Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 28, 2018
SOUTH KOREA

Ìdájọ́ Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ ní Ilé Ẹjọ́ Tó Ń Rí Sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Nílẹ̀ Korea: Kò Bófin Mu Bí Kò Ṣe Sí Iṣẹ́ Míì Téèyàn Lè Fi Sìnlú

Ìdájọ́ Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ ní Ilé Ẹjọ́ Tó Ń Rí Sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Nílẹ̀ Korea: Kò Bófin Mu Bí Kò Ṣe Sí Iṣẹ́ Míì Téèyàn Lè Fi Sìnlú

Ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù June, ọdún 2018 ni ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn ilẹ̀ South Korea tí Ilé Ẹjọ́ Tó Ń Rí Sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn máa sọ pé apá kan lára Ìlànà Iṣẹ́ Ológun Ilẹ̀ Korea, ìyẹn “Korea’s Military Service Act (MSA)” kò bófin mu, torí pé kò gba àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológún láyè láti ṣe iṣẹ́ míì. Ìdájọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí ló máa yí ìlànà “MSA” tó ti wà látọdún márùndínláàádọ́rin (65) sẹ́yìn pa dà, ìyẹn ìdájọ́ tó sọ pé kí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun máa lọ sẹ́wọ̀n.

Láti ọdún 1953, ó ju ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (19,300) àwọn ará wa tí wọ́n ti rán lẹ́wọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì ó lé ọgọ́rùn-ún méje (36,700) ọdún lápapọ̀. Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Nílẹ̀ Korea á lè lo ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ yìí ṣe nínú ọ̀rọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Yàtọ̀ síyẹn, ó ti wá di dandan pé káwọn tó wà nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ Korea dá iṣẹ́ míì téèyàn lè fi sìnlú sílẹ̀, ó pẹ́ tán December 31, 2019. Iṣẹ́ yìí làwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológún á máa ṣe.

Gbogbo wa la bá àwọn ará wa ní Korea yọ̀ pé ohun tó máa fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ tí wọ́n ti ń hù sí wọn láti ọ̀pọ̀ ọdún ti ṣeé ṣe.​—Òwe 15:30.