Sáàmù 142:1-7
Másíkílì.* Ti Dáfídì, nígbà tó wà nínú ihò àpáta.+ Àdúrà.
142 Mo fi ohùn mi ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́;+Mo fi ohùn mi bẹ Jèhófà pé kó ṣojú rere sí mi.
2 Mo tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde níwájú rẹ̀;Mo sọ nípa wàhálà mi níwájú rẹ̀+
3 Nígbà tí àárẹ̀ mú ẹ̀mí mi.*
Ò ń ṣọ́ ọ̀nà mi.+
Wọ́n dẹ pańpẹ́ pa mọ́ dè míNí ọ̀nà tí mò ń rìn.
4 Wo ọwọ́ ọ̀tún mi, kí o sì rí iPé kò sẹ́ni tó rí tèmi rò.*+
Kò síbi tí mo lè sá lọ;+Kò sẹ́ni tí ọ̀rọ̀ mi* ká lára.
5 Jèhófà, mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.
Mo sọ pé: “Ìwọ ni ibi ààbò mi,+Gbogbo ohun tí mo ní* lórí ilẹ̀ alààyè.”
6 Fetí sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,Nítorí wọ́n ti bá mi kanlẹ̀.
Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi,+Torí wọ́n lágbára jù mí lọ.
7 Mú mi* jáde kúrò nínú àjà ilẹ̀Kí n lè máa yin orúkọ rẹ.
Kí àwọn olódodo yí mi ká,Nítorí o ti ṣemí lóore.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “tí mi ò lágbára mọ́.”
^ Ní Héb., “tó dá mi mọ̀.”
^ Tàbí “ọ̀rọ̀ ọkàn mi.”
^ Ní Héb., “Ìpín mi.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”