Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Gbogbo Ẹ̀sìn Ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí?

Ṣé Gbogbo Ẹ̀sìn Ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí?

Ṣé Gbogbo Ẹ̀sìn Ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí?

Àwọn kan lè dáhùn pé:

▪ “Kò sí ẹ̀sìn tínú Ọlọ́run ò dùn sí, Ọlọ́run kan náà ṣáà ni gbogbo wa ń sìn.”

▪ “Ohun tó o gbà gbọ́ ò ṣe pàtàkì, tó o bá ṣáà ti jólóòótọ́.”

Kí ni Jésù sọ?

▪ Jésù sọ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” (Mátíù 7:13, 14) Jésù ò gbà gbọ́ pé gbogbo ẹ̀sìn ní inú Ọlọ́run dùn sí.

▪ Jésù sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’ Síbẹ̀síbẹ̀, ṣe ni èmi yóò jẹ́wọ́ fún wọn pé: Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.” (Mátíù 7:22, 23) Jésù ò tẹ́wọ́ gba gbogbo àwọn tó sọ pé àwọ́n ń tẹ̀ lé e.

Ọ̀PỌ̀ lára àwọn ẹlẹ́sìn ni kì í fohun tí wọ́n gbà gbọ́ àtàwọn àṣà ẹ̀sìn wọn ṣeré. Àmọ́ táwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́ yìí ò bá bá ohun tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu ńkọ́? Jésù jẹ́ ká mọ ewu tó wà nínú títẹ̀lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ èèyàn, ó sọ fáwọn aṣáájú ìsìn nígbà tó wà láyé pé: “Ẹ ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ nítorí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín.” Lẹ́yìn náà ló wá fa ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ yọ pé: “Àwọn ènìyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi, síbẹ̀ ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí mi. Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni bí ẹ̀kọ́.”—Mátíù 15:1-9; Aísáyà 29:13.

Yàtọ̀ sóhun téèyàn gbà gbọ́, ìwà tún ṣe pàtàkì. Bíbélì sọ nípa àwọn kan tó fẹnu lásán sọ pé àwọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run, ó ní: “Wọ́n polongo ní gbangba pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ wọn.” (Títù 1:16) Kódà, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó wà láyé lásìkò wa yìí pé: ‘Wọ́n fẹ́ràn fàájì dípò kí wọ́n fẹ́ràn Ọlọ́run. Ní òde ara, wọn dà bí olùfọkànsìn, ṣùgbọ́n wọn kò mọ agbára ẹ̀sìn tòótọ́. Ní tìrẹ, jìnnà sí irú àwọn èèyàn báyìí.’—2 Tímótì 3:4, 5, Ìròhìn Ayọ̀.

Òótọ́ ni pé ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run, àmọ́ ó tún jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé èèyàn lè máa fi tọkàntọkàn ṣohun tí kò tọ̀. Nítorí náà, ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run ṣe pàtàkì. (Róòmù 10:2, 3) Torí náà, níní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti fífàwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì ṣèwà hù máa jẹ́ kínú Ọlọ́run dùn sí wa. (Mátíù 7:21) Ká sòótọ́, kéèyàn tó lè sọ pé ìsìn tòótọ́ lòun ń ṣe, ó ní láti máa ṣe é pẹ̀lú ọkàn tó tọ́, kó gba ohun tó tọ́ gbọ́, kó sì máa ṣohun tó tọ́. Kéèyàn sì tó lè máa ṣohun tó tọ́, ó ní láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́!—1 Jòhánù 2:17.

Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run, wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn, kó o sì ní kí wọ́n wá máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ́fẹ̀ẹ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

Kéèyàn tó lè sọ pé ìsìn tòótọ́ lòun ń ṣe, ó ní láti máa ṣe é pẹ̀lú ọkàn tó tọ́, kó gba ohun tó tọ́ gbọ́, kó sì máa ṣohun tó tọ́