Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù

Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù

Wà á jáde:

  1. 1. Ọ̀pọ̀ ìpinnu là ń ṣe lójoojúmọ́.

    Ó yẹ ká máa fọgbọ́n lo àkókò wa.

    A máa ń fẹ́ wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa,

    Àmọ́ nǹkan míì wà tó tún ṣe pàtàkì jù.

    (ÈGBÈ)

    A gbọ́dọ̀ wáyè fóhun tó ṣe pàtàkì jù—

    Gbàdúrà, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́.

    Sún mọ́ Jèhófà, ìyẹn gan-an ló dára jù.

    Fàkókò rẹ ṣohun gidi.

    Máa ronú nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ.

    Má ṣe gbàgbé ohun tó ṣe pàtàkì jù.

  2. 2. Àtijẹ-àtimu, lè má rọrùn.

    Àmọ́ èyí lè fa ìpínyà ọkàn.

    Ká máa wáyè fún ìdílé wa.

    Tá a bá fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́, tá a fẹ́ bójú tó wọn​—

    (ÈGBÈ)

    A gbọ́dọ̀ wáyè fóhun tó ṣe pàtàkì jù—

    Gbàdúrà, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́.

    Sún mọ́ Jèhófà, ìyẹn gan-an ló dára jù..

    Fàkókò rẹ ṣohun gidi.

    Máa ronú nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ.

    Má ṣe gbàgbé ohun tó ṣe pàtàkì jù.

    (ÈGBÈ)

    A gbọ́dọ̀ wáyè fóhun tó ṣe pàtàkì jù—

    Gbàdúrà, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́.

    Sún mọ́ Jèhófà, ìyẹn gan-an ló dára jù.

    Fàkókò rẹ ṣohun gidi.

    Máa ronú nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ.

    Má ṣe gbàgbé ohun tó ṣe pàtàkì jù.