Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Ọlọ́run Máa Dárí Jì Mí?

Ṣé Ọlọ́run Máa Dárí Jì Mí?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́ tó o bá ṣe àwọn ohun tó yẹ. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “ṣe tán láti darí jini” àti pé “yóò dárí jì lọ́nà títóbi.” (Nehemáyà 9:17; Sáàmù 86:5; Aísáyà 55:7) Tí Ọlọ́run bá dárí jini, ó máa ń dárí jini pátápátá. Ọlọ́run ti ‘pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́’ tàbí nù ún kúrò. (Ìṣe 3:19) Ọlọ́run tún máa ń dárí jini délèdélẹ̀, torí ó sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́.” (Jeremáyà 31:34) Tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, kì í fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà bi wá mọ́ tàbí kó máa fìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà jẹ wá títí lọ.

 Àmọ́, kì í ṣe torí pé Ọlọ́run ò mọ ohun tó yẹ ló ṣe ń dárí jini tàbí torí pé ojú àánú rẹ̀ pọ̀ lápọ̀jù. Àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ kì í yí pa dà. Torí náà, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tí kì í dárí rẹ̀ jini.​—Jóṣúà 24:19, 20.

Àwọn ohun tó o lè ṣe kí Ọlọ́run lè dárí jì ẹ́

  1. Gbà pé bó o ṣe dẹ́ṣẹ̀ yẹn ti mú kó o tẹ àwọn ìlànà Ọlọ́run lójú. Òótọ́ ni pé ohun tó o ṣe ti lè múnú bí àwọn kan, àmọ́ o ní láti mọ̀ pé Ọlọ́run lẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ tó o dá yẹn dùn jù.​—Sáàmù 51:1, 4; Ìṣe 24:16.

  2. Jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ fún Jèhófà nínú àdúrà.​—Sáàmù 32:5; 1 Jòhánù 1:9.

  3. Fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ tó o dá náà dùn ẹ́ gan-an. “Ìbànújẹ́ ní ọ̀nà ti Ọlọ́run” yìí á mú kó o ronú pìwà dà tàbí kí èrò ọkàn rẹ yí pa dà. (2 Kọ́ríńtì 7:10) Èyí ní nínú pé kó o kábàámọ̀ ohun tó o ṣe tó wá yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀.​—Mátíù 5:27, 28.

  4. Jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ yẹn, ìyẹn ni pé kó o “yí padà.” (Ìṣe 3:19) Ó lè gba pé kó o yẹra fún ṣíṣe àṣìṣe kan náà tàbí kó o yẹra fún dídá ẹ̀ṣẹ̀ kan náà léraléra. Ó tún lè gba pé kó o yí bó o ṣe ń ronú àti bó o ṣe ń ṣe nǹkan pa dà.​—Éfésù 4:23, 24.

  5. Gbé ìgbésẹ̀ láti ṣàtúnṣe ohun buburú tí ẹ̀ṣẹ̀ tó o dá ti fà. (Mátíù 5:23, 24; 2 Kọ́ríńtì 7:11) Tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ tó o dá ṣe àkóbá fún, kó o sì ṣe àtúnṣe tó bá yẹ dé ibi tí agbára rẹ bá gbé e dé.​—Lúùkù 19:7-​10.

  6. Gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó dárí jì ọ́ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. (Éfésù 1:7) Kí Ọlọ́run lè gbọ́ àdúrà rẹ, ìwọ náà ní láti dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ ọ́.​—Mátíù 6:14, 15.

  7. Tó bá jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì lo dá, o nílò ìrànlọ́wọ́. Sọ fún ẹnì kan tó tóótun láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, kó sì gbàdúrà fún ẹ.​—Jákọ́bù 5:14-​16.

Àwọn èrò tí kò tọ́ nípa béèyàn ṣe lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run

 “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti pọ̀ jú, mí ò lè rí ìdáríjì.”

Ọlọ́run dárí ji Dáfídì nígbà tó ṣe panṣágà to sì tún pààyàn

 Tá a bá ti ń ṣe àwọn ohun tí Ọlọ́run ní ká ṣe, tó wà nínú Bíbélì, ó máa dárí jì wá. Ìdí ni pé agbára tó ní láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá ju àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa lọ. Ó lè dárí jì wá tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, títí kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá léraléra.​—Àìsáyà 1:18.

 Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nígbà tó ṣe panṣágà tó sì tún pààyàn. (2 Sámúẹ́lì 12:7-​13) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó tiẹ̀ ka ara rẹ̀ sí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jù lọ láyé pàápàá rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (1 Tímótì 1:15, 16) Kódà àwọn Júù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí Ọlọ́run dá lẹ́bi fún bí wọ́n ṣe pa Jésù tó jẹ́ Mèsáyà rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà tí wọ́n bá ronú pìwà dà.​—Ìṣe 3:15, 19.

 “Màá rí ìdáríjì gbà tí n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún àlùfáà tàbí òjíṣẹ́ Ọlọ́run kan.”

 Kò sí èèyàn kankan tó láṣẹ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí èèyàn míì bá ṣẹ Ọlọ́run jì í. Lóòótọ́, tí ẹnì kan bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún ẹlòmíì, ó lè mú kó jáwọ́, àmọ́ Ọlọrun nìkan ló lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini.​—Éfésù 4:32; 1 Jòhánù 1:7, 9.

 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún àwọn àpọ́sítélì pé: “Bí ẹ bá dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ji ènìyàn èyíkéyìí, wọ́n wà ní èyí tí a dárí jì wọ́n; bí ẹ bá dá àwọn ti ènìyàn èyíkéyìí dúró, wọ́n wà ní dídádúró síbẹ̀”? (Jòhánù 20:23) Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ọlá àṣẹ àrà ọ̀tọ̀ kan tó máa fún àwọn àpọ́sítélì tí wọ́n bá ti gba ẹ̀mí mímọ́.​—Jòhánù 20:22.

 Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣèlérí, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni àwọn àpọ́sítélì gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ yìí. (Ìṣe 2:1-4) Àpọ́sítélì Pétérù lo ọlá àṣẹ yìí nígbà tó dájọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà Ananíà àti Sáfírà. Lọ́nà ìyanu, Pétérù mọ ọgbọ́n àrékérekè tí wọ́n ń dá, bó sì ṣe dá wọn lẹ́jọ́ lọ́nà yẹn fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá kò ní ìdáríjì.​—Ìṣe 5:1-​11.

 Ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ tí wọ́n gbà lọ́nà ìyanu yìí àtàwọn ẹ̀bùn míì bí agbára láti woni sàn àti agbára láti sọ̀rọ̀ ní ahọ́n àjèjì dópin lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì. (1 Kọ́ríńtì 13:8-​10) Torí náà, kò sí èèyàn kankan tó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí èèyàn bíi tiẹ̀ bá ṣẹ Ọlọ́run jì í.