Màá Wá Ìṣúra
Wà á jáde:
1. Bí mò ń kẹ́kọ̀ọ́, Ọ̀r’Ọlọ́run
Ìṣura wà tí mò ń rí
Mò ń ṣèwádìí, kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀
Fún ìṣẹ́jú mélòó kan
Àfi bíi pé èmi alára wà níbẹ̀
Ó ń jẹ́ kí n lóye ohun tí Bíbélì sọ
(ÈGBÈ)
Wòó bíi póo wà ńbẹ̀, kóo sì ṣàṣàrò,
Ló ń jẹ́ n lóye ohun tó ṣẹlẹ̀.
Àti bí mo ṣe lè ṣohun tó tọ́,
Kí n sì tún ní ìwà rere;
Kí n ní ìwà rere.
2. Ronú nípa àwọn èèyàn;
Tó dára, tí kò dára.
Àpẹẹrẹ wọn ń jẹ́ kí n lóye
Bí Ọlọ́run ṣe ń ronú.
Nígbà míì àṣàrò mi máa ń jẹ́ kí n lè mọ
Bí mo ṣe lè wá túbọ̀ máa wu Jèhófà.
(ÈGBÈ)
Wòó bíi póo wà ńbẹ̀, kóo sì ṣàṣàrò,
A ó wá lóye nǹkan tó ṣẹlẹ̀.
Àti bí a ṣe lè ṣohun tó tọ́,
Ká sì tún ní ìwà rere;
Ká ní ìwà rere
(ÈGBÈ)
Wòó bíi póo wà ńbẹ̀, kóo sì ṣàṣàrò,
Wòó bíi póo wà ńbẹ̀, kóo sì ṣàṣàrò,
Wòó bíi póo wà ńbẹ̀, kóo sì ṣàṣàrò.