Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ọmọ Títọ́

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ọmọ Títọ́

Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ọmọ Títọ́

Fẹ́mi: a Káwọn òbí mi tó bá mi wí lórí àṣìṣe èyíkéyìí tí mo bá ṣe, wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti kọ́kọ́ mọ ìdí tí mo fi ṣe é àtohun tó ṣeé ṣe kó fà á. Mo sì máa ń gbìyànjú láti fara wé wọn nígbà tí mo bá ń bá àwọn ọmọbìnrin mi wí. Àmọ́, bí wọ́n ṣe tọ́ Kẹ́mi, ìyàwó mi dàgbà yàtọ̀. Àwọn òbí ẹ̀ kì í fi nǹkan falẹ̀. Wọn kì í sábà ronú lórí ohun tó mú káwọn ọmọ ṣe ohun tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí nà wọ́n tàbí kí wọ́n sọ̀rọ̀ gbá wọn lórí. Nígbà míì mo máa ń ronú pé ọ̀nà tó rorò yẹn nìyàwó mi náà máa ń gbà bá àwọn ọmọ wa wí.

Bólú: Ọmọ ọdún márùn-ún péré ni mí nígbà tí bàbá mi ti fi wá sílẹ̀ lọ. Wọn ò tiẹ̀ rí tèmi àtàwọn àbúrò mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta rò. Ńṣe ni màámi máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè fún wa láwọn nǹkan tá a nílò, ohun témi náà sì ń gbé ṣe láti ran àwọn àbúrò mi obìnrin lọ́wọ́ kò kéré rárá. Kò rọrùn fún mi láti gbádùn ìgbà ọ̀dọ́ mi, torí pé ojúṣe òbí ni mò ń ṣe. Títí dòní olónìí, iṣẹ́ ni mo máa ń ṣe bí aago, mi kì í sábà ń ṣeré. Tí mo bá fẹ́ báwọn ọmọ mi wí, mo máa ń fara balẹ̀ ronú lórí àwọn àṣìṣe wọn. Mo máa ń fẹ́ mọ ìdí tí wọ́n fi ṣohun tí wọ́n ṣe. Kọ́lá, ọkọ mi, ò ráyè ìrégbè, kì í pẹ́ ẹ rárá kó tó lóye ohun tó ṣẹlẹ̀. Bàbá ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ lóòótọ́, ó sì máa ń wáyè gbọ́ ti màmá ẹ̀, àmọ́ wọn ò gbàgbàkugbà. Kì í fọ̀rọ̀ bíbá àwọn ọmọbìnrin wa wí falẹ̀. Tó bá ti ronú lórí ọ̀ràn kan níwọ̀nba, tó sì ti ṣàwọn àtúnṣe tó yẹ, ó ń bá tiẹ̀ lọ nìyẹn.

BÓ O ṣe rí i nínú ìrírí Fẹ́mi àti Bólú, bí wọ́n ṣe tọ́ ìwọ alára dàgbà lè nípa tó pọ̀ lórí bí wàá ṣe máa bá àwọn ọmọ ẹ wí. Tó bá jẹ́ pé bí wọ́n ṣe tọ́ ọkọ àti ìyàwó ò dọ́gba, ó ṣeé ṣe kí ọ̀nà tí wọ́n á máa gbà tọ́mọ yàtọ̀ síra. Nígbà míì, ìyàtọ̀ yìí máa ń fa ìṣòro láàárín tọkọtaya.

Ìṣòro yìí tún lè légbá kan tọ́rọ̀ náà bá ti tojú sú wọn. Àwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bímọ máa ń rí i pé kó rọrùn láti tọ́mọ, bí ìgbà téèyàn ń ṣiṣẹ́ bóojí-o-jími ni. Bùnmi tóun àti Dáre, ọkọ ẹ̀ ti tọ́ àwọn ọmọbìnrin méjì dàgbà sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọbìnrin mi gan-an, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ní wọ́n kì í gbọ́ tèmi tí mo bá ní kí wọ́n lọ sùn. Ìgbà tó bá yẹ kí wọ́n máa sùn ni wọ́n á ranjú kalẹ̀ rangbọndan. Wọ́n máa ń já lu ọ̀rọ̀ mi. Wọ́n kì í kó aṣọ, bàtà àtàwọn nǹkan ìṣeré wọn pa dà síbi tí wọ́n ti kó o, tí wọ́n bá sì lo bọ́tà tán wọn ò jẹ́ gbé e pa dà sínú fìríìjì.”

Táyọ̀, tíyàwó ẹ̀ ní ìṣòro àbísínwín nígbà tó bímọ kejì sọ pé: “Ó ti máa ń rẹ̀ mí tẹnutẹnu nígbà tí mo bá fi máa dé láti ibi iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ọmọ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ò tún ní jẹ́ kí n sùn láàárín òru. Ìyẹn ò jẹ́ kí n lè ráyè tọ́ ọmọbìnrin wa àkọ́bí bó ṣe yẹ. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í jowú pé a ò ráyè gbọ́ tòun, tàbúrò òun la máa ń gbọ́ ní gbogbo ìgbà.”

Nígbà táwọn òbí tó ti rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí í jiyàn lórí bó ṣe yẹ kí wọ́n tọ́mọ, ọ̀rọ̀ kékeré sábà máa ń di ńlá mọ́ wọn lọ́wọ́. Àríyànjiyàn tí ò lójú lè mú kí tọkọtaya fi ara wọn sílẹ̀, ìyẹn á sì wá jẹ́ kọ́mọ wọn túbọ̀ ráyè máa lo agbárí fáwọn òbí ẹ̀ kó lè máa róhun tó bá ń fẹ́. Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ láti ṣera wọn lọ́kan bí wọ́n ti ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti tọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́nà tó gbéṣẹ́?

Ẹ Máa Wáyè Láti Gbọ́ Tara Yín

Ètò tí Ọlọ́run ti ṣe ni pé kí ọkọ àtìyàwó ti wà pa pọ̀ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ, kí wọ́n sì máa wà pa pọ̀ nìṣó lẹ́yìn táwọn ọmọ bá ti dàgbà tí wọ́n sì ti kúrò nílé. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó, ó ní: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mátíù 19:6) Tá a bá lóye ẹsẹ Bíbélì yìí dáadáa, a máa rí i pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ọmọ fi “baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀” sílẹ̀ nígbà tó bá yá. (Mátíù 19:5) Ká sòótọ́, kì í ṣe torí ọmọ títọ́ ní Ọlọ́run fi ṣètò ìgbéyàwó, ó kàn wulẹ̀ jẹ́ apá kan ojúṣe àwọn tó ti ṣègbéyàwó ni. Òótọ́ ni pé àwọn òbí gbọ́dọ̀ lo àkókò tó pọ̀ tó láti tọ́ àwọn ọmọ wọn, àmọ́ wọn ò tún gbọ́dọ̀ gbàgbé pé wọn ò ní lè bójú tó ojúṣe yìí tí àárín àwọn fúnra wọn ò bá gún.

Báwo làwọn tọkọtaya ṣe lè ṣera wọn lọ́kan láwọn àkókò tí wọ́n bá ṣì ń tọ́ àwọn ọmọ wọn? Ọ̀nà kan ni pé, tó bá ṣeé ṣe, kí wọ́n máa wáyè láti gbọ́ tara wọn láìsí àwọn ọmọ nítòsí. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè jíròrò àwọn ọ̀ràn pàtàkì tó ń lọ nínú ìdílé, á sì jẹ́ kí wọ́n lè gbádùn ara wọn. Ká sòótọ́, kò rọrùn fáwọn tọkọtaya láti ráyè gbọ́ tara wọn. Kẹ́mi tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Ìgbà témi àti ọkọ mi bá ní ká tiẹ̀ fàkókò díẹ̀ tá a ní gbádùn ara wa lọmọbìnrin wa àbígbẹ̀yìn máa fẹ́ ká gbé òun mọ́ra tàbí kéyìí àgbà tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà bẹ̀rẹ̀ ìjàngbọ̀n, bóyá torí kò rí kereyọ́ọ̀nù tó fi ń yàwòrán.”

Bólú àti Kọ́lá, tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣètò láti máa ráyè gbọ́ tara wọn nípa pípinnu ìgbà táwọn ọmọbìnrin wọn gbọ́dọ̀ lọ sùn. Bólú sọ pé: “Ó ti láago táwọn ọmọbìnrin wa ti gbọ́dọ̀ wà lórí bẹ́ẹ̀dì wọn, tí wọ́n á sì máa retí ká wá paná, kí wọ́n lè sùn. Àkókò yẹn sì lèmi àti ọkọ mi máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa, tá a sì máa gbádùn ara wa.”

Táwọn tọkọtaya bá ti jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ pé aago báyìí ni wọ́n gbọ́dọ̀ lọ sùn, wọ́n á máa ráyè gbọ́ tara wọn, ìyẹn á sì tún jẹ́ kí wọ́n ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti “má ṣe ro ara [wọn] ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.” (Róòmù 12:3) Nígbà tó bá yá, àwọn ọmọ tí wọ́n ti tọ́ láti máa sùn lákòókò táwọn òbí wọn fẹ́ máa rí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ṣe pàtàkì nínú ìdílé, àwọn nìkan kọ́ làwọn ṣe pàtàkì, wọ́n á sì tún wá lóye pé àwọn làwọn gbọ́dọ̀ máa mú ara àwọn bá àwọn ìlànà ìdílé mu, àwọn ò gbọ́dọ̀ máa retí pé káwọn ìlànà ìdílé máa yí pa dà nítorí tiwọn.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ: Ṣètò aago tó o fẹ́ káwọn ọmọ ẹ máa lọ sún, kó o sì rí i pé wọ́n ń sùn lákòókò yẹn. Tí ọ̀kan nínú wọn ò bá tètè sùn bóyá torí pé òùngbẹ ń gbẹ ẹ́, ẹ lè máa gbà á láyè lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, ẹ máà jẹ́ kọ́mọ yín yí aago tẹ́ ẹ fẹ́ kó máa sùn pa dà mọ́ yín lọ́wọ́, nípa wíwá àwáwí pé òun fẹ́ ṣèyí lónìí ṣèyẹn lọ́la. Tí ọmọ yín bá bẹ̀ yín pé kẹ́ ẹ gba òun láyè láti sùn ní ìṣẹ́jú márùn-ún lẹ́yìn aago tẹ́ ẹ ti fún un, ẹ ṣètò kí àláàmù yín dún nísẹ̀ẹ́jú márùn-ún géérégé. Tí àláàmù bá sì ti dún, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni kẹ́ ẹ ní kó lọ sùn. Ẹ jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni [yín] túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni [àti] Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.”—Mátíù 5:37.

Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Káwọn Ọmọ Yín Ráàárín Yín

Òwe ọlọ́gbọ́n kan sọ pé: “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 1:8) Ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ ni pé kò sóhun tó burú nínú kí bàbá àti ìyá pàṣẹ ohun táwọn ọmọ wọn tó wà lábẹ́ òrùlé wọn gbọ́dọ̀ ṣe. Bó ti wù ó rí, àwọn tọkọtaya tí ìwà àwọn òbí tó tọ́ wọn dàgbà ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra ṣì máa ń jiyàn lórí bó ṣe yẹ kí wọ́n tọ́ àwọn ọmọ wọn àtàwọn òfin tó yẹ kí wọ́n ṣe lórí àwọn ọ̀ràn kan. Kí làwọn òbí lè ṣe láti yanjú ìṣòro yìí?

Fẹ́mi, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Mo ronú pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn òbí má máa jiyàn níṣojú àwọn ọmọ wọn kí wọ́n má bàa ráàárín wọn.” Àmọ́, òun náà gbà pé kò rọrùn láti ṣe, torí lọ́pọ̀ ìgbà ọ̀rọ̀ ẹnu dùn ún ròfọ́ ló máa ń já sí. Fẹ́mi sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tètè máa ń yé àwọn ọmọ. Kódà, láwọn ìgbà tá ò jiyàn pàápàá, ọmọbìnrin wa máa ń mọ̀ pé nǹkan kan ń ṣẹlẹ̀ láàárín wa tó bá ṣáà ti rí bá a ṣe ń ṣe síra wa.”

Kí ni Fẹ́mi àti Kẹ́mi ṣe láti yanjú ìṣòro yìí? Kẹ́mi sọ pé: “Tínú mi ò bá dùn sí bí baálé mi ṣe bá ọmọbìnrin wa wí, mo máa ń ní sùúrù kọ́mọ náà rìn jìnnà kí n tó sọ tinú mi. Mi ò fẹ́ kó máa ronú pé òun lè ráàárín wa. Tó bá sì wá mọ̀ pé èmi àti bàbá òun ò fohùn ṣọ̀kan lórí ọ̀ràn kan, ohun tí mo máa ń sọ fún un ni pé, gbogbo wa nínú ìdílé la gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìdarí Jèhófà àti pé tọkàntọkàn ni mo fi máa ń fara mọ́ ìpinnu bàbá ẹ̀, bó ṣe yẹ kóun náà máa fara mọ́ ìpinnu àwa òbí ẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 6:1-3) Fẹ́mi sọ pé: “Tá a bá wà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, èmi ni mo sábà máa ń bá àwọn ọmọbìnrin wa wí. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé Kẹ́mi lọ̀rọ̀ náà yé dáadáa, mo máa ń jẹ́ kó sọ ohun tá a máa ṣe láti bá ọmọ náà wí, màá sì wá tì í lẹ́yìn. Tí mi ò bá tiẹ̀ fara mọ́ ohun tó ṣe, nígbà tó bá ku àwa nìkan ni mo máa ń sọ̀yẹn fún un.”

Káwọn ọmọ yín má bàa máa rí yín fín, kí lẹ lè ṣe tẹ́ ò fi ní jẹ́ kọ́rọ̀ títọ́ àwọn ọmọ yín da àárín yín rú?

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ: Ẹ wá àkókò pàtó kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tẹ́ ẹ máa máa jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ bẹ́ ẹ ṣe fẹ́ máa tọ́ àwọn ọmọ yín, kẹ́yin méjèèjì sì gbìyànjú láti sọ tinú yín láìfi ohunkóhun pa mọ́. Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti lóye ọkọ tàbí aya ẹ, kó o sì gbìyànjú láti gba tiẹ̀ rò, kó o máa rántí pé òun náà láṣẹ lórí àwọn ọmọ yín.

Ẹ Ṣera Yín Lọ́kan Gẹ́gẹ́ Bí Òbí

Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ tó ń tánni lókun lọ̀rọ̀ ọmọ títọ́. Nígbà míì, ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́ lè kààyàn láyà. Àmọ́, kẹ́ ẹ tó ṣẹ́jú pẹ́, àwọn ọmọ yín ti filé sílẹ̀, ìyẹn á sì wá jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ ráyè gbọ́ tara yín. Ṣé ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́ máa jẹ́ kẹ́ ẹ ṣera yín lọ́kan ni, àbí ó máa da àárín yín rú? Ìyẹn máa sinmi lórí bẹ́ ẹ bá ṣe fi ìlànà tó wà nínú Oníwàásù 4:9, 10 ṣèwà hù tó, ó ní: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan, nítorí pé wọ́n ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́ àṣekára wọn. Nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.”

Táwọn òbí bá fìmọ̀ ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́, ó dájú pé wọ́n máa ṣàṣeyọrí. Bólú tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, sọ bọ́rọ̀ náà ṣe máa ń rí lára ẹ̀, ó ní: “Mo mọ̀ pé ọkọ mi láwọn ànímọ́ rere tó pọ̀ gan-an, àmọ́ tó bá dọ̀rọ̀ ká jọ tọ́mọ, ọ̀pọ̀ ànímọ́ rere tí mi ò mọ̀ pó ní ni mo máa ń rí. Bó ṣe ń tọ́ àwọn ọmọbìnrin wa, tó sì fi hàn pé òun fẹ́ràn wọn ti jẹ́ kí ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tí mo ní fún un pọ̀ sí i.” Ohun tí Fẹ́mi sọ nípa Kẹ́mi rèé: “Bí mo ṣe ń rí i pé ìyàwó mi ti ń fọwọ́ tó ṣe kókó mú ọ̀ràn bíbójú tó àwọn ọmọ wa ti jẹ́ kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”

Tó o bá ń wá àyè láti gbọ́ tọkọ tàbí tìyàwó ẹ, tẹ́ ẹ sì jọ ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa rí i pé ayọ̀ yín á túbọ̀ máa pọ̀ sí i báwọn ọmọ yín ṣe ń dàgbà. Àpẹẹrẹ dáadáa wo lẹ lè fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ yín?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.

BI ARA Ẹ PÉ . . .

▪ Wákàtí mélòó ni mo fi máa ń wà pẹ̀lú ọkọ tàbí ìyàwó mi lọ́sẹ̀ láìsí àwọn ọmọ wa nítòsí?

▪ Kí ni mo máa ń ṣe láti fi hàn pé mo wà lẹ́yìn ọkọ tàbí ìyàwó mi nígbà tó bá ń bá àwọn ọmọ wa wí?