Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀

Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀

“Nígbà tí ẹrẹ̀ ya wọ̀lú, tí àkúnya omi sì ṣẹlẹ̀, ìdààmú bá wa, ọkàn wa sì gbọgbẹ́, torí pé gbogbo ohun tá a ní ló ṣègbé.”​—Andrew, Sierra Leone.

“Lẹ́yìn tí ìjì líle wáyé, a pa dà sílé wa, àmọ́ a ò dé bá ohunkóhun. Mo kàn ń wò ni, mi ò lè sọ̀rọ̀, ńṣe ni ọmọbìnrin mi ṣubú lulẹ̀, ó sì bú sẹ́kún.”​—David, Virgin Islands.

TÍ ÀJÁLÙ bá ti bá ẹ rí, wàá mọ̀ pé ohun tí ojú àwọn tó ṣẹlẹ̀ sí máa ń rí kì í ṣe kékeré. Ìdààmú ńlá máa ń bá wọn, á máa ṣe wọ́n bíi pé wọ́n ń lálàá, àníyàn máa ń gbà wọ́n lọ́kàn, wọn kì í mọ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe, kódà àwọn míì máa ń ṣe ìrànrán lójú oorun. Nǹkan máa ń sú ọ̀pọ̀ wọn, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn sì lè mú wọn débi pé wọ́n á gbà pé kò sí ìrètí kankan fún àwọn mọ́.

Tí àjálù bá ti bá ẹ rí tó sì mú kó o pàdánù gbogbo ohun tó o ní, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ó ti tán fún ẹ. O tiẹ̀ lè máa rò pé ìgbésí ayé rẹ ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ayé rẹ ṣì máa dùn àti pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára.

Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ FINI LỌ́KÀN BALẸ̀ PÉ Ọ̀LA Ń BỌ̀ WÁ DÁRA

Oníwàásù 7:8 sọ pé: “Òpin nǹkan sàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ.” Lẹ́yìn tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó lè dà bíi pé kò sí ìrètí kankan mọ́. Àmọ́ bó o ṣe ń sapá láti mú ìgbésí ayé rẹ pa dà bọ̀ sípò, nǹkan á bẹ̀rẹ̀ sí í sunwọ̀n sí i.

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí ‘a ò ní gbọ́ igbe ẹkún tàbí igbe ìdààmú mọ́.’ (Àìsáyà 65:19) Èyí máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí ayé yìí bá pa dà di Párádísè lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Sáàmù 37:11, 29) Àjálù á di ohun ìgbàgbé. Kódà, gbogbo ọgbẹ́ ọkàn àti wàhálà tí ìṣẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí bá ti fà máa di ohun ìgbàgbé pátápátá, torí pé Ọlọ́run Olódùmarè ti ṣèlérí pé: “Àwọn ohun àtijọ́ ò ní wá sí ìrántí, wọn ò sì ní wá sí ọkàn.”​—Àìsáyà 65:17.

Rò ó wò ná: Ẹlẹ́dàá wa ti ṣètò láti ‘fún ẹ ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan,’ ìyẹn ìgbé ayé ìfọ̀kànbalẹ̀ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Jeremáyà 29:11) Ṣé òtítọ́ inú Bíbélì lè fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ pé ayé rẹ ṣì máa dùn àti pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára? Sally tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Tó o bá ń rán ara rẹ létí àwọn ohun àgbàyanu tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú, ó máa jẹ́ kó o lè gbọ́kàn kúrò nínú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, wàá sì lè fara da ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí.”

Jọ̀wọ́, gbìyànjú kó o kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa tó ṣe fún aráyé. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, láìka àwọn àjálù tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ, wàá rí i pé ayé rẹ ṣì máa dùn, bó o ṣe ń retí àkókò tí kò ní sí àjálù mọ́. Ní báyìí, wàá rí àwọn ìlànà Bíbélì táá jẹ́ kó o lè fara da àwọn ìṣòro to máa ń wáyé lẹ́yìn tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.