Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Ti Wá Mọ Ọlọ́run Tí Mo Ń Sìn Wàyí

Mo Ti Wá Mọ Ọlọ́run Tí Mo Ń Sìn Wàyí

Ajíhìnrere kan ní ṣọ́ọ̀ṣì Gba-Jésù, tí wọ́n sọ pé ó ní agbára láti ṣe ìwòsàn, wá sí ilé ẹ̀kọ́ wa. Nígbà tó fi ọwọ́ kàn mí, mo ṣubú lulẹ̀, mo sì dá kú, mo “lọ nínú ẹ̀mí.” Nígbà tí mo sọ jí, ó ṣe mí bíi pé mo ti ní nǹkan tí mò ń wá, ìyẹn agbára láti máa ṣe ìwòsàn. Kí ló sún mi dé ìdí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ipa wo ló sì ní lórí ìgbésí ayé mi? Kí n tó sọ ohun tó fà á, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ sọ fún yín nípa ìgbésí ayé mi àtẹ̀yìn wá.

ỌJỌ́ kẹwàá oṣù December ọdún 1968 ni wọ́n bí mi ní ìlú Ilocos Norte lórílẹ̀-èdè Philippines, èmi sì ni ìkeje nínú àwa mẹ́wàá tí àwọn òbí mi bí. Inú ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ wa dàgbà bíi ti ọ̀pọ̀ ará ilẹ̀ Philippines yòókù. Mo jáde ilé ẹ̀kọ́ girama ní ọdún 1986, iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ló sì wù mí kí n ṣe. Ṣùgbọ́n, àìsàn líle kan tó ṣe mí kò jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe. Kódà, ṣe ni mo rò pé màá kú. Nígbà tí ìnira àìsàn yìí pàpọ̀jù, mo bẹ Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́, mo sì ṣèlérí pé tí mo bá bọ́ nínú àìsàn náà, òun ni màá fi gbogbo ọjọ́ ayé mi sìn.

Ó pẹ́ gan-an kí ara mi tó yá, àmọ́ lẹ́yìn náà mo rántí ìlérí tí mo ṣe fún Ọlọ́run. Torí náà, ní oṣù June ọdún 1991, mo lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì ti ṣọ́ọ̀ṣì àwọn Gba-Jésù. Ọ̀kan lára ààtò wọn nílé ẹ̀kọ́ náà ni gbígba “ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́.” Ó sì wù mí pé kí n ní agbára tí màá fi máa ṣe ìwòsàn. Wọ́n kọ́ wa ní ilé ẹ̀kọ́ náà pé ààwẹ̀ àti àdúrà la fi lè rí ẹ̀bùn náà gbà. Nítorí pé mo fẹ́ káwọn èèyàn rò pé mo ti ní “ẹ̀bùn” ẹ̀mí yìí, nígbà kan, lásìkò tí a ń gbàdúrà mo yọ́ kẹ́lẹ́ lọ gbọ́ àdúrà tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ kíláàsì mi ń gbà sókè ní kọ̀rọ̀. Nígbà tó ku díẹ̀ kí ó parí àdúrà rẹ̀, mo yára pa dà sí ibi tí mo kúnlẹ̀ sí tí mo ti ń gbàdúrà. Lẹ́yìn náà, mo lọ bá a, mo sì sọ gbogbo ohun tí ó ń tọrọ nínú àdúrà rẹ̀ gẹ́lẹ́ fún un. Ló bá gbà pé mo ti ní “ẹ̀bùn ẹ̀mí” náà lóòótọ́!

Bí mo ṣe ń bá ẹ̀kọ́ mi lọ ní ilé ẹ̀kọ́ náà, ọ̀pọ̀ ìbéèrè bẹ̀rẹ̀ sí í jà gùdù lọ́kàn mi. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Mátíù 6:9 sọ̀rọ̀ nípa “Baba” àti “orúkọ” rẹ̀. Mo wá ń béèrè àwọn ìbéèrè bíi: “Ta ni Baba tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?” àti pé “Orúkọ ta ló yẹ kí á sọ di mímọ́?” Ìdáhùn tí àwọn olùkọ́ wa máa ń fún mi kì í ṣe kedere, wọn kì í yanjú ìbéèrè mi. Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa Mẹ́talọ́kan, wọ́n ní àdììtú ni. Ìyẹn náà rú mi lójú. Síbẹ̀, mo ṣì ń bá ẹ̀kọ́ mi láti di pásítọ̀ nìṣó.

Bí Mo Ṣe Mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ní ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì yẹn, wọ́n kọ́ wa pé ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ̀sìn èké tó burú jù. Wọ́n tún máa ń pè wọ́n ní aṣòdì sí Kristi. Torí náà, mo kórìíra ẹ̀sìn náà gan-an.

Ní ọdún kejì tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ yẹn, mo wá sílé láti wá wo àwọn òbí mi nígbà ọlidé. Ọ̀kan nínú àwọn àǹtí mi, tó ń jẹ́ Carmen, gbọ́ pé mo wálé, òun náà bá wá sílé. Lákòókò yìí, ó ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ti ṣe ìrìbọmi, ó sì ti dẹni tó ń fi àkókò tó pọ̀ ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. Ó gbìyànjú láti kọ́ mi nípa Ọlọ́run, àmọ́ mo fi ìbínú sọ fún un pé: “Èmi mọ Ọlọ́run tí mò ń sìn!” Mo wá pariwo lé e lórí, mo tì í kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, mi ò sì fún un láyè láti tún bá mi sọ̀rọ̀ mọ́.

Nígbà tí mo pa dà sí ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì, Carmen fi ìwé pẹlẹbẹ náà Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí? * ránṣẹ́ sí mi. Mo rún un pọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ mo sì jù ú sínú iná, torí inú rẹ̀ ṣì ń bí mi.

Mo Di Pásítọ̀

Bí mo ṣe n bá ẹ̀kọ́ mi lọ nílé ẹ̀kọ́ Bíbélì, mo rí àwọn kan fà wọ ṣọ́ọ̀ṣì ti mo ń lọ. Inú mi dùn yàtọ̀ nígbà tí màmá mi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ṣọ́ọ̀ṣì Gba-Jésù tí mo ń lọ.

Ní oṣù March ọdún 1994, mo gboyè jáde ní ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì ti ṣọ́ọ̀ṣì àwọn Gba-Jésù. Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀, ajíhìnrere kan wá síbẹ̀ lásìkò náà. Gbogbo àwa tí a kẹ́kọ̀ọ́ yege la fẹ́ wà lọ́dọ̀ rẹ̀ torí a gbà pé ó ní ẹ̀bùn ṣíṣe ìwòsàn. A jọ wà lórí ibi pẹpẹ tó ti ń wàásù, a jọ ń pàtẹ́wọ́, à ń fò sókè káàkiri orí ibẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lu ìlù. Ẹni tí ó bá ti fọwọ́ kàn á ṣubú lulẹ̀, á sì “lọ nínú ẹ̀mí.” * Bó ṣe fọwọ́ kan èmi náà, mo ṣubú lulẹ̀, mo sì dá kú. Nígbà tí mo sọ jí, ẹ̀rù bà mí àmọ́ ó ṣe mí bíi pé mo ti ní agbára láti máa ṣe ìwòsàn, torí náà inú mi dùn gan-an.

Láìpẹ́ sígbà yẹn, mo fi agbára yìí wo ọmọbìnrin kan tó ní akọ ibà sàn. Bí mo ṣe gbàdúrà fún ọmọ náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í làágùn, ibà rẹ̀ sì fò lọ. Ọkàn mi wá balẹ̀ pé màá lè mú ìlérí tí mo ṣe fún Ọlọ́run ṣẹ wàyí. Síbẹ̀ dípò kí inú mi máa dùn, ṣe ló ń ṣe mí bíi pé ọwọ́ mi ò tíì tẹ ohun tí mo ń wá. Nínú ọkàn mi lọ́hùn-ún, mo gbà gbọ́ pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà, àmọ́ mi ò mọ ẹni tí ó jẹ́ gan-an. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì wa ni mo ń ṣiyè méjì nípa rẹ̀.

Mo fi agbára yìí wo ọmọbìnrin kan tó ní akọ ibà sàn

Àwọn Ohun Tó Mú Kí Èrò Mi Yí Pa Dà

Lẹ́yìn gbogbo ìyẹn, mo túbọ̀ wá kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an. Ìgbàkígbà tí mo bá rí ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí, ṣe ni mo máa ń jó o dà nù. Ohun kan tí mi ò rò tẹ́lẹ̀ wá ṣẹlẹ̀. Mo kàn dédé rí i pé màmá mi ò nífẹ̀ẹ́ sí ṣọ́ọ̀ṣì Gba-Jésù tí a jọ ń lọ mọ́, ìyẹn sì yà mí lẹ́nu. Àṣé Carmen ti ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì! Inú bí mi sí àǹtí mi gan-an.

Mo wá rí ìwé ìròyìn Jí! kan nínú ilé màmá mi. Ká ní tẹ́lẹ̀ ni, màá ti jó o dà nù. Ṣùgbọ́n torí pé mo tiẹ̀ fẹ́ wo ohun tí màmá mi ń rí kà níbẹ̀ gan-an, mo yẹ̀ ẹ́ wò gààràgà. Ojú mi kàn ta sí àpilẹ̀kọ kan tó sọ nípa ẹnì kan tó gba àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì gbọ́ gan-an tẹ́lẹ̀ rí. Àmọ́ bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó wá dá a lójú pé àwọn ẹ̀kọ́ bíi, Mẹ́talọ́kan, iná ọ̀run àpáàdì àti àìleèkú ọkàn kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Ohun tí mo kà yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, torí nǹkan tí èmi náà ti fẹ́ mọ̀ gan-an nìyẹn. Láti ìgbà náà ni ó ti ń wù mí gan-an pé kí èmi náà mọ òtítọ́ inú Bíbélì dunjú.

Nígbà tí mo tún ka ìtàn ìgbésí ayé ẹlòmíì nínú ìwé ìròyìn Jí!, tó jẹ́ ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀mùtí, tó sì máa ń lo oògùn olóró, àmọ́ tó ti wá yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà torí pé ó kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì, mo túbọ̀ tẹra mọ́ kíka ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí. Mo rí ìwé pẹlẹbẹ kan tó ń jẹ́ Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae. * Nígbà tí mo kà á mo rí i pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Inú mi sì dùn gan-an pé mo ti wá mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà!—Diutarónómì 4:39; Jeremáyà 10:10.

Inú mi sì dùn gan-an pé mo ti wá mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà!!

Mo wá ń yọ́lẹ̀ ka ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ, èyí sì mú kí n túbọ̀ mọ ọ̀pọ̀ òtítọ́ inú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ní ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì ti ṣọ́ọ̀ṣì àwọn Gba-Jésù tí mo lọ, wọ́n kọ́ mi pé Jésù ni Ọlọ́run, àmọ́ ohun tí mo rí kà nínú Bíbélì ni pé “Ọmọ Ọlọ́run alààyè” ni Jésù jẹ́.—Mátíù 16:15, 16.

Mo Yí Ọkàn Pa Dà

Nígbà tí èmi àti Carmen tún ríra, ó yà á lẹ́nu bí mo ṣe ní kó fún mi ní ìwé pẹlẹbẹ náà Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae àti àwọn ìwé míì. Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo lò ní ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo lọ, ṣùgbọ́n wọ́n kò kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ níbẹ̀, ṣe ni wọ́n fi mí sínú òkùnkùn biribiri nípa òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ ní báyìí, ayọ̀ kún ọkàn mi torí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí mo ń kọ́ látinú Bíbélì. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ wá ṣẹ sí mi lára, ó ní: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí í yí ìgbésí ayé mi pa dà.

Àwọn òtítọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ síi yí ìgbésí ayé mi pa dà

Mo kọ́kọ́ rò pé mo lè máa yọ́lẹ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run, kí n sì máa bá iṣẹ́ pásítọ̀ tí mo ń ṣe nìṣó. Àmọ́ kò pẹ́ tí mo fi rí i pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì wa ni ọkàn mi ò gbà kí n máa kọ́ àwọn èèyàn mọ́. Ṣùgbọ́n, ẹ̀rù ń bà mí. Mo ń rò ó pé báwo ni mo ṣe fẹ́ máa rí owó tí màá fi gbọ́ bùkátà ara mi tí mo bá fi iṣẹ́ pásítọ̀ sílẹ̀? Àti pé ìtìjú ńlá ló máa jẹ́ fún ṣọ́ọ̀ṣì wa tí ọ̀kan lára àwọn pásítọ̀ wọn bá lọ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà! Torí náà mo ń bá iṣẹ́ pásítọ̀ lọ, àmọ́ mo máa ń yẹra fún kíkọ́ àwọn èèyàn ní àwọn tó jẹ́ ẹ̀kọ́ èké lára ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì wá.

Nígbà tí èmi àti Carmen tún ríra, ó dábàá pé kí n lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó sì ti jẹ́ pé mo máa ń yọjú sí ṣọ́ọ̀ṣì tí olórí wa wà ní ìlú Laoag City, mo yọ́lẹ̀ wá ibi ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn Gbọ̀ngàn Ìjọba, níbẹ̀. Ìjọ yẹn ni wọ́n ti fi mí mọ arábìnrin Alma Preciosa Villarin, tí wọ́n tún máa ń pè ní “Precious.” Ó jẹ́ ẹni tó máa ń fi àkókò tó pọ̀ ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, mi ò tíì fi taratara fara mọ́ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, mo gbà pé kí arábìnrin yẹn máa kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ Bíbélì.

Mo rí i pé bí ẹ̀gbọ́n mi ṣe ní sùúrù gan-an nígbà tó ń sọ òtítọ́ inú Bíbélì fún mi, náà ni Precious ṣe ń ṣe pẹ̀lú mi. Ó ràn mí lọ́wọ́ gan-an kí n lè lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú máa ń bí mi nígbà míì, tí màá bá a jiyàn, màá fìbínú sọ̀rọ̀ fatafata, tí màá sì máa rin kinkin mọ́ àwọn nǹkan tí wọ́n ti fi kọ́ mi ní ṣọ́ọ̀ṣì. Bí arábìnrin Precious àti àwọn Ẹlẹ́rìí yòókù ṣe fìfẹ́ hàn sí mi, tí wọ́n fi ìwà tútù bá mi lò àti bí wọ́n ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Èyí mú kí n fẹ́ láti sin Jèhófà.

Ní July ọdún 1995, mo rí i pé kò sí ṣíṣe kò sí àìṣe, àfi kí n fi iṣẹ́ pásítọ̀ tí mò ń ṣe sílẹ̀ tí n bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kí nìdí? Ìwé Ìṣípayá 18:4 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn èké lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, lẹ́yìn náà ó sọ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.” Báwo ni màá ṣe wá máa gbọ́ bùkátà ara mi? Ohun tó wà nínú ìwé Hébérù 13:5 jẹ́ kí n mọ̀ pé tí a bá ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ìlérí Ọlọ́run ni pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.”

Láìka bí bàbá mi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ṣe wá ń ta kò mí sí, nígbà tó ku ọ̀sẹ̀ méjì kí n ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo ṣọkàn gírí mo wá sílé, mo sì jó gbogbo àwọn nǹkan tí mo ń lò nígbà tí mo ṣì jẹ́ pásítọ̀. Lẹ́yìn èyí, mo rí i pé gbogbo agbára àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n fún mi tẹ́lẹ̀ lọ pátápátá. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tí mo bá ń sùn, ó máa ń ṣe mí bíi pé nǹkan kan máa ń rìn mí mọ́lẹ̀ ṣáá. Ìyẹn kò tún ṣẹlẹ̀ mọ́. Bákan náà, mi ò tún rí àwọn òjìji tí mo sábà máa ń rí lójú fèrèsé mi mọ́. Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo ń kọ́ báyìí ti jẹ́ kí n mọ̀ pé èyíkéyìí nínú ẹ̀bùn ẹ̀mí tí àwọn èèyàn ń sọ pé àwọn ní lóde òní, irú bí èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìwòsàn, kò wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù ló ti wá. Inú mi dùn púpọ̀ pé mo ti bọ́ lọ́wọ́ ìdarí wọn bíi ti ìránṣẹ́bìnrin tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà dá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ “ẹ̀mí èṣù ìwoṣẹ́.”—Ìṣe 16:16-18.

Ẹ wo bí mo ṣe láyọ̀ tó bí èmi àti màmá mi ṣe dúró sí ẹ̀gbẹ́ ara wa nígbà tí a jọ fẹ́ ṣèrìbọmi láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóṣù September ọdún 1996! Lẹ́yìn tí mo ṣe ìrìbọmi, mo di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó máa ń fi àkókò tó pọ̀ ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, mo sì gbádùn bí mo ṣe fi ọ̀pọ̀ ọdún lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ náà.

Ní báyìí, èmi àti ọkọ mi Silver ti ṣe ìgbéyàwó. A sì jọ ń sa gbogbo ipá wa láti fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì tọ́ ọmọ wa obìnrin. Méjì nínú àwọn àǹtí mi àti àbúrò mi obìnrin kan náà ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tiwa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dùn mí pé ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi wà láìmọ Ọlọ́run, inú mi dùn pé mo ti wá mọ Ọlọ́run tí mo ń sìn wàyí.

^ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, àmọ́, a kò tẹ̀ ẹ́ mọ́.

^ Ọ̀rọ̀ náà “lọ nínú ẹ̀mí” ni àwọn onísìn kan sábà máa ń lò fún ọmọ ìjọ wọn tí wọ́n gbà pé “ẹ̀mí” bà lé lọ́nà tó lágbára gan-an débi pé ó ṣubú lulẹ̀.

^ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.