Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ó Bìkítà fún Ẹ”

“Ó Bìkítà fún Ẹ”

Kódà tí àwọn míì bá tiẹ̀ já ẹ kulẹ̀, ẹnì kan wà tí kò ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé. Ta ni ẹni náà?

Ọba Dáfídì sọ pé: “Kódà, tí bàbá mi àti ìyá mi bá kọ̀ mí sílẹ̀, Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.”​—Sáàmù 27:10.

Jèhófà jẹ́ “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tó ń tù wá nínú nínú gbogbo àdánwò wa.”​—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

“Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.”​—1 Pétérù 5:7.

Kó o lè mọ bí Ọlọ́run ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, wo orí 12 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, ó sì wà lórí ìkànnì www.mt711.com/yo