Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Inú Rere Ṣe Pàtàkì Lójú Ọlọ́run

Inú Rere Ṣe Pàtàkì Lójú Ọlọ́run

INÚURE bàbá àgbàlagbà kan tó jẹ́ èèyàn jẹ́jẹ́ wú ọ̀dọ́kùnrin kan ní orílẹ̀-èdè Japan lórí gan-an. Míṣọ́nnárì ni bàbá yìí, kò tíì ju ọdún mélòó kan tó dé orílẹ̀-èdè Japan, bẹ́ẹ̀ ni kò sì tíì fi bẹ́ẹ̀ mọ èdè ilẹ̀ Japan sọ. Síbẹ̀, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ló máa ń lọ sí ilé ọ̀dọ́kùnrin yìí láti kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Bàbá yìí máa ń fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, ẹ̀rín músẹ́ àti sùúrù dáhùn àwọn ìbéèrè ọ̀dọ́kùnrin tó máa ń béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè yìí.

Inúure bàbá yìí wọ ọ̀dọ́kùnrin náà lọ́kàn gan-an débi pé kò lè gbàgbé rẹ̀. Ó wá rò ó pé, ‘Tí Bíbélì bá lè múni di onínúure àti ẹni tó nífẹ̀ẹ́ tó báyìí, màá rí i dájú pé mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀.’ Bó ṣe wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ohun kan tó ṣàjèjì sí i pátápátá nìyẹn. Bẹ́ẹ̀ ni o, inú rere máa ń wọni lọ́kàn gan-an, ó sì sábà máa ń ní ipa tó lágbára lórí èèyàn ju ọ̀rọ̀ ẹnu lọ.

Ó Jẹ́ Ìwà Tí A Lè Fi Jọ Ọlọ́run

Lóòótọ́, ó wà nínú ẹ̀jẹ̀ àwa ẹ̀dá pé ká máa ṣe inúure sí àwọn tí wọ́n bá wa tan tímọ́tímọ́ *. Ọlọ́run ló dá inú rere mọ́ wa, ọ̀kan nínú ìwà rẹ̀ ni. Àmọ́ Jésù sọ pé kì í ṣe kìkì àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Baba òun nìkan ni ó máa ń ṣe inúure sí, pé ó tún máa ń ṣe inúure “sí àwọn aláìlọ́pẹ́” náà. Jésù wá rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí àwọn náà ṣe bíi ti Ọlọ́run, kí wọ́n máa ṣe inúure sí gbogbo èèyàn. Ó ní: “Ẹ jẹ́ pípé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí Baba yín ọ̀run ti jẹ́ pípé.”—Lúùkù 6:35; Mátíù 5:48; Ẹ́kísódù 34:6.

Dídá tí Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀ mú kí a jẹ́ ẹni tó lè fìwà jọ Ọlọ́run, ká sì jẹ́ onínúure bíi tirẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Torí náà, a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run kí àwa náà máa ṣe inú rere sí àwọn tó bá wa tan àti àwọn tí kò bá wa tán. Bíbélì sọ pé inú rere jẹ́ apá kan lára èso ẹ̀mí mímọ́, tàbí ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, tó yẹ ká ní. (Gálátíà 5:22) Nítorí náà, a lè fi kọ́ra, ká dẹni tó ń hù ú níwà bí a ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́, tí a sì ń mọ Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá wa sí i, tí a sì túbọ̀ ń sún mọ́ ọn.

Yàtọ̀ sí pé inú rere jẹ́ ara ìwà tí Ọlọ́run dá mọ́ àwa èèyàn ká máa hù, ó tún ṣe pàtàkì gan-an lójú Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi bọ́gbọ́n mu bí Ọlọ́run ṣe sọ fún wa pé kí a jẹ́ ‘onínúrere sí ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’ (Éfésù 4:32) Bíbélì sì tún rán wa létí pé: “Ẹ má gbàgbé aájò àlejò,” tàbí ṣíṣe inúure sí àwọn tí a kò mọ̀ rí.—Hébérù 13:2.

Nínú ayé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ti jẹ́ aláìláàánú àti aláìmoore yìí, ǹjẹ́ a lè máa ṣe inú rere sí àwọn ẹlòmíì, títí kan àwọn tí a kò mọ̀ rí? Kí ló máa mú ká máa ṣe bẹ́ẹ̀? Kí tiẹ̀ ni ìdí tó fi yẹ kí á rí i dájú pé a jẹ́ onínúure?

Ó Ṣe Pàtàkì Lójú Ọlọ́run

Ṣàkíyèsí pé lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe inú rere sí àwọn tí a kò mọ̀ rí, ó sọ pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀, àwọn kan ṣe àwọn áńgẹ́lì lálejò, láìjẹ́ pé àwọn fúnra wọn mọ̀.” Ìwọ rò ó wò ná, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ ká ní o láǹfààní láti ṣe àwọn áńgẹ́lì lálejò? Ṣùgbọ́n rántí pé gbólóhùn tí Pọ́ọ̀lù fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “láìjẹ́ pé àwọn fúnra wọn mọ̀.” Lọ́nà míì, ohun tó ń sọ ni pé tó bá ti mọ́ wa lára láti máa ṣe àwọn èèyàn lóore, títí kan àwọn àjèjì tàbí àwọn tí a kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀, a lè jàǹfààní rẹ̀ láwọn ọ̀nà tí a kò ronú kàn.

Ọ̀pọ̀ Bíbélì tó ní atọ́ka níbi tí Pọ́ọ̀lù ti sọ ọ̀rọ̀ yìí, ló tọ́ka sí ìtàn Ábúráhámù àti ti Lọ́ọ̀tì tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì orí kejìdínlógún àti ìkọkàndínlógún. A rí i kà nínú ìtàn àwọn méjèèjì yìí pé àwọn áńgẹ́lì wá sí ọ̀dọ̀ wọn bíi pé wọ́n jẹ́ àjèjì tó wá jíṣẹ́ pàtàkì fún wọn. Ní ti Ábúráhámù, ohun tí àwọn áńgẹ́lì wá sọ fún un dá lórí bí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ó máa bí ọmọkùnrin kan ṣe máa ní ìmúṣẹ, àmọ́ ní ti Lọ́ọ̀tì, ohun táwọn áńgẹ́lì wá sọ fún un ni bí ó ṣe máa yè bọ́ nínú ìparun tó fẹ́ dé bá ìlú Sódómù àti Gòmórà.—Jẹ́nẹ́sísì 18:1-10; 19:1-3, 15-17.

Tí o bá ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí nínú ìpínrọ̀ tó ṣáájú èyí wàá rí i pé, àwọn tí Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì kò mọ̀ rí, tó kàn ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá lọ ni wọ́n ṣe inúure sí. Òótọ́ ni pé, láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ó jẹ́ àṣà àti ojúṣe àwọn èèyàn láti máa ṣe àwọn tó bá ń rìnrìn àjò tàbí tí wọ́n ń kọjá lọ lálejò, yálà wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́, ìbátan tàbí àjèjì. Kódà, Òfin Mósè sọ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì tó bá ń gbé ní orílẹ̀-èdè wọn. (Diutarónómì 10:17-19) Ṣùgbọ́n, ẹ̀rí fi hàn pé Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì tiẹ̀ ṣe kọjá àṣà tó pa dà wá di òfin nígbà tó yá yìí. Wọ́n sa gbogbo ipá wọn láti ṣe inúure sí àwọn tí wọn kò mọ̀ rí rárá, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ìbùkún gbà.

Inú rere Ábúráhámù jẹ́ kó rí ìbùkún gbà ní ti pé ó bí ọmọkùnrin kan, àwa náà sì tún jàǹfààní inú rere rẹ̀. Lọ́nà wo? Ábúráhámù àti Ísákì ọmọ rẹ̀ kó ipa pàtàkì nínú bí ète Jèhófà ṣe ní ìmúṣẹ. Wọ́n di òpómúléró nínú ìlà ìdílé àwọn tí Jésù tó jẹ́ Mèsáyà ti wá. Nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́, ohun tí wọ́n ṣe tún jẹ́ àpẹẹrẹ bí ìfẹ́ àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ṣe mú kí Ọlọ́run pèsè ìgbàlà fún aráyé.—Jẹ́nẹ́sísì 22:1-18; Mátíù 1:1, 2; Jòhánù 3:16.

Àwọn ìtàn yìí túbọ̀ tẹ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn tí òun fẹ́ràn máa ṣe mọ́ wa lọ́kàn dáadáa, ó tún jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó lójú rẹ̀ pé ká jẹ́ onínúure. Ṣíṣe inúure kì í ṣe ọ̀ràn bí ó bá wù wá, ohun tó ṣe pàtàkì gan-an ni lójú Ọlọ́run.

Tí A Bá Jẹ́ Onínúure A Ó Túbọ̀ Mọ Ọlọ́run

Bíbélì ti sọ pé nígbà ìkẹyìn tí a wà yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn máa jẹ́ “aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tímótì 3:1-3) Ó dájú pé ojoojúmọ́ ni à ń bá irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ pàdé. Síbẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìwà wọn mú kí a ṣíwọ́ ṣíṣe inúure sí àwọn èèyàn. Bíbélì rán àwa Kristẹni létí pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. Ẹ pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lójú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:17.

Ẹ jẹ́ ká máa sa gbogbo ipá wa láti ṣe oore kí á sì máa ṣe é tinútinú. Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì nífẹ̀ẹ́ . . . jèrè ìmọ̀ nípa Ọlọ́run.” Ara ọ̀nà tí a lè gbà fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíì ni pé kí a máa ṣe oore fún wọn. (1 Jòhánù 4:7; 1 Kọ́ríńtì 13:4) Dájúdájú, bí a bá ń ṣe inúure sí àwọn èèyàn, a óò túbọ̀ mọ Ọlọ́run, èyí á sì mú ká túbọ̀ láyọ̀. Nínú ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú, níwọ̀n bí a ó ti fi àánú hàn sí wọn. Aláyọ̀ ni àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà, níwọ̀n bí wọn yóò ti rí Ọlọ́run.”—Mátíù 5:7, 8.

Tóò bá mọ ohun tó yẹ kóo ṣe tàbí sọ, ohun tó bá máa fi inú rere hàn ni kó o sọ tàbí ṣe

Wo àpẹẹrẹ Aki, ìyàwó ilé kan ní ilẹ̀ Japan tó ní ọmọkùnrin méjì. Ṣàdédé ni ìyá rẹ̀ kú, ìdààmú ọkàn sì bá a gan-an. Kódà, nígbà míì ìdààmú ọkàn rẹ̀ máa ń pọ̀ débi pé yóò lọ gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà. Láàárín àsìkò náà ni obìnrin kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ kó wá sí àdúgbò àwọn Aki. Kò tíì pẹ́ tí ọkọ obìnrin náà kú nínú ìjàǹbá kan, tó wá ku òun àti àwọn ọmọ kéékèèké márùn-ún. Àánú obìnrin yìí ṣe Aki gan-an, ló bá pa ọ̀rọ̀ tiẹ̀ mọ́ra, ó sún mọ́ ìdílé yìí, ó sì di ọ̀rẹ́ obìnrin náà àtàwọn ọmọ rẹ̀. Ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti fi ran ìdílé náà lọ́wọ́. Ó ń fún wọn ní oúnjẹ, àwọn aṣọ tó ti fo àwọn ọmọ tirẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bó ṣe wá borí ìdààmú ọkàn rẹ̀ nìyẹn. Ó wá rí i pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ká sòótọ́, tí o bá ní ìdààmú ọkàn, ohun tó ti dáa jù ni pé kí o máa ṣe inúure sí àwọn míì.

“Jèhófà Ni Ó Ń Wín”

Kò pọn dandan kí inú rere náni lówó rẹpẹtẹ. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀ràn bí a ṣe mọ nǹkan ṣe sí tàbí bóyá èèyàn jẹ́ alágbára. Ẹ̀rín músẹ́ tí a rín sí ẹnì kan, sísọ ọ̀rọ̀ ìtùnú fúnni, ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fúnni, fífúnni ní ẹ̀bùn tó bọ́ sí àkókò bí kò tiẹ̀ pọ̀, tàbí fífún àwọn míì láyè láti kọjá ṣáájú wa tí a bá wà lórí ìlà, máa ń dára púpọ̀, àwọn èèyàn sì sábà máa ń mọrírì rẹ̀. Tí o kò bá mọ ohun tó tọ́ láti sọ tàbí ohun tó tọ́ láti ṣe nínú ipò kan, sọ ọ̀rọ̀ onínúure tàbí kó o ṣe ohun tó máa fi hàn pé o jẹ́ onínúure. Inúure bàbá àgbàlagbà tó jẹ́ míṣọ́nnárì tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè ilẹ̀ Japan, tí a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ló fa ọ̀dọ́kùnrin tí a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yẹn mọ́ra ju ọ̀rọ̀ ẹnu bàbá yẹn lọ. Abájọ tí Ọlọ́run fi pàṣẹ pé kí àwọn tí ó ń jọ́sìn òun “nífẹ̀ẹ́ inú rere”!—Míkà 6:8.

Oore kì í gbé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, bó ti wù kí inúure kéré tó, ó máa ń ṣèrànwọ́ ju bí a ṣe rò lọ. Tí a bá fi ọkàn tó dáa ṣe inú rere, ó máa ń yọrí sí ìdùnnú fún àwa tí a ṣe é, àti ẹni tí a ṣe é fún, pàápàá tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ tí a ní fún Ọlọ́run ló sún wa ṣe é. Kódà bí àwọn èèyàn kò bá tiẹ̀ mọyì inúure rẹ, má rò pé o ṣe àṣedànù. Ọlọ́run mọyì rẹ̀ gan-an ni. Bíbélì jẹ́ kí ó dá wa lójú pé ẹni tó bá ń ṣe inúure sí ọmọnìkejì rẹ̀, “Jèhófà ni ó ń wín.” (Òwe 19:17) Nítorí náà, rí i pé ò ń lo àǹfààní tí o bá ní láti máa ṣe inúure sí àwọn míì.

^ Ìwé gbédègbẹyọ̀ tó ń jẹ́ The Oxford English Dictionary fi hàn pé “inú rere” túmọ̀ sí “ìbátan; kéèyàn sún mọ́ ẹnì kan; irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀.”