Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé A Lè Ka Fífi Ẹnu Lá Ẹ̀yà Ìbímọ Ẹlòmíì sí Ìbálòpọ̀?

Ṣé A Lè Ka Fífi Ẹnu Lá Ẹ̀yà Ìbímọ Ẹlòmíì sí Ìbálòpọ̀?

 Àjọ kan tó ń rí sí Ìkáwọ́ àti Ìdènà Àrùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ròyìn pé nǹkan bí ìlàjì nínú àwọn ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sí mọ́kàndínlógún [19] tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló ti fi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì rí. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Sharlene Azam, tó ṣe ìwé kan tó pè ní Oral Sex Is the New Goodnight Kiss sọ pé: “Tó o bá ń bá àwọn ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀ [nípa fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì] wọ́n á sọ fún ẹ pé kò sí nǹkan tó burú nínú rẹ̀. Kódà, àwọn ọ̀dọ́ yìí ò tiẹ̀ ka fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì sí ìbálòpọ̀.”

 Kí lèrò rẹ?

 Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ṣé bẹ́ẹ̀ ni àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

  1.   Ṣé ọmọbìnrin kan lè lóyún tó bá ń fi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì?

    1.   Bẹ́ẹ̀ ni

    2.   Bẹ́ẹ̀ kọ́

  2.   Ṣé fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì lè ṣàkóbá fún ìlera ẹni?

    1.   Bẹ́ẹ̀ ni

    2.   Bẹ́ẹ̀ kọ́

  3.   Ṣé a lè ka fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì sí ìbálòpọ̀?

    1.   Bẹ́ẹ̀ ni

    2.   Bẹ́ẹ̀ kọ́

 Kí làwọn ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa rẹ̀?

 Fi ìdáhùn rẹ wé àwọn ìdáhùn tó wà nísàlẹ̀ yìí.

  1.   Ṣé ọmọbìnrin kan lè lóyún tó bá ń fi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì?

     Ìdáhùn: Bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìdí nìyẹn táwọn kan fi parí èrò sí pé kò lè ṣe ìpalára fún àwọn, èrò yìí ò sì tọ̀nà.

  2.   Ṣé fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì lè ṣàkóbá fún ìlera ẹni?

     Ìdáhùn: Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹni tó bá ń fi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì lè kó àrùn mẹ́dọ̀wú, kòkòrò àrún genital warts, àtọ̀sí, ìléròrò ẹ̀yà ìbímọ, kòkòrò àrùn HIV àti àrùn rẹ́kórẹ́kó.

  3.   Ṣé a lè ka fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ sí ìbálòpọ̀?

     Ìdáhùn: Bẹ́ẹ̀ ni. Ìbálòpọ̀ ni ohunkóhun tó bá ti ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì, èyí ní nínú ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àti obìnrin, fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì, bíbá ẹlòmíì lò pọ̀ látinú ihò ìdí àti fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì.

 Kí nìdí tọ́rọ̀ yìí fi ṣe pàtàkì?

 Wo díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì.

 Bíbélì sọ pé: “Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, . . . pé kí ẹ ta kété sí àgbèrè.”​—1 Tẹsalóníkà 4:​3.

 Ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “àgbèrè” látinú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tọ́ka sí gbogbo ọ̀nà èyíkéyìí tí àwọn tí kì í ṣe tọkọtaya lè gbà ní ìbálòpọ̀, èyí sì ní nínú fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì, bíbá ẹlòmíì lò pọ̀ látinú ihò ìdí àti fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì. Àbájáde búburú ló máa yọrí sí fún ẹni tó bá ń ṣe àgbèrè, èyí tó sì wá burú jù ni pé ó máa ba àjọṣe tí onítọ̀hún ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́.​—1 Pétérù 3:12.

 Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.”​—1 Kọ́ríńtì 6:18.

 Fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì lè ṣe ìpalára nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa ń fa ẹ̀dùn ọkàn. Ìwé kan tí wọ́n pè ní Talking Sex With Your Kids sọ pé: “Kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin tó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì lọ́nà tí kò tọ́ nìkan ló lè máa ronú pé wọ́n ti lo òun nílòkulò, kó máa kábàámọ̀ tàbí kó tiẹ̀ kó àrùn ìbálòpọ̀. Àwọn tó bá ń lọ́wọ́ nínú èyíkéyìí lára àwọn ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ náà lè ní ẹ̀dùn ọkàn tí ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ ń fà. Torí náà, ìbálòpọ̀ ni ìbálòpọ̀ ń jẹ́, kò lórúkọ méjì.”

 Bíbélì sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.”​—Aísáyà 48:​17.

 Ṣé o gbà pé àǹfààní ara rẹ ni àwọn òfin Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ wà fún? Àbí o rò pé àwọn òfin yìí kò jẹ́ kó o ṣe ohun tó wù ẹ́? Kó o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ronú nípa títì márosẹ̀ kan tó ní àwọn àmì ojú ọ̀nà, irú bíi sáré níwọ̀n, àmì iná tó ń darí ọkọ̀ àti ibi tó ti yẹ kí èèyàn ti dúró jẹ́ẹ́. Ṣé ohun tó ń díni lọ́wọ́ ni wàá ka àwọn àmì yẹn sí ni àbí ohun tó ń dáàbò boni? Kí lo rò pé ó lè ṣẹlẹ̀ tí ìwọ àbí àwọn awakọ̀ míì kò bá ka àwọn àmì ojú ọ̀nà yìí sí?

Lóòótọ́ àwọn àmì ojú ọ̀nà lè má jẹ́ kó o ṣe ohun tó wù ẹ́, àmọ́ wọ́n ń dáàbò ẹ́. Bákan náà, àwọn òfin Ọlọ́run lè dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan kan, àmọ́ wọ́n ń dáàbò bò ẹ́

 Bí àwọn ìlànà Ọlọ́run ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Wàá rí àbájáde rẹ̀ tó o bá ń ṣàìka àwọn ìlànà yìí sí. (Gálátíà 6:7) Ìwé kan tí wọ́n pè ní Sex Smart sọ pé: “Bó o bá ṣe ń pa ìgbàgbọ́ rẹ àti àwọn ohun tó o kà sí pàtàkì tì, tó o wá lọ ń lọ́wọ́ nínú ohun tó o mọ̀ pé kò tọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni iyì ara ẹni tó o ní á ṣe máa dínkù.” Yàtọ̀ sí èyí, wàá fi hàn pé o jẹ́ ẹni rere tó o bá ń pa àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé wàá ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.​—1 Pétérù 3:16.