Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fìwà Jọ Ọmọdé

Fìwà Jọ Ọmọdé

Wà á jáde:

  1. 1. Jésù Kristi kọ́ wa

    Pé ká dà bí ọmọdé

    Ẹ̀mí ìgbéraga ló gbayé kan.

    Àmọ́ ó yẹ ká nírẹ̀lẹ̀

    Ká jọ Jèhófà, ká fìfẹ́ hàn sí gbogbo àwọn èèyàn.

    (ÈGBÈ)

    Ká nírẹ̀lẹ̀; ká fìwà jọ àwọn ‘mọdé.

    Yóò jẹ́ ká lè máa nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú.

    Ká nírẹ̀lẹ̀, ká sì tún ní ojú àánú.

    Yóò jẹ́ ká lè máa ṣoore fún gbogbo èèyàn

  2. 2. Ọjọ́ ìkẹyìn la wà.

    Ayé yìí túbọ̀ ń burú sí i.

    Ojú àánú ti fọ́ pátápátá.

    Àwọn èèyàn ti dájú gan-an.

    Ó yẹ ká ṣọ́ra, ká má dà bíi wọn. Ó yẹ ká máa ṣoore.

    (ÈGBÈ)

    Ká nírẹ̀lẹ̀; ká fìwà jọ àwọn ‘mọdé.

    Yóò jẹ́ ká lè máa nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú.

    Ká nírẹ̀lẹ̀, ká sì tún ní ojú àánú.

    Yóò jẹ́ ká lè máa ṣoore fún gbogbo èèyàn.

    Ká jónírẹ̀lẹ̀.

    (ÀSOPỌ̀)

    Bá a ṣe ń dàgbà sí i,

    Tá à ń sin Jèhófà,

    Tí a sì ń láyọ̀.

    Lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀,

    Ká fi sọ́kàn pé

    Ó ṣe pàtàkì gan-an

    Pé ká fìwà jọ àwọn ‘mọdé.

    (ÈGBÈ)

    Ká nírẹ̀lẹ̀; ká fìwà jọ àwọn ‘mọdé.

    Yóò jẹ́ ká lè máa nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú.

    Ká nírẹ̀lẹ̀, ká sì tún ní ojú àánú.

    Yóò jẹ́ ká lè máa ṣoore fún gbogbo èèyàn.

    Ká jónírẹ̀lẹ̀.