Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ẹsẹ Bíbélì fún Ọjọ́ Kọ̀ọ̀kan

Ẹsẹ Bíbélì fún Ọjọ́ Kọ̀ọ̀kan

Ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ máa ń ní ẹsẹ Bíbélì kan pàtó fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àti àlàyé ẹsẹ Bíbélì náà. Bó o ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ìwé yìí á jẹ́ kó o lè máa ronú lórí àwọn nǹkan rere tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tó wà nínú Bíbélì.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sígbà téèyàn ò lè ka ẹsẹ ojúmọ́ náà àti àlàyé rẹ̀, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ gbà pé ó dáa kéèyàn kà á láàárọ̀. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè máa ronú lé e lórí jálẹ̀ ọjọ́ náà. Tó bá jẹ́ pé o ti ní ìdílé, á dáa kẹ́ ẹ jọ ka ẹsẹ ojúmọ́ náà pa pọ̀.

Wàá rí ẹsẹ ojúmọ́ yìí lórí ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower, o sì lè wa gbogbo ti ọdún kan jádè ní ẹ̀dà PDF.