Sáàmù 104:1-35
104 Jẹ́ kí n* yin Jèhófà.+
Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, o tóbi gan-an.+
O fi ògo* àti ọlá ńlá wọ ara rẹ láṣọ.+
2 O fi ìmọ́lẹ̀+ bora bí aṣọ;O na ọ̀run bí aṣọ àgọ́.+
3 Ó tẹ́ igi àjà àwọn yàrá òkè rẹ̀ sínú omi lókè,*+Ó fi àwọsánmà ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀,+Ó ń lọ lórí ìyẹ́ apá ẹ̀fúùfù.+
4 Ó dá àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ní ẹ̀mí,Ó dá àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ní iná tó ń jó nǹkan run.+
5 Ó ti gbé ayé kalẹ̀ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀;+A kì yóò ṣí i nípò* títí láé àti láéláé.+
6 O fi ibú omi bò ó bí aṣọ.+
Omi náà bo àwọn òkè.
7 Bí wọ́n ṣe gbọ́ ìbáwí rẹ, wọ́n fẹsẹ̀ fẹ;+Bí wọ́n ṣe gbọ́ ìró ààrá rẹ, ìbẹ̀rù mú kí wọ́n sá lọ
8 —Àwọn òkè lọ sókè,+ àwọn àfonífojì sì lọ sílẹ̀—Sí ibi tí o ṣe fún wọn.
9 O pa ààlà tí wọn ò gbọ́dọ̀ kọjá,+Kí wọ́n má bàa bo ayé mọ́.
10 Ó ń mú kí omi sun jáde ní àwọn àfonífojì;Wọ́n ń ṣàn gba àárín àwọn òkè.
11 Wọ́n ń pèsè omi fún gbogbo ẹran inú igbó;Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó ń fi wọ́n pa òùngbẹ.
12 Orí àwọn igi tó wà létí wọn ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ń wọ̀ sí;Wọ́n ń kọrin láàárín àwọn ẹ̀ka tó léwé dáadáa.
13 Ó ń bomi rin àwọn òkè láti àwọn yàrá òkè rẹ̀.+
Iṣẹ́ ọwọ́* rẹ ń tẹ́ ilẹ̀ ayé lọ́rùn.+
14 Ó ń mú kí koríko hù fún àwọn ẹran orí pápá láti jẹÀti ewéko fún ìlò aráyé,+Kí oúnjẹ lè jáde látinú ilẹ̀
15 Àti wáìnì tó ń mú ọkàn èèyàn yọ̀,+Òróró tó ń mú kí ojú dánÀti oúnjẹ tó ń gbé ẹ̀mí ẹni kíkú ró.+
16 Àwọn igi Jèhófà rí omi mu,Àwọn igi kédárì Lẹ́bánónì tó gbìn,
17 Ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ ń kọ́ ìtẹ́ sí.
Ilé ẹyẹ àkọ̀+ wà lórí àwọn igi júnípà.
18 Àwọn òkè gíga wà fún àwọn ewúrẹ́ orí òkè;+Àwọn àpáta gàǹgà jẹ́ ibi ààbò fún àwọn gara orí àpáta.+
19 Ó dá òṣùpá láti máa sàmì àkókò;Oòrùn mọ ìgbà tó yẹ kó wọ̀.+
20 O mú kí òkùnkùn ṣú, alẹ́ sì lẹ́,+Gbogbo ẹranko inú igbó sì ń jẹ̀ kiri.
21 Àwọn ọmọ kìnnìún* ń ké ramúramù nítorí ẹran tí wọ́n fẹ́ pa jẹ,+Wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+
22 Nígbà tí oòrùn bá yọ,Wọ́n á pa dà, wọ́n á sì lọ dùbúlẹ̀ sínú ihò wọn.
23 Èèyàn á lọ sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀,Á sì ṣiṣẹ́ títí di àṣálẹ́.
24 Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà!+
Gbogbo wọn lo fi ọgbọ́n ṣe.+
Ayé kún fún àwọn ohun tí o ṣe.
25 Ibẹ̀ ni òkun wà, ó tóbi, ó sì fẹ̀,Àìmọye ohun alààyè ló wà nínú rẹ̀, èyí tó kéré àti èyí tó tóbi.+
26 Ibẹ̀ ni àwọn ọkọ̀ òkun ti ń rìnÀti Léfíátánì,*+ tí o dá kí ó lè máa ṣeré nínú rẹ̀.
27 Gbogbo wọn ń dúró dè ọ́Kí o lè fún wọn ní oúnjẹ lásìkò.+
28 Ohun tí o fún wọn ni wọ́n ń kó jọ.+
Tí o bá ṣí ọwọ́ rẹ, wọ́n á ní ọ̀pọ̀ ohun rere ní ànító.+
29 Tí o bá gbé ojú rẹ pa mọ́, ìdààmú á bá wọn.
Tí o bá mú ẹ̀mí wọn kúrò, wọ́n á kú, wọ́n á sì pa dà sí erùpẹ̀.+
30 Tí o bá rán ẹ̀mí rẹ jáde, a ó dá wọn,+Ìwọ á sì sọ ojú ilẹ̀ di ọ̀tun.
31 Ògo Jèhófà yóò wà títí láé.
Jèhófà yóò máa yọ̀ lórí àwọn iṣẹ́ rẹ̀.+
32 Ó wo ayé, ayé sì mì tìtì;Ó fọwọ́ kan àwọn òkè, wọ́n sì rú èéfín.+
33 Màá kọrin sí Jèhófà+ jálẹ̀ ayé mi;Màá kọ orin ìyìn* sí Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá fi wà láàyè.+
34 Kí èrò mi dùn mọ́ ọn.*
Èmi yóò máa yọ̀ nínú Jèhófà.
35 Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò pa rẹ́ kúrò láyé,Àwọn ẹni burúkú kò sì ní sí mọ́.+
Jẹ́ kí n* yin Jèhófà. Ẹ yin Jáà!*
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “iyì.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Ní Héb., “sínú omi.”
^ Tàbí “mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”
^ Tàbí “Èso iṣẹ́.”
^ Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “kọrin.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Kí ohun tí mò ń rò nípa rẹ̀ dùn mọ́ni.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.