Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Géhásì Fi Ojúkòkòrò Ba Ayé Ara Rẹ̀ Jẹ́

Géhásì Fi Ojúkòkòrò Ba Ayé Ara Rẹ̀ Jẹ́

ǸJẸ́ nǹkan kan ti wà tó wù ọ́ gan-an rí? * Àwọn èèyàn yòókù náà máa ń rí ohun tó wù wọ́n gan-an nígbà míì. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ó yẹ kí o parọ́ láti lè rí ohun tó wù ọ́ yẹn gbà?— Rárá, o kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ olójúkòkòrò. Jẹ́ kí a wo bí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Géhásì ṣe fi ojúkòkòrò ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. Géhásì jẹ́ ìránṣẹ́ Èlíṣà, wòlíì Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́.

Ayé àtijọ́ ni Èlíṣà àti Géhásì gbé láyé. Ó jẹ́ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù Ọmọ Ọlọ́run sórí ilẹ̀ ayé. Jèhófà lo Èlíṣà láti ṣe àwọn nǹkan tó yani lẹ́nu gan-an, èyí tí a máa ń pè ní iṣẹ́ ìyanu! Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ fún wa nípa ọkùnrin pàtàkì kan nínú àwọn ọmọ ogun Síríà, tó ní àrùn burúkú kan, ìyẹn àrùn ẹ̀tẹ̀. Kò rí ìwòsàn lọ́dọ̀ ẹnì kankan, àfi ìgbà tó dé ọ̀dọ̀ Èlíṣà.

Tí Ọlọ́run bá lo Èlíṣà láti wo àwọn èèyàn sàn, Èlíṣà kì í gba owó lọ́wọ́ wọn. Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀?— Ìdí ni pé Èlíṣà mọ̀ pé kì í ṣe agbára òun ni òun fi ń ṣe ìwòsàn, Jèhófà ló ń mú kí àwọn iṣẹ́ ìyanu náà ṣeé ṣe. Nígbà tí ara Náámánì yá, inú rẹ̀ dùn gan-an ó sì fẹ́ fún Èlíṣà ní àwọn ẹ̀bùn tó jẹ́ wúrà, fàdákà àti àwọn aṣọ tí ó dára. Èlíṣà kọ̀, kò gba àwọn ẹ̀bùn yìí, àmọ́ àwọn ẹ̀bùn náà wu Géhásì gan-an.

Lẹ́yìn tí Náámánì ti lọ, Géhásì sáré tẹ̀ lé e láì sọ fún Èlíṣà. Nígbà tí ó bá Náámánì, ǹjẹ́ o mọ ohun tí ó sọ fún un?— Géhásì sọ fún Náámánì pé: ‘Èlíṣà rán mi sí ọ, ó ní àwọn àlejò méjì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ́dọ̀ òun láìpẹ́ yìí. Nítorí náà kí o fún òun ní ìpààrọ̀ ẹ̀wù méjì kí òun lè fún àwọn ọkùnrin tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé náà.’

Àmọ́ irọ́ ló ń pa o! Géhásì fúnra rẹ̀ ló ronú gbogbo ìtàn irọ́ yẹn tó sì lọ sọ ọ́ fún Náámánì. Ó parọ́, torí pé ó fẹ́ gba àwọn aṣọ tí Náámánì fẹ́ kó fún Èlíṣà tẹ́lẹ̀. Náámánì kò kúkú mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Tayọ̀tayọ̀ ló fi kó àwọn ẹ̀bùn náà fún Géhásì. Kódà àwọn nǹkan tí Náámánì kó fún Géhásì ju ohun tí ó béèrè lọ. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí?

Nígbà tí Géhásì pa dà dé ilé, Èlíṣà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Ibo ni o lọ?’

Géhásì sọ pé: ‘Mi ò lọ sí ibì kankan.’ Àmọ́, Jèhófà ti jẹ́ kí Èlíṣà mọ ohun tí Géhásì ṣe. Èlíṣà wá sọ fún un pé: ‘Kì í ṣe àkókò nìyí láti gba owó àti aṣọ!’

Géhásì lọ gba owó àti àwọn aṣọ tí wọn kò sọ pé kó gbà. Torí náà Ọlọ́run mú kí àrùn ẹ̀tẹ̀ tó wà lára Náámánì tẹ́lẹ̀ wá sí ara Géhásì. Ẹ̀kọ́ wo ni o rò pé ìtàn yìí kọ́ wa?— Ohun tó kọ́ wa ni pé, a kò gbọ́dọ̀ máa sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́.

Kí nìdí tí Géhásì fi sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ yẹn?— Ìdí ni pé ó jẹ́ olójúkòkòrò tàbí oníwọra. Ó wù ú láti ní àwọn nǹkan tí kì í ṣe tirẹ̀, ó wá pa irọ́ kí ó lè gba àwọn nǹkan yẹn. Nítorí ohun tí Géhásì ṣe yìí, àrùn ẹ̀tẹ̀ burúkú yẹn kò kúrò ní ara rẹ̀ títí tó fi kú.

Ṣé o rí i, ohun mìíràn wà tó tún ṣẹlẹ̀ sí Géhásì, èyí tó burú ju àrùn ẹ̀tẹ̀ tó wá sára rẹ̀ lọ. Ǹjẹ́ o mọ ohun náà?— Ohun náà ni pé Ọlọ́run bínú sí i, kò sì fẹ́ràn rẹ̀ mọ́. Torí náà, a kò gbọ́dọ̀ máa ṣe ohunkóhun tí kò ní jẹ́ kí Ọlọ́run fẹ́ràn wa mọ́! Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí a jẹ́ onínúure, ká sì máa fún àwọn ẹlòmíràn lára àwọn ohun tí a bá ní.

Kà á nínú Bíbélì rẹ

^ Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.