Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdí Tí Àwọn Èèyàn Fi Fẹ́ràn Dọ́káàsì

Ìdí Tí Àwọn Èèyàn Fi Fẹ́ràn Dọ́káàsì

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Ìdí Tí Àwọn Èèyàn Fi Fẹ́ràn Dọ́káàsì

GBOGBO wa la fẹ́ kí àwọn èèyàn fẹ́ràn wa. Ṣé èrò tìrẹ náà nìyẹn? * Bíbélì sọ nípa Dọ́káàsì pé àwọn èèyàn fẹ́ràn rẹ̀ gan-an.

Ìlú Jópà ni Dọ́káàsì ń gbé, ìlú yìí sún mọ́ Òkun Mẹditaréníà. Nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56] ni Jerúsálẹ́mù fi jìn sí Jópà. Dọ́káàsì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.

Kí lo rò pé ó mú kí wọ́n fẹ́ràn Dọ́káàsì gan-an tó bẹ́ẹ̀?— Bíbélì sọ pé ó ṣe ohun rere tó pọ̀, ó sì ń fún àwọn èèyàn lẹ́bùn. Ẹ̀rí fi hàn pé ó máa ń ṣe aṣọ tó dáa fún àwọn opó, ìyẹn àwọn tí ọkọ wọn ti kú. Bíi ti Jésù, obìnrin yìí tún ń sọ nípa Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn.

Ǹjẹ́ o mọ ohun búburú tó wá ṣẹlẹ̀ sí Dọ́káàsì?— Àìsàn ṣe é, ó sì kú. Inú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ bà jẹ́ gan-an. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n rán àwọn èèyàn kan lọ sí ibi tí àpọ́sítélì Pétérù wà, ó jìnnà tó nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rìndínlógún [16]. Àwọn èèyàn náà sọ fún Pétérù pé kó wá kíákíá. Nígbà tí Pétérù dé, ó lọ sí òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì níbi tí Dọ́káàsì wà. Àwọn obìnrin tó wà níbẹ̀ ń sunkún, wọ́n ń fi aṣọ tí Dọ́káàsì ṣe fún wọn han Pétérù.

Pétérù sọ pé kí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ jáde. Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rí, àmọ́ kò sí ẹnì kankan lára wọn tó tíì jí òkú dìde. Kí lo rò pé Pétérù máa ṣe?

Pétérù kúnlẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú náà, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, ó ní kí Dọ́káàsì dìde. Dọ́káàsì sì dìde! Pétérù na ọwọ́, ó sì fà á dìde. Lẹ́yìn náà, ó pe àwọn òpó yẹn àtàwọn èèyàn yòókù, ó sì fi obìnrin náà hàn wọ́n. Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí inú wọn ṣe dùn tó?

Jẹ́ ká wá ronú nípa ohun tí o lè kọ́ nínu ìtàn yìí, ìyẹn nípa bí Dọ́káàsì ṣe jíǹde. Ohun kan tó fi kọ́ wa ni pé, bí o bá ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ wọn ló máa fẹ́ràn rẹ. Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, Ọlọ́run á rántí rẹ, á sì fẹ́ràn rẹ. Kò ní gbàgbé ohun rere tó o ṣe fún àwọn èèyàn. Yóò sì fi ìyè àìnípẹ̀kun pẹ̀lú ayọ̀ san èrè fún ọ nínú ayé tuntun, níbi tí òdodo yóò máa gbé.

Kà á nínú bíbélì rẹ

Ìṣe 9:36-43

Ìṣípayá 21:3-5

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ èrò rẹ̀.