Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ló Dé Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Ṣe Kérésìmesì?

Kí Ló Dé Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Ṣe Kérésìmesì?

Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn sábà máa ń ní

Irọ́: Torí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò gba Jésù gbọ́ ni ò jẹ́ kí wọ́n máa ṣe Kérésìmesì.

 Òótọ́: Kristẹni ni wá. A gbà pé nípasẹ̀ Jésù Kristi nìkan la fi lè rí ìgbàlà.—Ìṣe 4:12.

Irọ́: Ṣe lẹ̀ ń da ìdílé rú bẹ́ ẹ ṣe ń kọ́ àwọn ará ìjọ yín pé kí wọ́n má ṣe Kérésìmesì.

 Òótọ́: Ọ̀rọ̀ ìdílé jẹ wá lógún gan-an, ṣe la máa ń fi Bíbélì ran àwọn tó wà nínú ìdílé lọ́wọ́ kí àjọṣe àárín wọn lè dá a sí i.

Irọ́: Àsìkò Kérésìmesì lèèyàn máa ń lawọ́ sáwọn ẹlòmíì, tí àlàáfíà máa ń wà, táwọn èèyàn sì máa ń rí ojúure Ọlọ́run. Gbogbo ìyẹn lẹ fi ń du ara yín.

 Òótọ́: Ojoojúmọ́ la máa ń sapá láti jẹ́ ọ̀làwọ́, ká sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. (Òwe 11:25; Róòmù 12:18) Bí àpẹẹrẹ, bá a ṣe máa ń ṣe àwọn ìpàdé wa àti bá a ṣe ń wàásù bá ìtọ́ni tí Jésù fún wa mu. Ó ní: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:8) Bákan náà, ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run la máa ń sọ fáwọn èèyàn, pé ìjọba yẹn nìkan ló lè mú àlàáfíà wá sáyé.—Mátíù 10:7.

Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe Kérésìmesì?

  •   Ikú rẹ̀ ni Jésù pàṣẹ fún wa pé ká máa rántí, kò ní ká máa ṣèrántí ọjọ́ ìbí òun.—Lúùkù 22:19, 20.

  •   Àwọn àpọ́sítélì Jésù àtàwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn nígbà yẹn kì í ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé “kò sí nǹkan tó ń jẹ́ ayẹyẹ Kérésìmesì ṣáájú ọdún 243 [S.K.], ẹ̀yìn ọdún yẹn ni wọ́n dá a sílẹ̀,” ìyẹn ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ọdún lẹ́yìn ikú àpọ́sítélì tó gbẹ̀yìn.

  •   Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé December 25 ni wọ́n bí Jésù; Bíbélì ò sọ ọjọ́ tí wọ́n bí i.

  •   A gbà pé Ọlọ́run ò fọwọ́ sí ayẹyẹ Kérésìmesì, torí pé inú àṣà àti ẹ̀sìn àwọn Kèfèrí ló ti wá.—2 Kọ́ríńtì 6:17.

Kí ló dé tí ẹ jẹ́ kí tiyín yàtọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Kérésìmesì?

 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ pé inú ẹ̀sìn Kèfèrí ni Kérésìmesì ti wá, pé kò sí nínú Bíbélì, síbẹ̀ wọ́n ń ṣe é. Ó yẹ kírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bi ara wọn pé: Kí nìdí tó fi yẹ kí tàwọn Kristẹni yàtọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ló ń ṣe é?

 Bíbélì rọ̀ wá pé kí àwa fúnra wa máa ronú, ó ní ká máa lo “agbára ìmọnúúrò” wa. (Róòmù 12:1, 2) Ó kọ́ wa pé ká mọyì òtítọ́. (Jòhánù 4:23, 24) Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a fẹ́ káwọn èèyàn máa fojú tó dáa wò wá, àwọn ìlànà Bíbélì la máa ń tẹ̀ lé, kódà tíyẹn bá máa mú kí tiwa yàtọ̀ láàárín gbogbo èèyàn.

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa kì í ṣe Kérésìmesì, a gbà pé kálukú ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí. A kì í dí àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n má ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì.