, ó lè jẹ́ “ààbò.” (Oníwàásù 7:12) Láfikún sí i, Bíbélì gbóríyìn fún àwọn tó lawọ́ sí àwọn míì, èyí tó lè gba pé kéèyàn fún ẹlòmíì ní ẹ̀bùn owó.—Òwe 11:25.

Àmọ́, Bíbélì kìlọ̀ pé kó dáa kéèyàn máa wá bó ṣe máa lówó lójú méjèèjì. Ó sọ pé: “Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín, bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn.” (Hébérù 13:5) Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé, kò yẹ ká jẹ́ kí owó gbà wá lọ́kàn, ká má sì máa lépa ọrọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí àwọn ohun tá a nílò ní ti gidi bí oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé tẹ́ wa lọ́rùn.—1 Tímótì 6:8

 Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé ká ṣọ́ra fún ìfẹ́ owó?

Àwọn olójúkòkòrò kò ní jogún ìyè àìnípẹ̀kun. (Éfésù 5:5) Lákọ̀ọ́kọ́ náà, lára ìbọ̀rìṣà tàbí ìjọsìn èké ni ojúkòkòrò jẹ́. (Kólósè 3:5) Ìkejì, torí pé àwọn olójúkòkòrò máa ń wá bí wọ́n ṣe máa di ọlọ́rọ̀ lọ́nàkọnà, wọ́n kì í sábà tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà rere. Òwe 28:20 sọ pé “ọwọ́ ẹni tó ń kánjú láti di olówó kò lè mọ́.” Ó tiẹ̀ lè tì wọ́n débí tí wọ́n á fi lọ́wọ́ nínú àwọn ìwàkiwà bí ìbanilórúkọjẹ́, lílu jìbìtì, ìkówójẹ, ìjínigbé tàbí ìpànìyàn pàápàá.

Ká tiẹ̀ sọ pé ìfẹ́ owó tẹ́nì kan ní kò mú kó hùwà búburú, síbẹ̀ àbàjáde rẹ̀ kì í bímọ re. Bíbélì sọ pé: “Àwọn tó pinnu pé àwọn fẹ́ di ọlọ́rọ̀ máa ń kó sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́ ọkàn tí kò bọ́gbọ́n mu, tó sì lè pani lára.”​—1 Tímótì 6:9.

 Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ owó?

Tá ò bá ṣe àwọn ohun tá a mọ̀ pé kò dáa àtàwọn ohun tí Ọlọ́run kórìíra torí owó, a máa níyì lójú àwọn èèyàn, a sì máa rí ojúure Ọlọ́run àti ìtìlẹ́yìn rẹ̀. Ọlọ́run ṣèlérí fún àwọn tó bá ń sapá láti wù ú tọkàntọkàn, pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.” (Hébérù 13:5, 6) Ó tún mú un dá wa lójú pé: “Olóòótọ́ èèyàn yóò gba ọ̀pọ̀ ìbùkún.”​—Òwe 28:20.

a Ìtumọ̀ Bíbélì míì tu ẹsẹ yẹn lọ́nà yìí: “Ìfẹ́ owó ni ọ̀kan lára ohun tó ń fa onírúurú jàǹbá.”