Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2017

Kà nípa ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà àti kárí ayé.

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Wọ́n fẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé mọ̀ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn sì mọrírì wọn.

A Fún Iṣẹ́ Ìwàásù Kárí Ayé Láfiyèsí

Báwo làwọn tó ti wà ní Bẹ́tẹ́lì tẹ́lẹ̀ ṣe fi àwọn nǹkan kan kọ́ra nígbà tí wọ́n dé pápá?

“Ẹ̀yin Ni Aládùúgbò Tó Dáa Jù Lọ”

Ní May 7 àti 8, ọdún 2016, tó bọ́ sópin ọ̀sẹ̀, a ṣí ọ́fí ìsì wa tó wà ní Brooklyn sílẹ̀ káwọn èèyàn lè wá wo ìpàtẹ tó dá lórí ìtàn Bíbélì, èyí sì mú káwọn aládùúgbò gbọ́ ìwàásù.

Ìpàdé Tuntun fún Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni

Ní January 2016, àyípadà bá ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ táwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe kárí ayé.

Ètò Orí Tẹlifíṣọ̀n JW Ń ‘Fún Wa Lókun, Ó sì Ń Mára Tù Wá!’

Ọdún 2014 ni Tẹlifíṣọ̀n JW bẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn sì ti ń wò ó ní èdè tó ju àádọ́rùn-ún lọ báyìí. Báwo ló ṣe rí lára àwọn tó ń wò ó?

Ìyàsímímọ́ Ẹ̀ka Ọ́fí ìsì

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Àméníà àti Kyrgyzstan dùn gan-an láti wà níbi ìyàsímímọ́ àwọn ọ́fí ìsì tuntun.

Ìròyìn Nípa Àwọn Ẹjọ́ Lọ́dún 2016

Ìṣòro wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kojú lórí ọ̀rọ̀ ẹjọ́ lọ́dún 2016?

Ìròyìn—Nípa Àwọn Ará Wa

Ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà, Belize, Bùrúńdì, Kóńgò (Kinshasa), Jámánì, Ítálì, Nepal, Papua New Guinea àti Uganda.

Áfíríkà

Ka ìrírí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórílẹ̀-èdè Gánà, Gíní-Bìsaù, Làìbéríà, Màláwì, Tógò àti Siria Lóònù.

Àwọn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà

Àwọn ìrírí láti orílẹ̀-èdè Brazil, Haiti, Mẹ́síkò, Amẹ́ríkà àti Fẹnẹsúélà.

Éṣíà àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn

Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Hong Kong, Mòǹgólíà, Philippines àti Siri Láńkà.

Yúróòpù

Ka ìrírí àwọn èèyàn ní orílẹ̀-èdè Azerbaijan, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Bọ̀géríà, Jọ́jíà, Denmark, Hungary, Nọ́wè àti Ukraine.

Oceania

Àwọn ìrírí àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, Guam, New Caledonia, Papua New Guinea àti Timor-Leste.

Àlàyé Ṣókí Nípa Jọ́jíà

Wo àlàyé ṣókí nípa bí ilẹ̀ Jọ́jíà ṣe rí, àwọn èèyàn ibẹ̀, àṣà wọn àti èdè tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè yìí ní Òkun Dúdú.

Àwọn Tó Ń Wá Òtítọ́ Láyé Ìgbà Kan

Àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ níbòmí ì, tí wọ́n sì mọyì ohun tí wọ́n kọ́ wá sí Jọ́jíà, wọ́n sì tan ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run kálẹ̀.

Ìpàdé Mú Kí Ìgbàgbọ́ Gbogbo Wọn Lágbára

Báwo ni ìpàdé Kristẹni àtàwọn ìtẹ̀jáde lédè Jọ́jíà ṣe pilẹ̀ ìtẹ̀síwájú tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú?

Mo Fẹ́ Káyé Mi Nítumọ̀

Nígbà tí Davit Samkharadze sin ìjọba tán lẹ́nu iṣẹ́ ológun, ó gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ káyé oun nítumọ̀. Ọjọ́ kejì ló bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé.

Mo Bẹ Jèhófà Pé Kó Tọ́ Mi Sọ́nà

Kí Tamazi Biblaia tó kó lọ sílùú mí ì, ó bẹ Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́, Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́.

‘Ohun Gbogbo Ṣeé Ṣe Lọ́dọ̀ Ọlọ́run’

Nígbà tí Natela Grigoriadis ń ran àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiẹ̀ lọ́wọ́ láti tẹ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì jáde, ó kojú ohun kan tó dà bíi pé “kò ṣeé ṣe.”

Bíbélì Lédè Jọ́jíà

Àárín ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún tàbí ṣáájú ìgbà yẹn ni àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n kọ lédè Jọ́jíà ti wà.

“Ọlọ́run Ń Mú Kí Ó Máa Dàgbà.”—1 Kọ́r. 3:6.

Lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè Jọ́jíà gbòmìnira, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i lọ́nà tó kàmàmà.

Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Onífẹ̀ẹ́ Ṣètò Ìdánilẹ́kọ̀ọ́

Lẹ́yìn tí ìjọba Kọ́múní ìsì kógbá wọlé, báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣètò àwọn ìjọ, ìpàdé, àpéjọ àti iṣẹ́ ìtúmọ̀ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì?

Ọkọ Mi Ò Ṣíwọ́ Kíka Bíbélì!

Ó yá Badri Kopaliani lára gan-an láti ká Bíbélì rẹ̀ tuntun débi pé ó gbàyè ọjọ́ díẹ̀ níbi iṣẹ́ kó lè kà á tán.

Ibo Lẹ Wà Látọjọ́ Yìí?

Kò pé ọdún kan lẹ́yìn tí Artur Gerekhelia ṣèrìbọmi tó fi kó lọ síbi tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i.

Mò Ń Wò Ó Pé Ayé Mi Ti Dáa

Èèyàn pàtàkì ni Madona Kankia nínú Ẹgbẹ́ Ìjọba Kọ́múní ìsì tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó pinnu pé òun fẹ́ fi ayé ohun ṣe nǹkan mí ì.

Ìfẹ́ Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Yẹ̀

Nígbà ogun tó wáyé ní Abkhazia, Igor Ochigava àti Gizo Narmania ran àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tiwọn àtàwọn mí ì lọ́wọ́, wọ́n pèsè oúnjẹ fún wọn, wọ́n sì ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kára tù wọ́n.

Mo Fojú Ara Mi Rí Ohun tí Bíbélì Sọ!

Torí pé Pepo Devidze ń ṣiyèméjì nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ṣe ohun tí ìyá rẹ̀ sọ fún un, pé: “Lọ féti ara ẹ gbọ́ ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni.”

Wọ́n Rí Ìbùkún ‘ní Àsìkò tí Ó Rọgbọ àti ní Àsìkò tí Ó Kún fún Ìdààmú.’—2 Tím. 4:2.

Àwọn akéde yára pọ̀ sí i láwọn ọdún yìí, àmọ́ inúnibíni bẹ̀rẹ̀ láti ibi tí wọn ò retí.

Wọ́n Ń Sin Jèhófà, Bí Ọ̀tá Tiẹ̀ Ń Gbógun

Báwo ni ìwà ipá táwọn èèyàn ń hù sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Jọ́jíà ṣe rí lára àwọn aráàlú?

“Èyí Ni Ohun Ìní Àjogúnbá Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà.”—Aísá. 54:17.

Àwọn akéde tó ṣe gudugudu méje yàyà mẹ́fà lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run rí ìbùkún Jèhófà.

Wọ́n Rántí Ẹlẹ́dàá Wọn Atóbilọ́lá

Ìdá mẹ́ta àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà ní Jọ́jíà ló jẹ́ ọmọ ọdún 25 tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀.

Àwọn Tó ŃSọÈdè Kurdish Gba Ẹ̀kọ́ Òtítọ́

Inú àwọn tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run dùn láti gbọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ ní èdè wọn.

Ìfẹ́ Máa Ń Borí Ìdènà

Àwọn ìyá àgbà méjì mọ bí ìfẹ́ ará ṣe ń rí lára.

Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn—1917

Àsìkò ìdánwò àti ìyọ́mọ́ ni ọdún 1917 jẹ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ láìka ìṣòro tó wáyé sí, àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ ń kọ́wọ́ ti Ìjọba Ọlọ́run.

Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 2016

Ìròyìn ọdọọdún yìí jẹ́ ká rí kúlẹ̀kúlẹ̀ iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe kárí ayé lọ́dún 2016.

Ìròyìn Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn 2016 ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kárí Ayé

Ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ iye wa, iye ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, iye orílẹ̀-èdè tá a ti ń wàásù, iye àwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.