Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Àwọn ọmọdé àti Fóònù​—Apá Àkọ́kọ́: Ṣó Yẹ Kí Ọmọ Mi Ní Fóònù?

Àwọn ọmọdé àti Fóònù​—Apá Àkọ́kọ́: Ṣó Yẹ Kí Ọmọ Mi Ní Fóònù?

 Iye àwọn ọmọdé tó ní fóònù a ń pọ̀ sí i, ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì máa ń lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nígbà tí wọ́n bá dá wà. Ewu wo ló wà níbẹ̀ tó o bá jẹ́ kí ọmọ rẹ ní fóònù? Àǹfààní wo ló wà níbẹ̀? Ìgbà mélòó ló yẹ kó o jẹ́ kó lò ó lójúmọ́?

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

 Àǹfààní

  •   Ó ń dáàbò bo àwọn ọmọdé, ó sì ń fi àwọn òbí lọ́kàn balẹ̀. Bethany tó jẹ́ ìyá àwọn ọ̀dọ́ méjì kan sọ pé: “Ayé eléwu là ń gbé. Ó ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọ mọ bí wọ́n ṣe lè máa pe àwọn òbí wọn lórí fóònù.”

     Ìyá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Catherine tiẹ̀ sọ bí fóònù ṣe wúlò tó. Ó sọ pé “O lè lo àwọn ètò ìṣiṣẹ́ kan lórí fóònù ẹ tó máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú fóònù ọmọ rẹ, táá jẹ́ kó o mọ ibi tí ọmọ ẹ wà. Tó bá ń wa mọ́tò, o tiẹ̀ lè rí bó ṣe ń sáré sí.”

  •   Wọ́n lè fi ṣiṣẹ́ ilé ìwé. Ìyá kan tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Marie sọ pé: “Àwọn ọmọdé lè gba iṣẹ́ àṣetiléwá nípasẹ̀ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tàbí àtẹ̀jíṣẹ́, wọ́n sì lè bá àwọn olùkọ́ wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà kan náà.”

 Ewu

  •   Wọ́n máa ń pẹ́ gan-an nídìí ẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lórí fóònù wọn lójoojúmọ́. Kódà, bí àwọn òbí ṣe ń lo ọ̀pọ̀ àkókò lórí fóònù wọn náà ni wọ́n ń lo àkókò púpọ̀ láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìdílé ni a lè fi wé àwùjọ àwọn àjèjì tó wà papọ̀ tí wọn ò yéé tẹjú mọ́ fóònù wọn.” b

  •   Àwòrán ìṣekúṣe. Ìwádìí fi hàn pé, ìdajì àwọn ọ̀dọ́ ló ń àwòrán ìṣekúṣe kiri lóṣooṣù. Ìsọfúnni yìí ò yani lẹ́nu torí pé ó rọrùn gan-an láti fi fóònù wá àwòrán ìṣekúṣe. William tó jẹ́ bàbá àwọn ọ̀dọ́ méjì kan sọ pé: “Táwọn òbí bá jẹ́ káwọn ọmọ wọn ní fóònù, láìmọ̀, ṣe ni wọ́n fàyè gba ọmọ wọn láti máa wo onírúurú àwòrán ìṣekúṣe níbikíbi.”

  •   Ó lè di bárakú. Fóònù ti di bárakú fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Tí wọn ò bá rí fóònù wọn, wọ́n máa ń sọ pé ọkàn àwọn ò balẹ̀, wọ́n á ní àwọn ò mọ ohun tí wọ́n máa ṣe, àti pé ara àwọn ò yá. Àwọn òbí kan sọ pé, lásìkò táwọn ọmọ wọn bá ń lo fóònù, wọ́n máa ń hùwà ọ̀yájú. Carmen sọ pé: “Tí mo bá n bá ọmọkùnrin mi sọ̀rọ̀, ojú ẹ̀ máa ń le tàbí kó sọ̀rọ̀ tí kò fọ̀wọ̀ hàn torí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni dí i lọ́wọ́.”

  •   Ewu míì. Ewu míì tí fóònù máa ń fà ni bíba èèyàn lórúkọ jẹ́ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì àti fifi ohun tó ń mọ́kàn fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ síni lórí fóònù, ó sì lè fa onírúurú àìlera bíi kéèyàn má lè dúró dáadáa kó má sì rórun sùn. Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń lo ètò ìṣiṣẹ́ kan lórí fóònù wọn tó máa ń fi ohun tí wọn ò fẹ́ káwọn òbí wọn rí pamọ́.

     Daniel tó jẹ́ bàbá ọ̀dọ́bìnrin kan ṣàkópọ̀ rẹ̀ lọ́nà yìí: “Fóònù mú kó ṣeé ṣe fún ọmọ rẹ láti rí gbogbo ohun tó wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, bóyá ó dáa tàbí kò dáa.”

 Ohun tó yẹ kó o béèrè

  •   ‘Ṣe ọmọ mi nílò fóònù?’

     Bíbélì sọ pé: “Aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.” (Òwe 14:15) Èyí lè mú kó o béèrè lọ́wọ́ ara ẹ pé:

     ‘Ṣé ó máa bọ́gbọ́n mu pé kí ọmọ mi ní fóònù torí ààbò tàbí torí àwọn ìdí míì? Ṣe mo ti fara balẹ̀ ronú lórí àǹfààní àti ewu tó wà nínú ẹ̀? Ṣe ohun míì wà tí mo lè lò dípò fóònù?’

     Bàbá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Todd sọ pé: “O lè ra fóònù tí kì í lo Íńtánẹ́ẹ̀tì fọ́mọ rẹ, wàá lè máa pè é tàbí kó o fi fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i. Fóònù yìí ò sì wọ́n rárá.”

  •   ‘Ṣé ọmọ mi ti ṣe tán láti bójú tó ojúṣe yìí?’

     Bíbélì sọ pé: “Ọkàn ọlọ́gbọ́n ń darí rẹ̀ sí ọ̀nà tí ó tọ́.” (Oníwàásù 10:2) Èyí lè mú kó o béèrè lọ́wọ́ ara ẹ pé:

     ‘Kí ló mú kí n gbà pé ọmọ mi ṣe é fọkàn tán? Ṣó máa ń bá mi sọ̀rọ̀? Ṣé ọmọ mi máa ń sòótọ́ fún mi, pàápàá tó bá kan ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀? Ṣé ó máa ń kó ara ẹ̀ níjàánu tó bá ń lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé míì bíi tẹlifíṣọ̀n, tábúlẹ́ẹ̀tì tàbí kọ̀ǹpútà?’ Ìyá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Serena sọ pé: “Fóònù wúlò gan-an, àmọ́, ó tún lè léwu gan-an. Ronú nípa ojúṣe tọ́mọ rẹ máa ní lákòókò tí kò tíì nírìírí rárá.”

  •   ‘Ṣe mo ti ṣe tán láti bójú tó ojúṣe yìí?’

     Bíbélì sọ pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀.” (Òwe 22:​6, àlàyé ìsàlẹ̀) Èyí lè mú kó o béèrè lọ́wọ́ ara ẹ pé:

     ‘Ṣe mo mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa fóònù náà kí n lè ran ọmọ mi lọ́wọ́ kó lè lóye, kó sì yẹra fún ewu? Ṣé mo mọ nǹkan tí màá tẹ̀ lórí fóònù ẹ̀ tí kò fi ní lọ síbí tó léwu? Báwo ni màá ṣe ran ọmọ mi lọ́wọ́ kó lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání nígbà tó bá ń lo fóònù náà?’ Daniel, bàbá tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ó dunni pé ọ̀pọ̀ òbí kàn máa ń fún àwọn ọmọ wọn ní fóònù tí wọn ò sì ní mọ báwọn ọmọ wọn ṣe ń lò ó.”

 Kókó ibẹ̀: Àwọn ọmọdé nílò ká kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè lo fóònù lọ́nà tó dára. Ìwé kan tó ń jẹ́ Indistractable sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọmọdé ni kò lè ṣe kí wọ́n má lo àkókò tó pọ̀ nídìí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé yìí, pàápàá táwọn òbí ò bá mọ ohun tí wọ́n ń ṣe lórí ẹ̀ tàbí tí wọ́n ò bá tọ́ wọn sọ́nà.”

a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, fóònù tá à ń sọ ní àwọn fóònù tó lè lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

b Látinú ìwé Disconnected, látọwọ́ Thomas Kersting.