Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Ilẹ̀ Ayé Máa Pa Run?

Ṣé Ilẹ̀ Ayé Máa Pa Run?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Rárá o, ilẹ̀ ayé ò ní pa run láé, a ò ní finá sun ún, a ò sì ní pààrọ̀ rẹ̀. Ohun tí Bíbélì kọ́ni ni pé Ọlọ́run dá ayé ká lè máa gbé ibẹ̀ títí láé.

  •   “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”​—Sáàmù 37:29.

  •   “[Ọlọ́run] fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.”​—Sáàmù 104:5.

  •   “Ilẹ̀ ayé dúró . . . fún àkókò tí ó lọ kánrin.”​—Oníwàásù 1:4.

  •   “Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀, Òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in . . . kò wulẹ̀ dá a lásán, . . . ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.”​—Aísáyà 45:18.

Ṣé àwọn èèyàn máa lè ba ayé jẹ́?

 Ọlọ́run ò ní gbà kí àwọn èèyàn fi ìdọ̀tí, ogun tàbí ohunkóhun míì ba ayé yìí jẹ́ pátápátá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Báwo ló ṣe máa ṣe é?

 Ọlọ́run máa fi Ìjọba ọ̀run tó pé láìkù síbì kan, rọ́pò àwọn ìjọba èèyàn tí ò lè dáàbò bo ayé yìí. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10) Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run ló máa jẹ́ ọba Ìjọba yẹn. (Aísáyà 9:6, 7) Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi agbára tó ní ṣiṣẹ́ ìyanu láti kápá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àdáyébá. (Máàkù 4:35-41) Torí pé Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó máa lágbara dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lórí ayé àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀. Ó máa tún ayé ṣe, tàbí ká kúkú sọ pé ó máa sọ ayé di ọ̀tun, nǹkan á wá rí bó ṣe rí nínú ọgbà Édẹ́nì nígbà yẹn.​—Mátíù 19:28; Lúùkù 23:43.

Ṣebí Bíbélì sọ pé a máa finá sun ayé yìí?

 Rárá, kò sọ bẹ́ẹ̀. Ohun tó máa ń mú káwọn kan sọ bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ṣi ohun tó wà nínú 2 Pétérù 3:7 lóye, èyí tó sọ pé: “Àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná.” Wo kókó pàtàkì méjì tó máa jẹ́ ká lóye ohun tí ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí:

  1.   Tí Bíbélì bá lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “ọ̀run,” “ilẹ̀ ayé,” àti “iná”, ó máa ń ní ju ìtumọ̀ kan lọ. Bí àpẹẹrẹ, Jẹ́nẹ́sísì 11:1 sọ pé: “Gbogbo ilẹ̀ ayé ń bá a lọ láti jẹ́ èdè kan.” Àwọn èèyàn ni “ilẹ̀ ayé” tí ibí yìí sọ ń tọ́ka sí.

  2.   Àwọn ẹsẹ tó ṣáájú 2 Pétérù 3:7 jẹ́ ká mọ ohun tí àwọn ọ̀run, ilẹ̀ ayé àti iná tí ẹsẹ keje yẹn dárúkọ túmọ̀ sí. Ẹsẹ  5 àti 6 fọ̀rọ̀ wé Ìkún-omi ìgbà ayé Nóà. Nígbà yẹn, Ọlọ́run pa ayé run, àmọ́ ilẹ̀ ayé wa yìí ò pa run. Ṣe ni Ìkún-omi náà pa àwọn èèyàn oníwà ipá run. Àwọn ni “ayé” tó pa run. (Jẹ́nẹ́sísì 6:11) Ìkún-omi náà tún pa “ọ̀run” run​—ìyẹn àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso aráyé ìgbà yẹn. Torí náà, àwọn èèyàn burúkú ló pa run, kì í ṣe ilẹ̀ ayé wa yìí. Nóà àti ìdílé rẹ̀ la ìparun ayé ìgbà yẹn já, wọ́n sì ń gbé láyé lẹ́yìn Ìkún-omi náà.​—Jẹ́nẹ́sísì 8:15-18.

 Bíi ti òjò tó rọ̀ nígbà Ìkún-omi, àwọn èèyàn burúkú tó wà nínú ayé ni ìparun, tàbí “iná” tó wà nínú 2 Pétérù 3:7 máa fòpin sí, kì í ṣe ilẹ̀ ayé wa yìí. Ọlọ́run ṣèlérí “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” nínú èyí tí “òdodo yóò . . . máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) “Ọ̀run tuntun” tàbí àkóso tuntun, ìyẹn Ìjọba Ọlọrun, ló máa ṣàkóso lórí “ayé tuntun,” tàbí àwùjọ àwọn èèyàn tuntun. Tí Ìjọba yẹn bá ti ń ṣàkóso, ayé máa di párádísè, àlàáfíà á sì jọba.​—Ìṣípayá 21:1-4.