Àwọn Orin Wa Míì

Ẹ máa gbádùn àwọn orin ọlọ́kan-ò-jọ̀kan tó máa jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ mọyì ogún tẹ̀mí wa.

Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ

Ayọ̀ tá a ń ní kò láfiwé bá a ṣe ń tún ayé àwọn èèyàn ṣe tá a sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

A Ò Ní Gbàgbé Yín

Àwọn ará kò ní gbàgbé wa nígbà ìṣòro.

Iṣẹ́ Tí Mò Ń Ṣe

Àtẹ tí wọ́n fi ń wàásù ni mo jẹ́.

“Fi Àwọn Ohun Ìní Rẹ Tí Ó Níye Lórí Bọlá fún Jèhófà”

Kí la lè fún Jèhófà tó máa mú inú rẹ̀ dùn?

Mo Fẹ́ Fi Ayé Mi Sìn Ọ́

Fi gbogbo ara rẹ sin Ọlọ́run nígbà tó o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́.

Mo Borí Àdánwò

Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ kò ṣe ní ṣe ohun tí àwọn ẹgbẹ́ wọn ń ṣe ní ilé ìwé

Isinsìnyí Ló Yẹ Ká Túbọ̀ Wàásù

Tá a bá ní irú ẹ̀mí tí àwọn àṣáájú-ọ̀nà ní sí iṣẹ́ ìwáásù wa, á mú ká máa fi ìtara wàásù fún àwọn aládùúgbò wa.

Ẹ̀rín Músẹ́ Nìkan Ti Tó

Ẹ̀rín músẹ́ lè mú kí wọ́n gbọ́ wa, ó sì lè mú kí ayé wa túbọ̀ nítumọ̀.

Màá Wá Ìṣúra

Táa bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, táa sì ń ṣe ìjọsìn ìdílé, ó máa jẹ́ ká dàgbà nípa tẹ̀mí.

Jèhófà Ń Kí Ẹ Káàbọ̀ Sílé

Èmí mímọ́ Ọlọ́run lè ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.

Ayọ̀ Àpéjọ Wa!

Tá a bá lọ sí àpejọ̀ àgbègbè, a máa ń gbádùn ìṣọ̀kan àti ìfẹ́ ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé.

Ohun Tó Dáa Jù Ni Mo Fún Ọ

Kìí rọrùn fún àwọn òbí láti rí i pé ọmọ àwọn ń kó lọ sí ibi tó jìn sí wọn.

Fara Balẹ̀ Yan Ẹni Tó O Máa Fẹ́

Tá a bá fẹ́ yan ẹni tá a máa fẹ́, ṣe ló yẹ ká fara balẹ̀, ká má ṣe kánjú.

Fojú Inú Wò Ó

Ìgbà ọ̀tun ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé.

Máa Bá a Lọ

Máa bá ètò Jèhófà tó ń tẹ̀síwájú rìn!

Àwọn Ìbùkún Kíkọ́ Èdè Míì

Àwọn ìbùkùn wo lo máa rí tóo bá kọ́ èdè tuntun?

Má Ṣe Kánjú

Táa bá ń fara balẹ̀, tá ò sì kánjú jù, a máa gbádùn iṣẹ́ ìwáásù wa àti ìgbésí ayé wa.

“Tẹ̀ lé Ipa Ọ̀nà Áàjò Àlejò”

Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà fi ẹ̀mí áájò àlejò hàn?

O Ṣé O Baba

Jèhófà ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè kojú àwọn ìṣòro wa. Èyí ló ń mú ká fi orín dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Ibi Tó Yẹ Mí

Báwo lo ṣe lè yan àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́?

Ìpinnu

Ó yẹ ká máa rónú lórí bí àwọn ìpinnu táa ń ṣe ṣe ń nípa lórí iṣẹ́ ìwáásù wa àti àwọn míì.

Ẹ Máa Dárí Ji Ara Yín

Tó bá di pé kó o dárí ji àwọn míì, máa wo bó o ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà nínú ayé ẹ.

Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Tán

Tá a bá ń fọkàn yàwòrán Párádísè tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó máa jẹ́ ká lè fara da àdánwò.

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Dára

Táwọn ọ̀dọ́ bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.

Ọ̀rọ̀ Rẹ Wà Títí Láé

Yin Ọlọ́run torí bó ṣe pa Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ fún aráyé!

Gbàdúrà sí Jèhófà

Kí la lè ṣe tá a bá níṣòro?

Màá Fọjọ́ Ọ̀la Mi Sin Jèhófà

Jẹ́ kí àwọn ìpinnu tó ò ń ṣe lójoojúmọ́ máa múnú Jèhófà dùn.

A Nílò Ìgbàgbọ́

Ó gba ìsapá kí ìgbàgbọ́ wa tó lè lágbára, àmọ́ Jèhófà máa san wá lẹ́san tá a bá sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Àwọn Ìránnilétí Rẹ Ràn Mí Lọ́wọ́

Ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a mọyì àwọn ìránnilétí Jèhófà nínú ìwà àti ìṣe wa.

Mo Ṣì Lè Dìde

Wo bí ìránṣẹ́ Jèhófà kan tó nítara tẹ́lẹ̀ ṣe rí ohun tó ràn án lọ́wọ́ tó fi lè pa dà sínú ìjọ Ọlọ́run, láàárín àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Ìyanu Ni Iṣẹ́ Rẹ

Mọyì àǹfààní tó o ní láti máa bá Jèhófà ṣiṣẹ́!

Ọmọbìnrin Mi Ọ̀wọ́n

Bàbá kan tọ́ ọmọ rẹ̀ láti kékeré títí ó fi dàgbà, tó sì sọ òtítọ́ di tara rẹ̀.

Fìgbàgbọ́ Ṣohun Tó Tọ́

Tí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ba fi kún iṣẹ́-ìsìn wa ní ọ̀nà èyíkèyìí, a máa láyọ̀ gan-an.

Wojú Mi

Gbádùn àsìkò tó o wà pẹ̀lú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

Oníṣẹ́ Àrà, Mo Gbé Ọ Ga!

Ìyanu ni gbogbo iṣẹ́ Jèhófà, ó sì mú ká máa gbé e ga.

Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù

A gbọ́dọ̀ wáyè fóhun tó ṣe pàtàkì jù​—àdúrà, ìkẹ́kọ̀ọ́, ká sì sún mọ́ Jèhófà.

Ìfẹ́ Tòótọ́

Tá a bá fi Jèhófà ṣatọ́nà nínú ìgbeyàwó wa, ìgbeyàwó wa á ládùn, á sì lóyin!

Ilé Tó Máa Mú Ìyìn Wá Bá Ọ

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa pé ó jẹ́ ká lè kọ́ ilé tó máa gbé orúkọ rẹ̀ ga.

Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọ

Táa bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, ó máa fún wa lókun lati fara da àwọn ìṣòro ìgbésí ayé.

Mo Gbọ́dọ̀ Ṣe Àyípadà

Ṣé ó ti ṣe tán láti ṣe àyípadà lẹ́nu iṣẹ́ ìwáàsù rẹ?

Jèhófà Wà Pẹ̀lú Mi

Táa bá ti ní Jèhófà bí Ọlọ́run wa, a ò ní dá wà láé!

Ìfẹ́ Ará

Kò sí àwùjọ kankan láyé yìí tó máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro bí àwa èèyàn Jèhófà.

Má Bẹ̀rù

Tá a bá ń kojú ìṣòro, ká máa rántí pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa.

À Ń Wá Òtítọ́

Àwọn tó bá ń wá bí wọ́n á ṣe mọ Ọlọ́run lè mọ̀ ọ́ tí wọ́n bá ń sapá láti wá a.

Ọ̀rẹ́ Tòótọ́

Ibo la ti máa rọ́rẹ̀ẹ́ gidi tó ṣeé fọkàn tán?

Màá Dúró Tì Ẹ́

Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ á dúró tì wá nígbà dídùn àtìgbà kíkan.

Jèhófà Ló So Wá Pọ̀

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro pọ̀ láyé, ẹgbẹ́ ara wa wà níṣọ̀kan àti ní àlááfíà.

Jẹ́ Kí N Ní Ìgboyà

Jèhófà lè jẹ́ ká ní ìgboyà ká lè fara da àdánwò yòówù kó dé bá wa.

Màá Sin Jèhófà Tọkàntọkàn

Jèhófà yẹ lẹ́ni tá à ń fi gbogbo ọkàn wa sìn lóòótọ́.

Ọjọ́ Kọ̀ọ̀kan Ní Wàhálà Tiẹ̀

Láìkà ti pé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní wàhálà tiẹ̀, a lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn, ká sì láyọ̀.

Jẹ́ Onígboyà àti Alágbára

Orin aládùn tó máa ń jẹ́ ká lè fara dàá.

Mo Dúpẹ́ fún Ìṣẹ̀dá Ọlọ́run

Máa kí yè sí àwọn ìṣẹ̀dá Jèhófà, kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.

Ìdílé Kan Ni Wá

Ibi yòówù ká wà, ara ìdílé Jèhófà ni wá.

“Ja Ìjà Rere ti Ìgbàgbọ́”

A lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìka ìṣòro tàbí ẹ̀dùn ọkàn èyíkéyìí tá a bá ní sí.

Jèhófà Máa Ń Dúró Tì Wà

Ó máa ń wu Jèhófà pé kó dì wá lọ́wọ́ mú.

Ayé Tuntun

A lè ní èrò tó dáa tá a bá ń ronú nípa nǹkan tó dáa. Orin yìí ti jẹ́ ká máa fojú inú wo bí ayé tuntun ṣe máa rí.

Mo Fi Ayé Mi Fún Ọ

Ifẹ́ tá a ní sí Jèhófà ló ń mú ká yara wa sí mímọ́ fún-un, ká sì ṣèrìbọmi.

Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀

Ìfẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà kì í yẹ̀. Ó máa ń fún wa ní ayọ̀ àti ìtùnú.

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Tó o bá ní ẹ̀dùn ọkàn, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa tù ẹ́ ninú, ó sì máa fún ẹ lágbára.

Fìwà Jọ Ọmọdé

Báwo la ṣe lè dà bí ọmọdé lọ́nà tá a gbà ń fi ìfẹ́ hàn?

Ó Dá Mi Lójú

Ó yẹ kó dá wa lójú pé kò síṣòro tó lè yà wá nínú ìfẹ́ Jèhófà.

Máa Dárí Jini Látọkàn

Ṣé ẹnì kan ti ṣẹ̀ ẹ́ rí? Ṣé ó ṣì nira fún ẹ láti dárí ji onítọ̀hún? Wo bó o ṣe lè dárí ji ẹni náà látọkàn.

Sá Eré Náà Dé Òpin

Ṣe àwon ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, kó o lè sá eré ìje ìyè dé òpin.

A Ò Ní Wẹ̀yìn

Tá a bá fẹ́ kọ́ ilé tó lágbára, a gbọ́dọ̀ lo àwọn ohun èèlò tó jẹ́ ojúlówó. Lọ́nà kan náà, tá a bá fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, àwọn ohun pàtàkì kan wà tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe.

Ẹni Tọ́kàn Mi Fẹ́

Ẹ̀bùn ni ìgbéyàwó jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà. Jẹ́ kó máa múnú rẹ dùn.

Máa Ṣọ́ Ohun Tí Ò Ń Rò

Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí èrò tí kò tọ́.

“Máa Yọ̀ Nígbà Gbogbo”

Orin ayọ̀ máa ń rán wa létí ìdí tó fi yẹ kínú wa máa dùn.

A Wà Níṣọ̀kan

Láìka àtakò àti inúnibíni tá à ń kojú, àwa èèyàn Jèhófà wà níṣọ̀kan.

Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Jèhófà

Tó o bá tẹra mọ́ isẹ́ Jèhófà, o ò ní kábàámọ̀!

Orísun Ayọ̀ Wa

Jèhófà ni orísun ayọ̀ wa ní báyìí àti títí láé.

Ìlérí Ọlọ́run Máa Ṣẹ

Jẹ́ kí ìrètí ayé tuntun máa múnú ẹ dùn.

Wá Àyè fún Jèhófà

Kéèyàn wáyè fún Jèhófà lohun tó ṣe pàtàkì jù téèyàn lè fayé ẹ̀ ṣe.

Mo Ní Ìgbàgbọ́

Fojú inú wo ohun àgbàyanu tí Ọ̇lọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé.

Àlàáfíà Ayérayé! (Orin Àpéjọ Agbègbè ti Ọdún 2022)

Jẹ́ kí ìlérí àlàáfíà tí Ọlọ́run ṣe mú kó o máa fara da ìṣòro tó o ní.

“Kò Ní Pẹ́ Rárá!” (Orin Àpéjọ Agbègbè 2023)

Máa fi sùúrù dúró de Jèhófà bíi tàwọn tó fòótọ́ sin Jèhófà nígbà àtijọ́.