ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Kò Fi Ní Máa Rẹ̀ Mí Jù?
Tó bá jẹ́ pé ó sábà máa ń rẹ̀ ẹ́ gan-an, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Kí ló máa ń fà á
Mo fẹ́ ṣe tibí, mo fẹ́ ṣe tọ̀hún. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Julie sọ pé: “Wọ́n máa ń sọ pé ká máa ṣe dáadáa ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa, ká máa sunwọ̀n sí i, wọ́n tún ní ká ní àfojúsùn tó nítumọ̀, ká sì lé wọn bá. Nǹkan kì í rọrùn fún wa rárá nítorí bí wọ́n ṣe ń fúngun mọ́ wa yìí!”
Ìmọ̀ ẹ̀rọ. Fóònù àtàwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tá à ń lò ti mú kó rọrùn láti mọ nǹkan tó ń lọ lórí ìkànnì, èyí lè mú kọ́wọ́ wa dí nígbà gbogbo, ó sì lè mú kó rẹ̀ wá gan-an.
Oorun. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Miranda sọ pé: “Ilé ìwé, iṣẹ́ àti eré ìnàjú ni kì í jẹ́ káwọn míì tètè sùn, wọ́n sì máa ń tètè jí, bó ṣe máa ń rí fún wọn nìyẹn lọ́pọ̀ ìgbà torí kò sóun tí wọ́n lè ṣe sí i.” Irú nǹkan báyìí lè jẹ́ kó rẹni gan-an.
Ìdí tó fi yẹ kó o mọ̀
Bíbélì gbóríyìn fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára. (Òwe 6:6-8; Róòmù 12:11) Àmọ́ kò fẹ́ ká máa ṣiṣẹ́ bí aago, tó fi jẹ́ pé a ò ní ráyè bójú tó ìlera wa àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì.
“Ṣàdédé ni mo rántí pé mi ò tíì jẹun látàárọ̀, ìdí sì ni pé ọwọ́ mi dí gan-an. Mo ti wá rí i báyìí pé tí wọ́n bá ní kí n ṣe iṣẹ́ kan tí mo mọ̀ pé ó máa pa mí lára, ó máa dáa tí mo bá sọ pé mi ò ní lè ṣe é.”—Ashley.
Ó ní ìdí tí Bíbélì fi sọ pé: “Ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ.” (Oníwàásù 9:4) Tó o bá ń lo ara ẹ lálòjù ó lè dà bíi pé o lágbára bíi kìnnìún. Àmọ́ tó o bá ń jẹ́ kó rẹ̀ ẹ́ jù, ó léwu fún ìlera ẹ.
Ohun tó o lè ṣe
Sọ pé oò ní lè ṣe é. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Ẹni tó bá mẹ̀tọ́mọ̀wà máa ń mọ ibi tágbára ẹ̀ mọ, kò sì ní máa ṣe nǹkan tó ju agbára ẹ̀ lọ.
“Ẹni tó sábà máa ń rẹ̀ jù ni ẹni tó máa ń ṣòro fún láti sọ pé mi ò lè ṣe é, tó jẹ́ pé gbogbo nǹkan ní wọ́n máa ń fẹ́ dáwọ́ lé. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Bópẹ́ bóyá ó máa rẹ̀ ẹ́ gan-an.”—Jordan.
Máa sùn dáadáa. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.” (Oníwàásù 4:6) Oorun ni wọ́n ń pè ní “oúnjẹ ọpọlọ,” àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni kì í sùn tó wákàtí mẹ́jọ sí mẹ́wàá, iye wákàtí tó sì yẹ kí wọ́n máa fi sùn nìyẹn.
“Tí mo bá ní nǹkan púpọ̀ láti ṣe, mi ò kì í ráyè sùn dáadáa. Àmọ́ lọ́jọ́ tí mo bá sùn dáadáa, màá lókun láti ṣiṣẹ́, inú mi sì máa dùn gan-an lọ́jọ́ kejì.”—Brooklyn.
Ṣètò ara rẹ. Bíbélì sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” (Òwe 21:5) Tó o bá kọ́ bó o ṣe lè máa ṣètò ara rẹ pẹ̀lú àkókò rẹ, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá dàgbà.
“Tó ò bá fẹ́ máa fún ara rẹ ní wàhálà jù, á dáa kó o ṣètò àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mọ àwọn apá ibi tó yẹ kó o ṣe àtúnṣe sí kó o má bàa rẹ̀ ẹ́ jù.”—Vanessa