Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ààwẹ̀?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ààwẹ̀?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, tí àwọn èèyàn bá gba ààwẹ̀ lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, inú Ọlọ́run máa dùn sírú ààwẹ̀ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ tí wọn ò bá ṣe é lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, inú rẹ̀ ò ní dùn sí i. Bíbélì ò pàṣẹ fún wa lónìí pé ká gbààwẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé ká má gba ààwẹ̀ tá a bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀.

Ìdí táwọn èèyàn fi ń gbààwẹ̀ láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?

  •   Nígbà tí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n gbààwẹ̀ kí wọ́n bàa lè fi han Ọlọ́run pé lóòótọ́ làwọn nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. (Ẹ́sírà 8:21-23) Pọ́ọ̀lù àti Bánábà náà gbààwẹ̀ láwọn ìgbà kan tí wọ́n fẹ́ yan àwọn alàgbà sí ìjọ.​—Ìṣe 14:23.

  •   Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi, ó gbààwẹ̀ fún ogójì [40] ọjọ́, kó bàa lè gbara dì fún bó ṣe máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀.​—Lúùkù 4:1, 2.

  •   Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fi hàn pé àwọn ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀. Ọlọ́run gbẹnu wòlíì Jóẹ́lì sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ aláìṣòdodo pé: “Ẹ padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà yín, àti pẹ̀lú ààwẹ̀ gbígbà àti pẹ̀lú ẹkún sísun àti pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún.”​—Jóẹ́lì 2:12-15.

  •   Ní Ọjọ́ Ètùtù. Lára Òfin tí Ọlórun fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni pé kí wọ́n máa gba ààwẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù. a (Léfítíkù 16:29-31) Ààwẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an lọ́jọ́ yẹn torí ìyẹn ló máa rán wọn létí pé aláìpé ni wọ́n àti pé wọ́n nílò ìdáríjì Ọlọ́run.

Àwọn nǹkan tí kò tọ̀nà tó bá dọ̀rọ̀ ààwẹ̀

  •   Ojú ayé. Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ìpinnu ara ẹni ni ààwẹ̀, ààrín ẹni yẹn àti Ọlọ́run ló sì yẹ kó wà, kò yẹ kí ẹtí kẹta gbọ́.​—Mátíù 6:16-18.

  •   Ààwẹ̀ máa fi hàn pé a jẹ́ olódodo. Ààwẹ̀ ò lè mú kí ìwà wa tàbí ìjọsìn wa sàn ju tàwọn ẹlòmíì lọ.​—Lúùkù 18:9-14.

  •   Láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn mọ̀ọ́mọ̀ dá. (Aísáyà 58:3, 4) Ìgbà tẹ́nì kan bá tẹ̀lé ìlànà Ọlọ́run tó sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ tó dá tọkàntọkàn nìkan ni Ọlórun máa tẹ́wọ́ gba ààwẹ̀ tó gbà.

  •   Bá a ṣe máa ń ṣe é nínú ẹ̀sìn wa nìyẹn. (Aísáyà 58:5-7) Ká sọ pé ọmọ kan ṣe nǹkan kan fún òbí rẹ̀ torí pé ó di dandan kó ṣe nǹkan yẹn, ó dájú pé inú òbí yẹn ò ní dùn torí pé kò wá látọkàn ọmọ yẹn láti ṣe é. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí lójú Ọlọ́run.

Ṣé dandan ni káwọn Kristẹni gbààwẹ̀?

 Rárá. Lóòótọ́ Ọlórun pàṣẹ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbààwẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù, àmọ́ àṣẹ yẹn ti kásẹ̀ nílẹ̀ nígbà tí Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ètùtù tó ga jù lọ fún àwọn tó bá ronúpìwàdà. (Hébérù 9:24-26; 1 Pétérù 3:18) Yàtọ̀ síyẹn inú Òfin Mósè ni Ọjọ́ Ètùtù wà, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwa Krisẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè mọ́. (Róòmù 10:4; Kólósè 2:13, 14) Torí náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá òun máa gbààwẹ̀.​—Róòmù 14:1-4.

 Àwọn Kristẹni mọ̀ pé orí ààwẹ̀ kọ́ ni ìjọsìn wọn dá lé. Bíbélì ò sọ pé tá a bá gbààwẹ̀ la má tó láyọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, bíi ti Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” ìdùnnú la fi ń dá ẹ̀sìn Krisẹni tòótọ́ mọ̀.​—1 Tímótì 1:11; Oníwàásù 3:12, 13; Gálátíà 5:22.

Àwọn èrò tí kò tọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ààwẹ̀

 Èrò tí kò tọ́: Àpọ́sítẹ́lì Pọ́ọ̀lù sọ pé káwọn Kristẹni tó ṣe ìgbéyàwó gbààwẹ̀.​—1 Kọ́ríńtì 7:5, Bíbélì Mímọ́.

 Òótó ọ̀rọ̀: Nínú àwọn Bíbélì tí wọ́n fọwọ́ kọ tó lọ́jọ́ lórí jù, kò sí ààwẹ̀ nínú 1 Kọ́ríńtì 7:5. b Ó ṣe kedere pé àwọn tó da Bíbélì kọ ló fi ààwẹ̀ kún ẹsẹ yìí àtàwọn ẹsẹ míì, irú bíi Mátíù 17:21; Máàkù 9:29 àti Ìṣe 10:30. Nínú ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì tòde òní, kò sí ààwẹ̀ láwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn.

 Ẹ̀rò tí kò tọ̀nà: Torí Jésù gbààwẹ̀ fún ogójì [40] ọjọ́ lẹ́yìn tó ṣe ìrìbọmi, àwọn Kristẹnì náa gbọ́dọ̀ máa gbààwẹ̀.

 Òótó ọ̀rọ̀: Jésù ò pàṣẹ pé ká ṣe bẹ́ẹ̀, bákan náà kò sí ẹ̀rí kankan nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni ṣe bẹ́ẹ̀. c

 Èrò tí kò tọ́: Àwọn Kristẹnì gbọ́dọ̀ gbààwẹ̀ tí wọ́n bá ń rántí ikú Jésù.

 Òótó ọ̀rọ̀: Jésù ò sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun máa gba ààwẹ̀ tí wọ́n bá ń rántí ikú òun. (Lúùkù 22:14-18) Lóòótọ́ Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa gba ààwẹ̀ tí òun bá kú, àmọ́ kì í ṣe pé o ń pàṣẹ fún wọn, ńṣe ló kàn ń sọ nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn tí òun bá kú. (Mátíù 9:15) Bíbélì sọ fáwọn Kristẹni pé tí ebi bá ń pa wọ́n, kí wọ́n jẹun wá láti ilé kí wọ́n tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.​—1 Kọ́ríńtì 11:33, 34.

a Ọlọ́run sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: Ní Ọjọ́ Ètùtù “Kí ẹ̀yin kí ó pọ́n ọkàn yín lójú.” (Léfítíkù 16:29, 31;Bíbélì Mímọ́) Ohun tọ́rọ̀ yìí túmọ̀ sí ni pé kí wọ́n gba ààwẹ̀. (Aísáyà 58:3) Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀ sọ ọ́ báyìí pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ gbààwẹ̀.”

b Wo ìwé A Textual Commentary on the Greek New Testament, látọwọ́ Bruce M. Metzger, Ẹ̀dà Kẹta, ojú ìwé 554.

c Lórí ọ̀rọ̀ ààwẹ̀ ológójì [40] ọjọ́ táwọn èèyàn máa ń pè ní Lẹ́ńtì, ìwé New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Ní ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́ta àkọ́kọ́, ààwẹ̀ tí wọ́n máa ń gbà kí wọ́n tó ṣe ọdún àjíǹde [Easter] kì í kọjá ọ̀sẹ̀ kan, ìgbà míì kì í ju ọjọ́ méjì lọ. . . . Nínú òfin karùn-ún ti Council of Nicaea (325), la ti kọ́kọ́ gbọ́ ogójì [40] ọjọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan ò gbà pé ọ̀rọ̀ Lẹ́ńtì ni wọ́n ń sọ níbẹ̀.”​—Ẹ̀dà Kejì, Ìdìpọ̀ 8, ojú ìwé 468.