Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tí Ìṣòro Bá Pọ̀ Lápọ̀jù

Tí Ìṣòro Bá Pọ̀ Lápọ̀jù

ÌGBÉSÍ ayé máa ń dùn tí nǹkan bá ń lọ dáadáa fúnni. Àmọ́, tí ìṣòro bá pọ̀ lápọ̀jù, ńṣe ni gbogbo nǹkan máa ń súni.

Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìjì líle wáyé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sally * pàdánù èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn nǹkan tó ní, ó sọ pé: “Ìdààmú bá mi, gbogbo nǹkan sì sú mi. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, ńṣe ló ń ṣe mí bíi pé ẹ̀mí mi ò lè gbé e mọ́.”

Ìṣòro míì tó tún lágbára ni ikú ẹnì kan téèyàn fẹ́ràn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin kan tó ń jẹ́ Janice ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà nìyẹn, ó sọ pé: “Àárín ọdún méjì péré ni àwọn ọmọkùnrin mi méjèèjì kú, èyí sì mú kí n ní ẹ̀dùn ọkàn tó lékenkà. Mo gbìyànjú láti ṣara gírí débi tí agbára mi lè gbé e dé. Mo wá sọ fún Ọlọ́run pé: ‘Ìyà yìí ti pọ̀ jù, agbára mi ò gbé e mọ́! Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n kúkú sùn kí n má sì jí mọ́.’”

Àpẹẹrẹ míì tún ni ti Daniel tó ní ìdààmú ọkàn tó lágbára gan-an nígbà tí ìyàwó rẹ̀ lọ ṣèṣekúṣe pẹ̀lú ọkùnrin míì. Ó sọ pé: “Nígbà tí ìyàwó mi jẹ́wọ́ pé òun ti ṣèṣekúṣe, ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n fi ọ̀bẹ gún ọkàn mi. Ńṣe ni gbogbo ara ń ro mí goorogo lójoojúmọ́ fún ọ̀pọ̀ oṣù.”

Àwọn nǹkan tá a máa jíròrò nínú Ilé Ìṣọ́ yìí máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ pé ìgbésí ayé rẹ ṣì máa dùn kódà

Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè ṣe tí àjálù bá ṣẹlẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 3 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí àtàwọn tó tẹ̀ lé e.