Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Apá Mi Á Ká Àwọn Iṣẹ́ Àṣetiléwá Báyìí?

Ṣé Apá Mi Á Ká Àwọn Iṣẹ́ Àṣetiléwá Báyìí?

 “Láago kan òru, kéèyàn má tíì sùn, kó máa ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá, kò rọrùn rárá. Bí oorun, bí oorun lá máa ṣèèyàn.”​—David.

 “Mo ṣì máa ń wà nídìí ìwé láago mẹ́rin ààbọ̀ ìdájí nígbà míì, mo sì gbọ́dọ̀ jí láago mẹ́fà àárọ̀ kí n lè múra ilé ìwé. Kò dẹrùn fún mi rárá!”​—Theresa.

 Ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá máa ń pọ̀ jù fún ẹ ni? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa kọ́ ẹ lọ́gbọ́n tó máa dáa sí i.

 Kí nìdí táwọn olùkọ́ fi máa ń fún àwọn ọmọ iléèwé ní iṣẹ́ àṣetiléwá?

 Díẹ̀ lára ẹ̀ ni pé, iṣẹ́ àṣetiléwá . . .

  •   máa ṣí ojú àti ọpọlọ ẹ sí ọ̀pọ̀ nǹkan tó ò tíì mọ̀

  •   máa jẹ́ kó o di ẹni tó ṣe é gbara lé

  •   máa jẹ́ kó o lè ṣètò àkókò rẹ dáadáa

  •   máa jẹ́ kó o lóye ohun tí olùkọ́ ń kọ́ ẹ a

 “Àwọn olùkọ́ máa ń fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní iṣẹ́ àṣetiléwá torí kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè fi ohun tí wọ́n ti kọ́ dánra wò dípò kó kàn jẹ́ pé ńṣe làwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ wọn gba etí ọ̀tún wọlé, tó sì ń gba tòsì jáde.”​—Marie.

 Ní pàtàkì, ẹ̀kọ́ ìṣirò àti sáyẹ́ǹsì máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè yanjú ìṣòro. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ pé, àwọn ẹ̀kọ́ yẹn máa jẹ́ kí ọpọlọ rẹ̀ ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Torí náà, iṣẹ́ àṣetiléwá dà bí eré ìmárale fún ọpọlọ rẹ!

 Bóyá o gbà pé iṣẹ́ àṣetiléwá máa ṣe ẹ́ láǹfààní àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, o ní láti mọ̀ pé ohun tó yẹ kó o ṣe ni. Ohun kan tó o gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn rèé: Lóòtọ́, o kò lè pinnu bí iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n máa fún ẹ ṣe máa pọ̀ tó, àmọ́ ó lè má gbà ẹ́ lákòókò tó pọ̀. Jẹ́ ká wo bó o ṣe lè ṣe é.

 Ìmọ̀ràn to máa ràn ẹ́ lọ́wọ́

 Tó bá jẹ́ pé kò rọrùn fún ẹ láti ṣe àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n ń fún ẹ, má ṣe rò pé òkè ìṣòrò tó ò lè borí ni. Àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

  •   Ìmọ̀ràn 1: Múra sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.” (Òwe 21:5) Rí i dájú pé gbogbo nǹkan tó o fẹ́ ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kó ní sídìí láti máa dìde káàkiri.

     Tún wa ibi tó rọrùn fún ẹ tí wàá ti lè pọkàn pọ̀. Àwọn kan máa ń fẹ́ ibi tó pa rọ́rọ́ tí iná sì wà níbẹ̀. Àwọn míì sì máa ń kúrò nílè wọn, wọ́n tiẹ̀ le lọ sí ilé ìkówèésí.

     “Tó o bá ní ìwé tàbí kàlẹ́ńdà tó o fi ń kọ àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá tó o fẹ́ ṣe àti déètì tó o fẹ́ parí wọ́n, wàá lè fọgbọ́n ṣètò àkókò rẹ lọ́nà tó dáa. Tó o bá ń fọkàn sí iṣẹ́ àṣetiléwá tó yẹ kó o ṣè àti ìgbà tó yẹ kó o ṣe é, àníyàn rẹ máa dín kù.”​—Richard.

  •   Ìmọ̀ràn 2: Ṣètò iṣẹ́ rẹ. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ . . . létòlétò.” (1 Kọ́ríńtì 14:40) Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn rẹ̀, pinnu iṣẹ́ àṣetiléwá tó o máa kọ́kọ́ ṣe àtèyí tó máa ṣe tẹ̀ lé e.

     Àwọn kan máa ń fẹ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èyí tó nira. Ó sì máa ń yá àwọn míì lára tí wọ́n bá kọ́kọ́ ṣe àwọn èyí tó rọ̀. Èyí tó bá rọrùn fún ẹ ni kó o ṣe nínú méjèèjì.

     “Ó máa ń ṣèrànwọ́ gan-an téèyàn bá níbi tó ń kọ àwọn ohun tó fẹ́ ṣe sí àti bí wọ́n ṣe tò tẹ̀ lé ara wọn. Ìyẹn máa jẹ́ kó o lè ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá lásìkò, kò sì ní kà ẹ́ láyà.”​—Heidi.

  •   Ìmọ̀ràn 3: Jára mọ́ṣẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa ṣiṣẹ́ kára, ẹ má ṣọ̀lẹ.” (Róòmù 12:11) Má ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan míì gba àsìkò tó yẹ kó o fi ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mọ́ ẹ lọ́wọ́, láìka bó ti wù kó wù ẹ́ tó.

     Àwọn tó ti mọ́ lára láti máa fòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la kì í parí iṣẹ́ wọn lásìkò àbí kó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n máa kánjú parí ẹ̀, ìyẹn sì máa ń ṣàkóbá fún ẹ̀kọ́ àti ìṣẹ́ wọn. Ohun tó o lè ṣe tó ò bá fẹ́ kí irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ẹ ni pé kó o máa tètè ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ.

     “Tí mo bá tètè ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mi ní gbàrà tí mo bá dé láti ilé ìwé tàbí tí mo bẹ̀rẹ̀ sí i ṣiṣẹ́ lórí ohun kan tí wọ́n ní kí ń ṣe láìpẹ́ sígbà tí wọ́n fún mi, ṣe ni ọkàn mi máa ń balẹ̀, ó sì máa ń fún mi láyè láti ṣe àwọn nǹkan míì.”​—Serina.

     ÀBÁ: Àkókò kan náà ni kó o máa ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ lójoojúmọ́. Ìyẹn máa jẹ́ kó o kóra rẹ níjàánu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó máa mọ́ ẹ lára.

  •   Ìmọ̀ràn 4: Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ níyà. Bíbélì sọ pé: “Iwájú rẹ gan-an ni kí o tẹjú mọ́.” (Òwe 4:25) Tó o bá fẹ́ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun, ní pàtàkì àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé, pín ọkàn rẹ níyà nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́.

     Tó bá jẹ́ pé ṣe ló ń ti orí ìkànnì kan bọ́ sí òmíì, tó sì ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́, ó máa gba ìlọ́po méjì àkókò tó yẹ kó o fi parí iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ. Àmọ́ tó o bá pọkàn pọ́, wàá rí i pé o kò ní ṣe wàhálà tó pọ̀, wàá sì tún ráyé ṣeré.

     “Ọkàn rẹ̀ ò ní pa pọ̀ tó o bá tan fóònù, kọ̀ǹpútà, àwọn ohun tó o fi ń gbá géèmù àti tẹlifíṣọ̀n sílẹ̀. Ohun tó máa ń ràn mí lọ́wọ́ ni pé mo máa ń pa fóònù, máa sì pa gbogbo ohun èlò ìgbàlódé tó lè pín ọkàn mi níyà tó bá wà nítòsí.”​—Joel.

  •   Ìmọ̀ràn 5: Wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.” (Fílípì 4:5) Máa fún ara rẹ ní ìsinmi kí iṣẹ́ náà má bàá mú ẹ lómi kọjá bó ṣe yẹ. O lè rìn jáde, o lè gun kẹ̀kẹ́ tàbí kó o sáré.

     Lẹ́yìn tó o bá ti ṣe gbogbo ohun tá a gbé yẹ̀ wó yìí, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ ṣì pọ̀ jù fún ẹ, bá àwọn olùkọ́ rẹ sọ̀rọ̀. Tí wọ́n bá rí i pé, ò ń gbìyànjú lóòótọ́, wọ́n lè pinnu láti dín iṣẹ́ tí wọ́n ń gbé fún ẹ kù.

     “Má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ àṣetiléwá sọ ẹ di ẹni tí kò láyọ̀ àtẹni tí gbogbo nǹkan sú. Sa gbogbo ipá rẹ. Àwọn nǹkan kan wà tí kò yẹ kó sọ ẹ́ dìdàkudà, ọ̀kan lára ẹ̀ ni iṣẹ́ àṣetiléwá.”​—Julia.

 Bi ara rẹ láwọn ìbéèrè yìí:

  •   Àwọn ohun wo ni mo nílò fún iṣẹ́ àṣetiléwá mi?

  •   Àkókò wo ló dáa jù tó yẹ kí ń fi ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mi?

  •   Ibo ló dáa jù tí màá ti lè pọkàn pọ̀?

  •   Báwo ni mi ò ṣe ní máa fòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la?

  •   Àwọn ohun wo ló lè pín ọkàn mi níyà?

  •   Báwo ni mi ò ṣe ní jẹ́ kí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tàbí àwọn nǹkan míì pín ọkàn mi níyà?

  •   Báwo ni màá ṣe rí i dájú pé mo tètè ń ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mi láìsì pé ó ń kó mi lọ́kàn sókè?

 ÌRÀNNÍLÉTÍ PÀTÀKÌ: Rí i dájú pé o mọ ohun tí olùkọ́ rẹ fẹ́ kó o ṣe nínú iṣẹ́ àṣetiléwá tó fún ẹ. Tí kò bá yé ẹ, béèrè lọ́wọ́ olùkọ́ rẹ kó o tó kúrò nílé ìwé.

a Inú ìwé náà, School Power, látọwọ́ Jeanne Schumm la ti mú àwọn kókó yìí.