Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JỌ́JÍÀ

Àwọn Tó ŃSọÈdè Kurdish Gba Ẹ̀kọ́ Òtítọ́

Àwọn Tó ŃSọÈdè Kurdish Gba Ẹ̀kọ́ Òtítọ́

GULIZAR sọ pé, “Mi ò lè ṣe kí n máà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà bó ṣe jẹ́ kí n mọ òun lédè àbínibí mi.”

Ọdún mẹ́jọ ni Gulizar fi dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ìgbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé tí wọ́n ń ṣe lédè ìbílẹ̀ rẹ̀, ìyẹn èdè Kurdish, ló tó ṣèrìbọmi. Ó wà lára ọ̀pọ̀ àwọn ará Kurd tó gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ ní Jọ́jíà lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Àmọ́ àwọn wo là ń pè ní Kurd?

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni àwọn tó ń sọ èdè Kurdish ti ń gbé ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrun. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé àtọmọdọ́mọ àwọn ará Mídíà ayé àtijọ́ tí Bíbélì sọ ni wọ́n. (2 Ọba 18:11; Ìṣe 2:9) Ọ̀kan lára èdè àwọn ará Ìráànì ni wọ́n ń sọ.

Lónìí, oríṣiriṣi orílẹ̀-èdè ni ọ̀pọ̀ mílíọ́nù àwọn ará Kurd ń gbé, títí kan Àméníà, Ìráànì, Ìráàkì, Síríà àti Tọ́kì. Nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan [20,000] àwọn ará Kurd ló wà ní Jọ́jíà. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fọ́rọ̀ Ọlọ́run.

Ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] akéde ló ń sọ èdè Kurdish ní Jọ́jíà báyìí, ìjọ mẹ́ta ni wọ́n sì ti ń sọ èdè náà. Lọ́dún 2014, inú gbogbo èèyàn ló ń dùn nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe àpéjọ àgbègbè léde Kurdish nílùú Tbilisi, àwọn èèyàn sì wá láti orílẹ̀-èdè Àméníà, Jámánì, Tọ́kì àti Ukraine.